Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ìbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì

A rọ̀ ẹ́ pé kó o wá ṣèbẹ̀wò sí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Bẹ́tẹ́lì la sábà máa ń pe àwọn ibí yìí. Àwọn kan lára àwọn ọ́fíìsì yìí ní àwọn àtẹ téèyàn lè wò fúnra ẹ̀.

A Lè Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ṣèbẹ̀wò Pa Dà: Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àti June 1, 2023 làwọn èèyàn ti láǹfààní láti ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni sí i, kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tí wàá fẹ́ ṣèbẹ̀wò sí. Jọ̀wọ́, má ṣe wá fún ìbẹ̀wò tí àyẹ̀wò bá fi hàn pé ó ní àrùn Kòrónà, tàbí tó ń ṣe ẹ́ bí òtútù tàbí ibà, tàbí tó o wà pẹ̀lú ẹnì kan tí àyẹ̀wò fi hàn pé ó ní àrùn náà.

Portugal

Rua Conde Barão, 511

P-2649-513 ALCABIDECHE

PORTUGAL

+351 214-690-600

Wíwo Ọgbà Wa Yíká

Monday sí Friday

8:30 àárọ̀ sí 11:30 àárọ̀ àti 1:30 ọ̀sán sí 4:30 ìrọ̀lẹ́

Ó máa gba wákàtí 1

Àwọn iṣẹ́ tí à ń ṣe níbẹ̀

À ń fí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700] ní orílẹ̀-èdè Portugal, Azores, Madeira, Cape Verde, São Tomé àti Príncipe. À máa ń gba ohùn sílẹ̀, a sì ń ṣe àwọn fídíò lédè European Portuguese àti lédè Àwọn Adití Lọ́nà ti Portuguese.

Wa ìwé pẹlẹbẹ tó ń ṣàlàyé ẹ̀ka ọ́fíìsì wa jáde.