Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ìbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì

A rọ̀ ẹ́ pé kó o wá ṣèbẹ̀wò sí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Bẹ́tẹ́lì la sábà máa ń pe àwọn ibí yìí. Àwọn kan lára àwọn ọ́fíìsì yìí ní àwọn àtẹ téèyàn lè wò fúnra ẹ̀.

A Lè Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ṣèbẹ̀wò Pa Dà: Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àti June 1, 2023 làwọn èèyàn ti láǹfààní láti ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni sí i, kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tí wàá fẹ́ ṣèbẹ̀wò sí. Jọ̀wọ́, má ṣe wá fún ìbẹ̀wò tí àyẹ̀wò bá fi hàn pé ó ní àrùn Kòrónà, tàbí tó ń ṣe ẹ́ bí òtútù tàbí ibà, tàbí tó o wà pẹ̀lú ẹnì kan tí àyẹ̀wò fi hàn pé ó ní àrùn náà.

Germany

Jehovas Zeugen

Am Steinfels 1

65618 SELTERS

GERMANY

+49 6483-41-0

Wíwò Ọgbà Wa Yíká

Monday sí Friday

8:00 àárọ̀ sí 11:00 àárọ̀ àti 1:00 ọ̀sán sí 4:00 ìrọ̀lẹ́

Ó máa gba wákàtí 2 láti mú ẹ yí ká ọgbà

O tún lè lo wákàtí kan sí i láti wo ìpàtẹ

Jọ̀ọ́, forúkọ sílẹ̀ ṣáájú tí ẹ̀yin tí ẹ̀ ń bọ̀ bá pọ̀

Àwọn iṣẹ́ tí à ń ṣe níbẹ̀

Ẹ̀ka ọ́fíìsì Central Europe tó wà ní Selters, lórílẹ̀-èdè Germany, ló ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù lórílẹ̀-èdè Austria, Germany, Liechtenstein, Luxembourg àti Switzerland. Wàá rí ìpàtẹ kan tó sọ ìtàn bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe lọ láwọn orílẹ̀-èdè tó wà nílẹ̀ Central Europe yìí. Ẹ̀ka ọ́fíìsì yìí ń tẹ̀wé, wọ́n sì ń kó o ránṣẹ́ sí ìjọ tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25,000] láwọn orílẹ̀-èdè bí ọgọ́rùn-ún [100].

Wa ìwé pẹlẹbẹ tó ń ṣàlàyé ẹ̀ka ọ́fíìsì wa jáde.