Kí Nìdí Táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Máa Ń Fi Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ Kọ̀ Láti Ka Ẹ̀jẹ́ Tàbí Kọ Orin Orílẹ̀-Èdè?
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń bọ̀wọ̀ fún ìjọba àtàwọn àmì ìlú. A sì gbà pé àwọn míì lè pinnu láti ka ẹ̀jẹ́ orílẹ̀-èdè, láti bẹ́rí tàbí kí àsíá tàbí kí wọ́n kọ orin orílẹ̀-èdè.
Àmọ́, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í lọ́wọ́ nínú àwọn nǹkan yìí torí a gbà pé ó ta ko ìlànà Bíbélì. Inú wa máa ń dùn táwọn míì bá bọ̀wọ̀ fún ìpinnu tá a ṣe yìí torí àwa náà máa ń bọ̀wọ̀ fún ìpinnu táwọn míì bá ṣe.
Nínú àpilẹ̀kọ yìí
Àwọn ìlànà Bíbélì wo ni kì í jẹ́ ká lọ́wọ́ nínú àwọn nǹkan yìí?
Àwọn ìlànà Bíbélì méjì yìí la gbé ìpinnu wa kà:
Ọlọ́run nìkan ló yẹ ká máa sìn. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni o gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni o gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún.” (Lúùkù 4:8) Ẹ̀jẹ́ orílẹ̀-èdè àti orin orílẹ̀-èdè sábà máa ń ní àwọn ọ̀rọ̀ kan níbi tí ẹni tó ń kà á ti máa ṣèlérí pé òun á fi gbogbo agbára òun sin orílẹ̀-èdè òun, àtipé orílẹ̀-èdè òun ni òun á fi ṣáájú ohun gbogbo. Torí náà, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò lè ṣe irú ìlérí bẹ́ẹ̀ torí pé kò bá ẹ̀rí ọkàn wa mu.
Bákan náà, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé tá a bá bẹ́rí tàbí kí àsíá, ṣe là ń jọ́sìn ohun tí àsíá náà ṣàpẹẹrẹ. Ìbọ̀rìṣà nìyẹn, Bíbélì sì sọ pé a ò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí ìbọ̀rìṣà. (1 Kọ́ríńtì 10:14) Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé àmì ìjọsìn kan ni àsíá. Kódà, òpìtàn kan tó ń jẹ́ Carlton J. H. Hayes sọ pé: “Àsíá ni àmì tí wọ́n fi ń gbé ìjọsìn orílẹ̀-èdè lárugẹ.” a Òǹkọ̀wé kan tó ń jẹ́ Daniel P. Mannix sọ nípa àwọn Kristẹni ayé àtijọ́ pé: “Àwọn Kristẹni kọ̀ láti rúbọ sí olú ọba Róòmù, ìyẹn sì dà bí ìgbà téèyàn kọ̀ láti bẹ́rí tàbí kí àsíá.” b
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í bẹ́rí tàbí kí àsíá, a kì í fà á ya tàbí ká dáná sun ún, a kì í sì í ṣe ohunkóhun tó fi hàn pé a ò bọ̀wọ̀ fún àsíá tàbí àmì míì tí ìjọba ń lò.
Ọ̀kan náà ni gbogbo èèyàn jẹ́ lójú Ọlọ́run. (Ìṣe 10:34, 35) Bíbélì sọ nípa Ọlọ́run pé “láti ara ọkùnrin kan ló ti dá àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè.” (Ìṣe 17:26) Ìdí nìyẹn táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé kò ní dáa ká máa gbé ẹ̀yà kan tàbí orílẹ̀-èdè kan lárugẹ ju òmíì lọ. Torí náà, gbogbo èèyàn la máa ń bọ̀wọ̀ fún láìka ibi tí wọ́n ti wá àti ibi tí wọ́n ń gbé sí.—1 Pétérù 2:17.
Tí ìjọba bá ṣòfin pé dandan ni ká lọ́wọ́ sí ńkọ́?
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ta ko ìjọba. A gbà pé àwọn ìjọba yìí wà lára “ètò tí Ọlọ́run ṣe,” tó sì gbà láàyè. (Róòmù 13:1-7) A tún gbà pé àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sí ìjọba.—Lúùkù 20:25.
Àmọ́ tí ìjọba bá ṣe òfin tó ta ko òfin Ọlọ́run ńkọ́? Láwọn ipò kan, a lè tọ̀ ọ́ lọ́nà òfin, ká sì kọ̀wé sí ìjọba pé kí wọ́n ṣe àwọn àyípadà kan sí òfin náà. c Tí wọ́n bá kọ̀ jálẹ̀, tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi máa yàn láti “ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí alákòóso dípò èèyàn.”—Ìṣe 5:29.
Ṣé torí ká lè gbè sẹ́yìn ẹgbẹ́ òṣèlú kan làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi í lọ́wọ́ nínú àwọn nǹkan yìí?
Rárá o. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú. Ti pé a ò ka ẹ̀jẹ́ orílẹ̀-èdè, a ò bẹ́rí fún àsíá, a ò sì kọ orin orílẹ̀-èdè, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé à ń ta ko ìjọba. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn nǹkan yìí la pinnu láti ṣe.