Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ìbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì

A rọ̀ ẹ́ pé kó o wá ṣèbẹ̀wò sí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Bẹ́tẹ́lì la sábà máa ń pe àwọn ibí yìí. Àwọn kan lára àwọn ọ́fíìsì yìí ní àwọn àtẹ téèyàn lè wò fúnra ẹ̀.

A Lè Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ṣèbẹ̀wò Pa Dà: Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àti June 1, 2023 làwọn èèyàn ti láǹfààní láti ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni sí i, kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tí wàá fẹ́ ṣèbẹ̀wò sí. Jọ̀wọ́, má ṣe wá fún ìbẹ̀wò tí àyẹ̀wò bá fi hàn pé ó ní àrùn Kòrónà, tàbí tó ń ṣe ẹ́ bí òtútù tàbí ibà, tàbí tó o wà pẹ̀lú ẹnì kan tí àyẹ̀wò fi hàn pé ó ní àrùn náà.

South Africa

Ìbẹ̀wò sí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì

Ṣó yẹ kéèyàn sọ ṣáájú kó tó ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì? Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ. A fẹ́ kí gbogbo ẹni tó fẹ́ ṣèbẹ̀wò sí bẹ́tẹ́lì kọ́kọ́ sọ fún wa ṣáájú kí wọ́n tó máa bọ̀, yálà àwọn tó ń bọ̀ pọ̀ tàbí wọn ò tó nǹkan ìdí sì ni pé a ò fẹ́ kí èrò pọ̀ jù, a si fẹ́ kí gbogbo ẹni tó wá gbádùn ìbẹ̀wò wọn. A fẹ́ kẹ́ ẹ ti sọ fún wa ní ó kéré tán ọ̀sẹ̀ kan ṣáájú. Àmọ́, ẹ jẹ́ kó ju ọ̀sẹ̀ kan lọ dáadáa tó bá jẹ́ ọjọ́ ọlidé lẹ fẹ́ wá.

Tẹ́ ò bá sọ fún wa ṣáájú, ṣé ẹ ṣì lè ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì? Tẹ́ ò bá sọ fún wa ṣáájú, ó ṣeé ṣe ká má gbà yín láàyè láti rìn yíká ọgbà wa. Ìdí sì ni pé ó níye èèyàn tá a lè mù rìn yíká ọgbà wa lójúmọ́.

Ìgbà wo ló yẹ kẹ́ ẹ dé? Kérò má bàa pọ̀ jù, ẹ jọ̀wọ́, ẹ dé ní ó kéré tán, wákàtí kan kó tó di pé wọ́n máa mú yín rìn yíká.

Báwo lẹ ṣe máa sọ fún wa ṣáájú? Tẹ bọ́tíìnì tá a pè ní “Ṣàdéhùn Ọjọ́ Ìbẹ̀wò.”

Ṣé ẹ lè yí ọjọ́ tẹ́ ẹ fẹ́ wá pa dà tàbí kẹ́ ẹ sọ pé ẹ ò ní lè wá mọ́? Bẹ́ẹ̀ ni. Tẹ bọ́tíìnì tá a pè ní “Wo Ọjọ́ Àdéhùn Tàbí Kó O Yí I Pa Dà.”

Tó bá ṣẹlẹ̀ pé kò sí àyè mọ́ lọ́jọ́ tẹ́ ẹ fẹ́ wá ńkọ́? Ẹ máa wo ìkànnì wa látìgbàdégbà. Àyè máa yọ táwọn kan bá yí ọjọ́ tí wọ́n fẹ́ wá pa dà tàbí tí wọn ò fẹ́ wá mọ́.

Wa Ìwé Pẹlẹbẹ Tó Ń Ṣàlàyé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa jáde

Àwọn Ohun Tó Wà

Ibi Ìgbàlejò Tó Wà ní Ilé Bẹ́tẹ́lì: Ẹ máa rí oríṣiríṣi àwọn fídíò tó ń fi àwọn iṣẹ́ tó ń lọ lábẹ́lẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì hàn àti bí iṣẹ́ Bẹ́tẹ́lì ṣe ń ti ìjọsìn wa lẹ́yìn.

Ibi Ìgbàlejò Tó Wà ní Ibi Ìtẹ̀wé Kejì: Ẹ máa wo àwọn fídíò tó ṣàlàyé àwọn àǹfààní tó wà nínú bá a ṣe ń tú àwọn ìwé wa sí èdè ìbílẹ̀ tá a sì ń tẹ̀ wọ́n jáde. Bákan náà lẹ́ máa lè gun ibì kan níbí tẹ́ ẹ ti máa wo bí ẹ̀rọ̀ ìtẹ̀wé wa ṣe ń ṣiṣẹ́ látòkè. Ẹ tún máa gbádùn àtẹ Bíbélì tó ń fi bí wọ́n ṣe lo orúkọ Ọlọ́run ní àwọn èdè ìbílẹ̀ kan hàn.

Ibi Ìgbàlejò Tó Wà ní Ibi Ìtẹ̀wé Kẹta: Ẹ máa gun ibì kan tẹ́ ẹ ti máa lè rí gbogbo agbègbè ibi tá a ti ń kó ìwé ránṣẹ́, bákan náà lẹ máa rí tẹlifíṣọ̀n kan tó ń sọ ibi tí àwọn ìwé tí wọ́n ń kó ń lọ. Ẹ máa rí àwọn fídíò to fi bá a ṣe ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, bá a ṣe ń kó àwọn ìwé ránṣẹ́ àti bá a ṣe ń ṣe àwọn fídíò àti àtẹ́tísí.

Àfikún Ìsọfúnni: Àwọn ọkọ̀ kéékèèké wà tá a máa gbé àwọn àlejò káàkiri àwọn ibi ìgbàlejò wa. Àwọn àlejò á láǹfààní láti gbádùn oúnjẹ wọn ní Ibi Táwọn Àlejò Ti Lè Sinmi.

Àdírẹ́sì àti Fóònù

1 Robert Broom Drive East

Rangeview

KRUGERSDORP

1739

SOUTH AFRICA

+27 11-761-1002