Ṣé Bíbélì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Yàtọ̀?
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti lo oríṣiríṣi ìtumọ̀ Bíbélì láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àmọ́ láwọn èdè tí Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun bá ti wà, òun la máa ń lò. A máa ń mọyì bó ṣe lo orúkọ Ọlọ́run, bí ìtumọ̀ rẹ̀ ṣe péye àti bí àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ṣe rọrùn láti lóye.
Ó lo orúkọ Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ àwọn tó tẹ Bíbélì kùnà láti fi ògo fún ẹni tó yẹ kí wọ́n fi í fún. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n tẹ ìtumọ̀ Bíbélì kan jáde, wọ́n kọ orúkọ àwọn tó lé ní àádọ̀rin [70] tó ṣèrànwọ́ lọ́nà kan tàbí òmíràn sínú rẹ̀. Àmọ́, wọ́n yọ orúkọ ẹni tó jẹ́ Òńṣèwé Bíbélì kúrò pátápátá, ìyẹn Jèhófà Ọlórun!
Ṣùgbọ́n, ṣe ni Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun dá orúkọ Ọlọ́run pa dà sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ibi tó ti fara hàn nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀, síbẹ̀ orúkọ àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ tó túmọ̀ rẹ̀ kò hàn nínú rẹ̀ rárá.
Ìtumọ̀ rẹ̀ péye. Kì í ṣe gbogbo ìtumọ̀ Bíbélì ló gbé àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ jáde lọ́nà tó péye. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n túmọ̀ Mátíù 7:13 nínú Bíbélì kan lọ́nà yìí: “Ẹ gba ẹnu ọ̀nà tí ó fún wọlé. Ọ̀nà ọ̀run apaadi gbòòrò, ẹnu ọ̀nà rẹ̀ sì fẹ̀.” Àmọ́, “ìparun” ni Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ lò ní ibí yìí kì í ṣe “ọ̀run apaadi.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ torí pé àwọn atúmọ̀ èdè yẹn gbà gbọ́ pé àwọn èèyàn burúkú máa joró títí láé nínú iná ni wọ́n ṣe lo ọ̀rọ̀ náà “ọ̀run apaadi.” Ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nìyẹn. Torí náà, wọ́n túmọ̀ rẹ̀ lọ́nà tó péye nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun pé: “Ẹ gba ẹnubodè tóóró wọlé, nítorí fífẹ̀ àti aláyè gbígbòòrò ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìparun.”
Ó rọrùn láti lóye. Yàtọ̀ sí pé ìtumọ̀ Bíbélì kan gbọ́dọ̀ péye, ó tún yẹ kó ṣe kedere, kó sì rọrùn láti lóye. Wo àpẹẹrẹ kan. Nínú ìwé Róòmù 12:11, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo ọ̀rọ̀ kan tó túmọ̀ ní tààràtà sí “ẹ̀mí tó ń hó.” Àmọ́ lóde òní, bóyá lọ̀rọ̀ yẹn máa nítumọ̀ sí wa. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ṣe sọ ọ́ lọ́nà tó rọrùn láti lóye. Ó sọ pé ó yẹ “kí iná ẹ̀mí máa jó” nínú àwọn Kristẹni.
Ní àfikún sí bí Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ṣe lo orúkọ Ọlọ́run, tí ìtumọ̀ rẹ̀ péye, tó sì rọrùn láti lóye, ó tún yàtọ̀ lọ́nà míì torí pé a kì í tà á. Èyí mú kó rọrùn fún ọ̀pọ̀ mílíọ́nù èèyàn láti rí Bíbélì kà lédè abínibí wọn, títí kan àwọn tágbára wọn ò ká a láti ra Bíbélì.