Ṣé Ẹ Máa Ń Ṣèrànwọ́ Nígbà Àjálù?
Bẹ́ẹ̀ ni, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣèrànwọ́ nígbà àjálù. Àti Ẹlẹ́rìí àtẹni tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí la máa ń ràn lọ́wọ́ tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, torí ohun tí Bíbélì ní ká ṣe nìyẹn nínú Gálátíà 6:10: “Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.” A tún máa ń gbìyànjú láti tu àwọn tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ sí nínú, a sì máa ń fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbé wọn ró torí ohun tí wọ́n nílò gan-an lásìkò yẹn nìyẹn.—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.
Ìṣètò
Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, àwọn alàgbà ìjọ tó wà lágbègbè náà máa ń kàn sí gbogbo àwọn ará ìjọ kí wọ́n lè mọ̀ bóyà àlàáfíà ni wọ́n wà, kí wọ́n sì lè mọ̀ bóyá wọ́n á nílò ohunkóhun. Àwọn alàgbà náà á wá jábọ̀ ìsọfúnni tí wọ́n bá rí gbà àti ìgbésẹ̀ tí wọ́n bá gbé láti ṣèrànwọ́ fún ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè wọn.
Tí àjálù tó ṣẹlẹ̀ bá kọjá ohun táwọn ìjọ àdúgbò náà lè bójú tó, Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣètò láti pèsè ohun tí wọ́n nílò. Báwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní náà ṣe bójú tó ara wọn nígbà kan tí ìyàn mú nìyẹn. (1 Kọ́ríńtì 16:1-4) Ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè náà máa wá yan Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù láti ṣètò bí ìrànwọ́ ṣe máa dé ọ̀dọ̀ àwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láwọn ibòmíì máa ń yọ̀ǹda àkókò wọn láti wá ràn wọ́n lọ́wọ́, wọ́n sì máa ń fi ohun ìní wọn ṣèrànwọ́.—Òwe 17:17.
Ìnáwó
Táwọn èèyàn bá fi owó ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ọ̀kan lára ohun tá a máa ń fi ṣe ni pé ká fi ṣèrànwọ́ fún àwọn tí àjálù bá dé bá. (Ìṣe 11:27-30; 2 Kọ́ríńtì 8:13-15) Torí pé ṣe làwọn tó ń ṣèrànwọ́ máa ń yọ̀ǹda ara wọn, wọn kì í gbowó iṣẹ́, orí àwọn tí àjálù dé bá la máa ń ná gbogbo owó tí wọ́n bá ṣètò pé ká ná fún wọn sí, a kì í yọ lára rẹ̀ fún àwọn tó ń ṣèrànwọ́. A máa ń fọgbọ́n lo gbogbo ọrẹ tá a bá rí gbà.—2 Kọ́ríńtì 8:20.