Ojú Wo Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Ń Wo Ẹ̀kọ́ Ìwé?
Àwọn ìlànà Bíbélì ló ń jẹ́ ká mọ irú ojú tó yẹ ká fi wo ẹ̀kọ́ ìwé. Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀ọ̀kan máa ń fi ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀ tó ti fi Bíbélì kọ́ pinnu bó ṣe máa fi àwọn ìlànà Bíbélì, bí irú èyí tó tẹ̀ lé e yìí, sílò. a
Ẹ̀kọ́ ìwé ṣe pàtàkì
Ẹ̀kọ́ ìwé máa ń jẹ́ kéèyàn ní “ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ àti agbára láti ronú,” Bíbélì sì sọ pé ó dáa gan-an kéèyàn ní àwọn ànímọ́ yìí. (Òwe 2:10, 11; 3:21, 22) Bákan náà, Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa kọ́ àwọn èèyàn lóhun tí òun pa láṣẹ. (Mátíù 28:19, 20) Torí náà, a máa ń ṣèrànwọ́ fáwọn ará wa, a sì máa ń gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n kọ́ ẹ̀kọ́ ìwé nípa oríṣiríṣi nǹkan, irú bí wọ́n ṣe ń kàwé, bí wọ́n ṣe ń kọ̀wé àti béèyàn ṣe lè máa bá àwọn míì sọ̀rọ̀, b tó fi mọ́ ẹ̀kọ́ nípa àwọn ẹ̀sìn míì àtàwọn àṣà ìbílẹ̀ míì.—1 Kọ́ríńtì 9:20-22; 1 Tímótì 4:13.
Ìjọba náà rí bí ẹ̀kọ́ ìwé ṣe ṣe pàtàkì tó, wọ́n sì sábà máa ń fi dandan lé e pé káwọn ọ̀dọ́ lọ sílé ìwé àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ àti ilé ẹ̀kọ́ girama. A máa ń tẹ̀ lé àwọn òfin tí ìjọba ṣe yìí torí Bíbélì pàṣẹ pé: “Kí olúkúlùkù ọkàn wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga,” tàbí àwọn ìjọba. (Róòmù 13:1) Yàtọ̀ síyẹn, a máa ń gba àwọn ọmọ wa níyànjú láti ṣiṣẹ́ kára níléèwé, kí wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe, kí wọ́n má fọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú ẹ̀kọ́ wọn. c Ó ṣe tán, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Gbogbo ohun tó o bá ń ṣe, fi gbogbo ọkàn ẹ̀ ṣe é, bíi pé Olúwa lò ń ṣe é fún, kì í ṣe àwọn èèyàn.”—Kólósè 3:23, Bíbélì Good News Translation.
Ẹ̀kọ́ ìwé máa ń jẹ́ ká lè pèsè fún ìdílé wa. Bíbélì sọ pé, “bí ẹnì kan kò bá pèsè fún àwọn tí í ṣe tirẹ̀, àti ní pàtàkì fún àwọn tí í ṣe mẹ́ńbà agbo ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.” (1 Tímótì 5:8) Ẹ̀kọ́ ìwé máa ń jẹ́ ká lè ṣe ojúṣe tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ pé ká bójú tó ìdílé wa. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé, iṣẹ́ pàtàkì tí ẹ̀kọ́ ìwé ń ṣe ni pé “ó ń jẹ́ káwọn èèyàn wúlò láwùjọ . . . ó ń sọ wọ́n di òṣìṣẹ́.” Ẹni tó kàwé, tó sì mọṣẹ́ ṣeé fọkàn tán pé ó máa pèsè fún ìdílé ẹ̀ dáadáa ju ẹni tí ò kàwé, tí ò sì mọṣẹ́.—Òwe 22:29.
Ọ̀nà míì táwọn òbí lè gbà pèsè fáwọn ọmọ wọn ni pé kí wọ́n múra wọn sílẹ̀ di ìgbà táwọn náà máa di géńdé, ipa kékeré kọ́ sì ni lílọ síléèwé ń kó lórí ọ̀rọ̀ yìí. (2 Kọ́ríńtì 12:14) A máa ń rọ àwọn òbí pé, bí wọ́n bá tiẹ̀ ń gbé láwọn àdúgbò tó jẹ́ pé kò sí ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́, tó ti nira láti rán ọmọ lọ síléèwé tàbí tí kò ti bá àṣà ìbílẹ̀ wọn mu láti ṣe bẹ́ẹ̀, kí wọ́n rí i pé àwọn jẹ́ kí ọmọ àwọn lọ síléèwé. d A tún máa ń dábàá tó gbéṣẹ́ fáwọn òbí lórí bí wọ́n ṣe lè mójú tó ẹ̀kọ́ ìwé àwọn ọmọ wọn. e
Ó yẹ ká fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ ìwéy
A máa ń fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn àbá tó bá wà lórí ẹ̀kọ́ ìwé. Bíbélì sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Òwe 14:15) Ọ̀nà tá a máa ń gbà fi ìlànà yìí sílò ni pé a máa ń fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn àbá tó wà nípa béèyàn ṣe lè kàwé sí i (lẹ́yìn ilé ẹ̀kọ́ girama) àti iye tó máa náni. Bí àpẹẹrẹ, téèyàn bá lọ kọṣẹ́ ọwọ́, èèyàn sábà máa ń rí nǹkan gidi jèrè láàárín àkókò díẹ̀.
Ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run níye lórí ju ẹ̀kọ́ ìwé lọ. Ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a gbé karí Bíbélì máa ń jẹ́ kéèyàn ní ìmọ̀ Ọlọ́run tó lè gbẹ̀mí ẹni là. Ẹ̀kọ́ ìwé ò lè ṣèyẹn. (Jòhánù 17:3) Ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún máa ń kọ́ èèyàn ní ìwà rere, ìyẹn “òdodo àti ìdájọ́ àti ìdúróṣánṣán, gbogbo ipa ọ̀nà ohun rere pátá.” (Òwe 2:9) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kàwé, kódà a lè fi ìwé tó kà wé yunifásítì òde òní, síbẹ̀ ó gbà pé “ìníyelórí títayọ lọ́lá ti ìmọ̀ nípa Kristi Jésù Olúwa” ló dáa jù lọ. (Fílípì 3:8; Ìṣe 22:3) Bẹ́ẹ̀ náà ló rí lónìí, ọ̀pọ̀ nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ti lọ sílé ìwé gíga, síbẹ̀ wọ́n gbà pé ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run táwọn ń kọ́ ṣeyebíye ju ẹ̀kọ́ ìwé lọ. f
Ilé ẹ̀kọ́ gíga lè ṣàkóbá fúnni nínú ìwà àti ìjọsìn Ọlọ́run
Òwe Bíbélì kan sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́.” (Òwe 22:3) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kíyè sí i pé ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ láwọn yunifásítì kan àtàwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga míì lè kọ́ ọmọ kan ní ìwàkiwà, kó sì kó bá ìjọsìn ẹ̀ sí Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló pinnu pé àwọn ò ní lọ sírú ibi tó lè ṣàkóbá yìí, àwọn ò sì ní rán ọmọ àwọn lọ síbẹ̀. Wọ́n gbà pé àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga sábà máa ń kọ́ àwọn èèyàn ní àwọn àṣìlóye tá a tò sísàlẹ̀ yìí:
Àṣìlóye: Owó máa ń fúnni láyọ̀, ó sì máa ń dáàbò boni
Wọ́n sábà máa ń fi kọ́ àwọn èèyàn pé tí wọ́n bá fẹ́ ríṣẹ́ olówó ńlá, àfi kí wọ́n kàwé gíga, torí ẹ̀ ló ṣe jẹ́ pé àwọn ọmọ iléèwé tó ń lọ yunifásítì ń pọ̀ sí i torí àtilówó. Èrò àwọn kan ni pé táwọn bá ti lówó, àwọn máa láyọ̀, àwọn á sì máa gbé ní ààbò, àmọ́ Bíbélì jẹ́ ká rí i pé irọ́ gbuu ni. (Oníwàásù 5:10) Èyí tó tiẹ̀ ṣe pàtàkì jù ni pé, Bíbélì tún fi kọ́ wa pé “ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo,” ó sì sábà máa ń jẹ́ kéèyàn kúrò nínú ìgbàgbọ́. (1 Tímótì 6:10) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń sapá gidigidi kí “agbára ìtannijẹ ọrọ̀” má bàa dẹkùn mú wa.—Mátíù 13:22.
Àṣìlóye: Ilé ẹ̀kọ́ gíga máa ń sọ èèyàn dẹni ńlá àti ẹni iyì láwùjọ
Bí àpẹẹrẹ, Nika Gilauri, tó jẹ́ olórí orílẹ̀-èdè Jọ́jíà tẹ́lẹ̀, kọ̀wé nípa èrò táwọn ọmọ ìbílẹ̀ rẹ̀ sábà máa ń ní, ó ní: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ di dandan pé kẹ́ni tó bá fẹ́ kí wọ́n gba tòun láwùjọ ní Jọ́jíà gboyè jáde ní yunifásítì. . . . [Nígbà àtijọ́,] ìtìjú làwọn ọ̀dọ́ tí kò bá gboyè jáde ní yunifásítì jẹ́ fáwọn mọ̀lẹ́bí wọn.” g Àmọ́ ohun tí Bíbélì kọ́ wa yàtọ̀ sí èyí, ó kìlọ̀ fún wa pé ká má ṣe wá ipò ńlá nínú ayé yìí. Jésù sọ fáwọn aṣáájú ẹ̀sìn tí wọ́n ń wá ògo nígbà ayé rẹ̀ pé: “Báwo ni ẹ ṣe lè gbà gbọ́, nígbà tí ẹ ń tẹ́wọ́ gba ògo láti ọ̀dọ̀ ara yín?” (Jòhánù 5:44) Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní yunifásítì àti ohun tí wọ́n ń kọ́ níbẹ̀ lè mú kéèyàn ní ẹ̀mí ìgbéraga, Ọlọ́run sì kórìíra ìwà yìí.—Òwe 6:16, 17; 1 Pétérù 5:5.
Àṣìlóye: Kálukú ló yẹ kó pinnu ìlànà tóun á máa tẹ̀ lé lórí ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́
Ìlànà tí Ọlọ́run fi lélẹ̀ lórí ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́ làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé. (Aísáyà 5:20) Àmọ́ àpilẹ̀kọ kan tó jáde nínú ìwé Journal of Alcohol and Drug Education sọ pé ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe ló máa ń jẹ́ kí ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní yunifásítì “ṣe àwọn ìpinnu tó yàtọ̀ sí ohun tí wọ́n gbà tẹ́lẹ̀ pé ó tọ́ àtèyí tí kò tọ́.” h Ohun tí àpilẹ̀kọ yẹn sọ bá ìlànà Bíbélì yìí mu, tó sọ pé: “Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:33) Àwọn ìwà tí Ọlọ́run ò fẹ́, bí ìmutípara, lílo oògùn olóró àti ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó wọ́pọ̀ gan-an ní yunifásítì, àwọn èèyàn sì máa ń gbé e lárugẹ níbẹ̀.—1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; 2 Kọ́ríńtì 7:1.
Àṣìlóye: Ẹ̀kọ́ iléèwé gíga ló lè bá wa tún ayé ṣe lọ́nà tó dáa jù
A mọ̀ pé kì í ṣe torí owó, ipò ńlá tàbí torí ìgbádùn tí kò tọ́ ni ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga, torí àtitún ìgbésí ayé wọn ṣe, kí wọ́n sì tún ayé ṣe ni ọ̀pọ̀ ṣe ń lọ. Ohun tó dáa ni wọ́n ní lọ́kàn lóòótọ́, àmọ́ ojú táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń wo nǹkan yàtọ̀ síyẹn. Bíi ti Jésù, Ìjọba Ọlọ́run nìkan la gbà pé ó lè tún ayé ṣe. (Mátíù 6:9, 10) Àmọ́ kì í kàn ṣe pé a jókòó tẹtẹrẹ, tá à ń retí pé kí Ìjọba náà dé, kó wá yanjú ìṣòro ayé. Kàkà bẹ́ẹ̀, bíi ti Jésù, à ń kéde “ìhìn rere Ìjọba yìí” káàkiri ayé, a sì ń ran ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn lọ́wọ́ lọ́dọọdún láti yí ìgbésí ayé wọn pa dà sí rere. i—Mátíù 24:14.
a Àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ṣì ń gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn máa ń ṣe ohun tí òbí wọn bá fẹ́ tó bá dọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ ìwé, tí kò bá ṣáà ti ta ko òfin Ọlọ́run.—Kólósè 3:20.
b Torí èyí, a ti tẹ àwọn ohun tá a fi ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ̀-ọ́n-kọ mọ̀-ọ́n-kà jáde ní iye tó ju mílíọ̀nù mọ́kànlá (11,000,000) lọ, àpẹẹrẹ kan ni ìwé Apply Yourself to Reading and Writing. A sì ń kọ́ àwọn èèyàn kárí ayé láti mọ̀-ọ́n-kọ mọ̀-ọ́n-kà ní ọgọ́fà (120) èdè. Láàárín ọdún 2003 sí 2017, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin (70,000) làwọn tá a kọ́ bí wọ́n ṣe ń kàwé àti bí wọ́n ṣe ń kọ̀wé.
c Wo àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Ṣé Kí N Fi Iléèwé Sílẹ̀?”
d Bí àpẹẹrẹ, a máa ń rọ àwọn òbí láti rán àwọn ọmọ wọn lọ́kùnrin àti lóbìnrin lọ síléèwé. Wo àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí Ọmọ Mi Lọ Sílé Ẹ̀kọ́?” nínú Ilé Ìṣọ́ March 15, 2003.
e Wo àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Bó O Ṣe Lè Ran Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Kí Máàkì Rẹ̀ Lè Gbé Pẹ́ẹ́lí.”
f Wo abala “Èrò Àwọn Èèyàn Nípa Ìṣẹ̀dá” lórí ìkànnì jw.org.
g Practical Economics: Economic Transformation and Government Reform in Georgia 2004—2012, ojú ìwé 170.
h Ìdìpọ̀ 61, No. 1, April 2017, ojú ìwé 72.
i Wo abala “Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà” lórí ìkànnì jw.org kó o lè rí ìtàn ìgbésí ayé àwọn èèyàn tó máa jẹ́ kó o rí bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ọ̀rọ̀ Ìjọba náà ṣe lágbára tó.