Kí Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Gbọ́ Lórí Ọ̀rọ̀ Ìsìnkú?
Tó bá dọ̀rọ̀ ìsìnkú, ohun tó wà nínú Bíbélì la máa ń tẹ̀ lé. Àwọn àpẹẹrẹ kan nìyí:
Kò sóhun tó burú nínú ká ṣọ̀fọ̀ tẹ́ni tá a fẹ́ràn bá kú. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣọ̀fọ̀ nígbà táwọn ọ̀rẹ́ wọn kú. (Jòhánù 11:33-35, 38; Ìṣe 8:2; 9:39) Torí náà, a kì í ṣe àríyá níbi ìsìnkú. (Oníwàásù 3:1, 4; 7:1-4) Àsìkò téèyàn máa ń káàánú àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ la kà á sí.—Róòmù 12:15.
Àwọn òkú ò mọ nǹkan kan. Bíbélì ò fi kọ́ni pé àwọn òkú mọ nǹkan kan tàbí pé wọ́n lè ṣe ohunkóhun fáwọn alààyè. Torí náà, láìka ohun táwọn èèyàn ń ṣe níbi tá a ti wá tàbí tí wọ́n ti tọ́ wa dàgbà sí, a kì í lọ́wọ́ sí àwọn àṣà tó bá dá lé irú nǹkan bẹ́ẹ̀. (Oníwàásù 9:5, 6, 10) Àwọn àpẹẹrẹ kan ni àìsùn òkú, ayẹyẹ ìsìnkú aláriwo àti ìrántí olóògbé, ètùtù òkú, kéèyàn máa bá òkú sọ̀rọ̀ tàbí kó máa wádìí lọ́dọ̀ òkú àti ààtò ilé opó. A kì í lọ́wọ́ sí gbogbo àṣà yìí torí pé a fẹ́ tẹ̀ lé àṣẹ tí Bíbélì pa pé: “Ẹ . . . ya ara yín sọ́tọ̀, . . . kí ẹ sì jáwọ́ nínú fífọwọ́kan ohun àìmọ́.”—2 Kọ́ríńtì 6:17.
Ìrètí wà fáwọn tó ti kú. Bíbélì kọ́ wa pé àjíǹde máa wà, ìgbà kan sì ń bọ̀ tí kò ní sí ikú mọ́. (Ìṣe 24:15; Ìṣípayá 21:4) Ìrètí yìí ran àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ lọ́wọ́, kì í sì í jẹ́ káwa náà ṣọ̀fọ̀ ju bó ṣe yẹ.—1 Tẹsalóníkà 4:13.
Bíbélì rọ̀ wá pé ká máa ṣe nǹkan níwọ̀n. (Òwe 11:2) A ò gbà pé ó yẹ kí ibi ìsìnkú jẹ́ ibi téèyàn á ti máa fi nǹkan ìní ẹ̀ àti bó ṣe jẹ́ láwùjọ ṣe “ṣekárími.” (1 Jòhánù 2:16) A kì í náwó yàlà-yòlò níbi ìsìnkú tàbí ká náwó rẹpẹtẹ láti ra pósí tàbí ra aṣọ olówó ńlá ká lè fi ṣe fọ́rífọ́rí fáwọn èèyàn.
A kì í fipá mú káwọn míì gba ohun tá a gbà gbọ́ lórí ọ̀rọ̀ ìsìnkú. Ìlànà Bíbélì la máa ń tẹ̀ lé lórí ọ̀rọ̀ yìí, ó sọ pé: “Olúkúlùkù wa ni yóò ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.” (Róòmù 14:12) Àmọ́ tí àǹfààní ẹ̀ bá yọ, a máa ń gbìyànjú àti ṣàlàyé ohun tá a gbà gbọ́ “pẹ̀lú inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.”—1 Pétérù 3:15.
Báwo ni ìsìnkú àwa Ẹlẹ́rìí ṣe máa ń rí?
Ibi tá a ti máa ń ṣe é: Tí ẹbí ẹnì kan bá fẹ́ ṣe ààtò ìsìnkú èèyàn wọn kan tó kú, wọ́n lè ṣe é níbi tó bá wù wọ́n. Ó lè jẹ́ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, nílé tí wọ́n ń gbé òkú sí, nílé àdáni, níbi tí wọ́n ti ń sun òkú tàbí létí ibojì.
Ìsìn: Ẹnì kan máa sọ àsọyé tó máa tu àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ nínú, ó máa ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa ikú àti ìrètí àjíǹde. (Jòhánù 11:25; Róòmù 5:12; 2 Pétérù 3:13) Lásìkò ìsìn yẹn, ẹni tó ń sọ àsọyé náà lè sọ̀rọ̀ lórí ìwà rere ẹni tó kú, ó tiẹ̀ lè sọ àwọn ohun tí àpẹẹrẹ rere ẹni náà kọ́ wa.—2 Sámúẹ́lì 1:17-27.
Wọ́n lè kọ orin kan tó dá lórí Ìwé Mímọ́. (Kólósè 3:16) Wọ́n á wá fi àdúrà tó ń tuni nínú parí ìsìn náà.—Fílípì 4:6, 7.
Owó tàbí ọrẹ: A kì í gba owó lọ́wọ́ àwọn ará wa tá a bá ń ṣe ìsìn, títí kan ààtò ìsìnkú, bẹ́ẹ̀ la kì í gbégbá ọrẹ láwọn ìpàdé wa.—Mátíù 10:8.
Àwọn tó lè wá: Àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí lè wá síbi ààtò ìsìnkú tá a bá ṣe nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bíi tàwọn ìpàdé wa míì ló rí, kò sẹ́ni tí ò lè wá.
Ṣe àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń lọ síbi ìsìnkú táwọn ẹlẹ́sìn míì bá ṣe?
Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀ọ̀kan ti fi Bíbélì kọ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ̀, torí náà òun fúnra rẹ̀ ló máa pinnu bóyá òun á lọ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. (1 Tímótì 1:19) Àmọ́ tá a bá rí i pé àwọn ayẹyẹ ìsìn kan ta ko Bíbélì, a kì í lọ́wọ́ sí i.—2 Kọ́ríńtì 6:14-17.