Báwo Ni Ìgbéyàwó Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣe Máa Ń Rí?
Ayẹyẹ ìgbéyàwó tó mọ níwọ̀n làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sábà máa ń ṣe, ó máa ń buyì kúnni, a sì máa ń gbọ́ àsọyé ṣókí látinú Bíbélì níbẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn, a lè ṣe ayẹyẹ, ká sì fáwọn èèyàn lóúnjẹ. a Nígbà tí Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó lọ síbi tí wọ́n ti ṣe irú ayẹyẹ bẹ́ẹ̀ ní ìlú Kánà.—Jòhánù 2:1-11.
Àwọn nǹkan wo làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó?
Apá pàtàkì lára ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ níbi ìgbéyàwó àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni àsọyé Bíbélì, òjíṣẹ́ kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló máa ń sọ àsọyé yìí fún ọgbọ̀n [30] ìṣẹ́jú. Àsọyé tó ń gbéni ró, tó sì dá lórí Bíbélì yìí máa ń jẹ́ kí tọkọtaya mọ bí wọ́n ṣe lè túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn, kí wọ́n láyọ̀, kí ìgbéyàwó wọn sì tọ́jọ́.—Éfésù 5:33.
Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, ìjọba máa ń fún àwọn òjíṣẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà láṣẹ láti so tọkọtaya pọ̀. Torí náà, lọ́wọ́ ìparí àsọyé yẹn, tọkọtaya máa ka ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó. Wọ́n tún lè fi òrùka síra wọn lọ́wọ́. Lẹ́yìn ìyẹn, òjíṣẹ́ tí ìjọba fún láṣẹ láti so wọ́n pọ̀ á wá sọ pé wọ́n ti di tọkọtaya.
Láwọn orílẹ̀-èdè míì, òṣìṣẹ́ ìjọba lòfin fàyè gbà pé kó so tọkọtaya pọ̀, wọ́n sì gbọ́dọ̀ ṣe é ní ọ́fíìsì ìjọba. Torí náà, wọ́n máa gbọ́ àsọyé ìgbéyàwó lẹ́yìn tí òṣìṣẹ́ ìjọba bá ti so wọ́n pọ̀. Tí tọkọtaya ò bá ka ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó ní ọ́fíìsì ìjọba, wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ ìparí àsọyé náà. Àmọ́, tí wọ́n bá ti ka ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó ní ọ́fíìsì ìjọba, wọ́n lè tún un kà, àmọ́ wọ́n á sọ ọ́ lọ́nà tá fi hàn pé wọ́n ti kà á tẹ́lẹ̀. Lẹ́yìn àsọyé ìgbéyàwó yẹn, wọ́n máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run wà pẹ̀lú tọkọtaya náà.
Ibo làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣe ìgbéyàwó?
Gbọ̀ngàn Ìjọba lọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣe ìgbéyàwó. b Tí tọkọtaya bá fẹ́ ṣe àwẹ̀jẹ àwẹ̀mu, ibòmíì ni wọ́n ti máa ṣe é.
Ta ló lè wá síbi ìgbéyàwó náà?
Tó bá jẹ́ pé Gbọ̀ngàn Ìjọba ni wọ́n ti fẹ́ ṣe ìgbéyàwó náà, ẹnikẹ́ni ló lè lọ síbẹ̀, ì báà jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí ẹni tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Tí tọkọtaya bá fẹ́ ṣe àwẹ̀jẹ àwẹ̀mu, àwọn ló máa pinnu ẹni tá wá síbẹ̀.
Ṣé ó ní báwọn tí wọ́n pè ṣe gbọ́dọ̀ múra?
Lóòótọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò retí pé kéèyàn múra lọ́nà kan pàtó tó bá ń lọ síbi ìgbéyàwó tí wọ́n ń ṣe nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba, síbẹ̀ wọ́n máa ń sapá láti tẹ̀ lé ohun tí Bíbélì sọ, wọ́n máa ń wọ aṣọ tó bójú mu, tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, tó sì buyì kún ayẹyẹ ìgbéyàwó náà. Inú wọn sì máa ń dùn táwọn míì bá múra lọ́nà tó bójú mu. (1 Tímótì 2:9) Tí tọkọtaya bá fẹ́ ṣe àwẹ̀jẹ àwẹ̀mu, ìlànà yìí kan náà ló yẹ káwọn tó máa lọ síbẹ̀ tẹ̀ lé.
Ṣé àwọn èèyàn lè mú ẹ̀bùn wá fún tọkọtaya?
Bíbélì sọ pé ó yẹ ká jẹ́ ọ̀làwọ́. (Sáàmù 37:21) Torí náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fáwọn èèyàn lẹ́bùn ìgbéyàwó, inú àwọn náà sì máa ń dùn táwọn èèyàn bá fún wọn lẹ́bùn ìgbéyàwó. (Lúùkù 6:38) Àmọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í tọrọ ẹ̀bùn, wọn kì í sì í kéde orúkọ àwọn tó bá fún wọn lẹ́bùn. (Mátíù 6:3, 4; 2 Kọ́ríńtì 9:7; 1 Pétérù 3:8) Yàtọ̀ sí pé àṣà yìí ò bá Bíbélì mu, ó tún lè dójú ti àwọn tó wá síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó náà.
Ṣé wọ́n máa ń dáṣà ká fi ife ọtí kan tẹlòmíì níbẹ̀?
Rárá o. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í na ife ọtí sókè láti fi kan tẹlòmíì, torí pé inú ẹ̀sìn èké ni àṣà yìí ti wá. c Dípò ìyẹn, àwọn nǹkan míì wà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe láti fi hàn pé àwọn fẹ́ kí Ọlọ́run bù kún tọkọtaya náà.
Ṣé àwọn èèyàn lè fọ́n ìrẹsì tàbí bébà wínníwínní sára tọkọtaya?
Rárá o. Láwọn ibì kan, àwọn èèyàn máa ń fọ́n ìrẹsì, bébà wínníwínní tó ní àwọ̀ oríṣiríṣi tàbí ohun míì tó jọ ọ́ sára tọkọtaya. Wọ́n gbà pé èyí máa mú kí tọkọtaya náà ṣoríire, kí wọ́n láyọ̀, kí wọ́n sì pẹ́ láyé. Ṣùgbọ́n àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í lọ́wọ́ sí àṣà tó dá lórí ohun asán. Wọn kì í gbọ́wọ́ lé tọkọtaya lórí láti gbàdúrà pé kí wọ́n ṣoríire, torí pé irú àṣà bẹ́ẹ̀ ta ko ìlànà Bíbélì.—Àìsáyà 65:11.
Ṣé jíjẹ mímu máa ń wà níbẹ̀?
Kì í sí oúnjẹ tàbí ọtí níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá ṣe nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àmọ́, àwọn tọkọtaya kan lè ṣètò pé àwọn máa ṣe ayẹyẹ lẹ́yìn tí wọ́n bá kúrò ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, kí wọ́n lè fún àwọn èèyàn ní oúnjẹ tàbí ìpápánu. (Oníwàásù 9:7) Tí wọ́n bá yàn láti fún àwọn èèyàn lọ́tí, wọ́n máa ń rí i dájú pé kò pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ, àwọn tó dàgbà tó láti mutí nìkan ni wọ́n sì máa ń fún.—Lúùkù 21:34; Róòmù 13:1, 13.
Ṣé wọ́n máa ń kọrin, ṣé wọ́n sì máa ń jó níbẹ̀?
Tí tọkọtaya náà bá yàn láti ṣe ayẹyẹ, wọ́n lè kọrin níbẹ̀, káwọn èèyàn sì jó. (Oníwàásù 3:4) Àwọn ló máa pinnu orin tí wọ́n fẹ́ lò níbi ìgbéyàwó wọn, àmọ́ wọ́n máa rí i pé orin náà tu gbogbo èèyàn lára, ó sì bá àṣà orílẹ̀-èdè wọn mu. Orin tó dá lórí Bíbélì ni wọ́n máa ń lò níbi ìgbéyàwó tí wọ́n bá ṣe nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba.
Ṣé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe ayẹyẹ àyájọ́ ọjọ́ ìgbéyàwó?
Bíbélì ò ní kéèyàn má ṣe ayẹyẹ àyájọ́ ọjọ́ ìgbéyàwó, kò sì ní kéèyàn ṣe é. Torí náà, àwọn tọkọtaya tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló máa pinnu bóyá àwọn á ṣe ayẹyẹ náà àbí àwọn ò ní ṣe é. Tí wọ́n bá pinnu láti ṣe ayẹyẹ yìí, àwọn méjèèjì lè ṣe é láàárín ara wọn, wọ́n sì lè yàn láti pe tẹbí tọ̀rẹ́.
a Àṣà, ìṣe àti ìlànà òfin máa ń yàtọ̀ síra láti ibì kan síbòmíì.
b Òjíṣẹ́ tó máa sọ àsọyé ìgbéyàwó kì í gbowó, ọ̀fẹ́ ni wọ́n sì ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba.
c Tó o bá fẹ́ àlàyé nípa bá a ṣe mọ̀ pé inú ẹ̀sìn èké ni àṣà ká fi ife ọtí kan tẹlòmíì ti wá, wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ February 15, 2007.