Kí Nìdí Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì Í Fi Ṣayẹyẹ Ọdún Àjíǹde?
Àwọn èrò tí kò tọ́ táwọn èèyàn ní
Irọ́: Ìdí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi ṣe ayẹyẹ ọdún Àjíǹde ni pé wọn kì í ṣe Kristẹni.
Òótọ́: A nígbàgbọ́ pé Jésù Kristi ni Olùgbàlà wa, a sì ń ṣe gbogbo nǹkan tá a lè ṣe láti “tọ ipasẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.”—1 Pétérù 2:21; Lúùkù 2:11.
Irọ́: Ẹ ò gbà gbọ́ pé Jésù jíǹde.
Òótọ́: A gbà pé Jésù jíǹde, àti pé àjíǹde ẹ̀ wà lára ohun pàtàkì táwa Kristẹni gbà gbọ́, a sì ń wàásù ẹ̀ fáwọn èèyàn.—1 Kọ́ríńtì 15:3, 4, 12-15.
Irọ́: Ẹ̀ ń jẹ́ káwọn ọmọ yín pàdánù ayọ̀ táwọn míì máa ń ní lákòókò tí wọ́n ń ṣe ọdún Àjíǹde.
Òótọ́: A nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wa gan-an, a sì ń ṣe gbogbo nǹkan tá a lè ṣe láti kọ́ wọn lóhun tó máa jẹ́ kí wọ́n ní ayọ̀ tòótọ́.—Títù 2:4.
Kí nìdí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi ṣayẹyẹ ọdún Àjíǹde?
Kò sí ibi tí Bíbélì ti sọ pé káwa Kristẹni máa ṣe ayẹyẹ ọdún Àjíǹde.
Jésù pàṣẹ pé ìrántí ikú òun ni ká máa ṣe dípò àjíǹde òun. Ọdọọdún la máa ń ṣe Ìrántí Ikú Jésù lọ́jọ́ tó bá bọ́ sí nínú kàlẹ̀ńdà àwọn Júù.—Lúùkù 22:19, 20.
Àtinú àṣà àwọn tó ń jọ́sìn òrìṣà ìbímọlémọ ni wọ́n ti yọ àwọn nǹkan tí wọ́n ń ṣe nínú ọdún Àjíǹde, ìdí nìyẹn tá a fi gbà pé inú Ọlọ́run ò dùn sí ayẹyẹ náà. Ọlọ́run fẹ́ ká “máa sin òun nìkan ṣoṣo,” inú ẹ̀ kì í sì dùn táwọn èèyàn bá ń ṣe ohun tí kò bá ìfẹ́ rẹ̀ mu nínú ìjọsìn wọn.—Ẹ́kísódù 20:5; 1 Àwọn Ọba 18:21.
Ohun tí Bíbélì sọ ló jẹ́ ká pinnu pé a ò ní ṣe ọdún Àjíǹde. Bíbélì sì rọ̀ wá pé ká máa lo “ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ àti làákàyè” tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu dípò ká kàn máa tẹ̀ lé àṣà àwọn èèyàn. (Òwe 3:21; Mátíù 15:3) Táwọn èèyàn bá fẹ́ mọ èrò wa nípa ọdún Àjíǹde, a máa sọ fún wọn. Àmọ́ a kì í fipá mú wọn láti gba ohun tá a sọ torí a mọ̀ pé ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu ohun táá ṣe.—1 Pétérù 3:15.