Ṣé Èèyàn Lè Kúrò Nínú Ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
Bẹ́ẹ̀ ni. Ohun méjì ni ẹnì kan lè ṣe tó bá fẹ́ kúrò nínú ẹ̀sìn wa:
Ó lè sọ fún wa. Tẹ́nì kan bá pinnu pé òun ò fẹ́ ṣe ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́, ó lè bá wa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ tàbí kó kọ̀wé sí wa.
Ó lè gbé ìgbésẹ̀. Ẹnì kan lè ṣe ohun kan tó máa fi hàn pé òun ò sí lára ẹgbẹ́ ará wa tó wà kárí ayé mọ́. (1 Pétérù 5:9) Bí àpẹẹrẹ, ó lè máa ṣe ẹ̀sìn míì, kó sì jẹ́ kó hàn pé ẹ̀sìn yẹn lòun fẹ́ máa ṣe báyìí.—1 Jòhánù 2:19.
Tẹ́nì kan ò bá wàásù mọ́ tàbí tí kò wá sí ìpàdé yín mọ́ ńkọ́? Ṣé ẹ máa ka ẹni náà mọ́ ara àwọn tó ti kúrò nínú ẹ̀sìn yín ni?
Rárá, a kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹni tó kúrò nínú ẹ̀sìn wa tàbí tó pinnu pé òun ò dara pọ̀ mọ́ wa mọ́ yàtọ̀ sí ẹni tó nígbàgbọ́, àmọ́ tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ò lágbára mọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, tẹ́nì kan ò bá jọ́sìn déédéé tàbí ti ò jọ́sìn mọ́, kì í ṣe pé ó ti kúrò nínú ẹ̀sìn yẹn, ó lè jẹ́ pé onítọ̀hún ti ń rẹ̀wẹ̀sì ni. Dípò tá a fi máa wá pa ẹni náà tì, ṣe la máa ń gbìyànjú láti tù ú nínú, ká sì ràn án lọ́wọ́. (1 Tẹsalóníkà 5:14; Júúdà 22) Tẹ́ni náà bá fẹ́ ká ran òun lọ́wọ́, àwọn alàgbà nínú ìjọ ló máa kọ́kọ́ gbé ìgbésẹ̀ láti ràn án lọ́wọ́ kó lè pa dà sún mọ́ Ọlọ́run.—Gálátíà 6:1; 1 Pétérù 5:1-3.
Àmọ́, àwọn alàgbà ò láṣẹ láti fipá mú ẹnì kan pé kò gbọ́dọ̀ kúrò nínú ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kálukú ló máa pinnu ẹ̀sìn tó máa ṣe. (Jóṣúà 24:15) A gbà pé téèyàn bá fẹ́ sin Ọlọ́run, ó yẹ kó ṣe é látọkàn wá, kò yẹ kí wọ́n fipá mú un.—Sáàmù 110:3; Mátíù 22:37.