Ìbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì
A rọ̀ ẹ́ pé kó o wá ṣèbẹ̀wò sí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Bẹ́tẹ́lì la sábà máa ń pe àwọn ibí yìí. Àwọn kan lára àwọn ọ́fíìsì yìí ní àwọn àtẹ téèyàn lè wò fúnra ẹ̀.
A Lè Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ṣèbẹ̀wò Pa Dà: Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àti June 1, 2023 làwọn èèyàn ti láǹfààní láti ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni sí i, kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tí wàá fẹ́ ṣèbẹ̀wò sí. Jọ̀wọ́, má ṣe wá fún ìbẹ̀wò tí àyẹ̀wò bá fi hàn pé ó ní àrùn Kòrónà, tàbí tó ń ṣe ẹ́ bí òtútù tàbí ibà, tàbí tó o wà pẹ̀lú ẹnì kan tí àyẹ̀wò fi hàn pé ó ní àrùn náà.
Taiwan
Ìbẹ̀wò sí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì
Ṣó yẹ kéèyàn sọ ṣáájú kó tó ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì? Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ. A fẹ́ kí gbogbo ẹni tó fẹ́ ṣèbẹ̀wò sí bẹ́tẹ́lì kọ́kọ́ sọ fún wa ṣáájú kí wọ́n tó máa bọ̀, yálà àwọn tó ń bọ̀ pọ̀ tàbí wọn ò tó nǹkan, ìdí sì ni pé a ò fẹ́ kí èrò pọ̀ jù, a sì fẹ́ kí gbogbo ẹni tó wá gbádùn ìbẹ̀wò wọn.
Tẹ́ ò bá sọ fún wa ṣáájú, ṣé ẹ ṣì lè ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì? Tẹ́ ò bá sọ fún wa ṣáájú, ó ṣeé ṣe ká má gbà yín láyè láti rìn yíká ọgbà wa. Ìdí sì ni pé ó níye èèyàn tá a lè mú rìn yíká ọgbà wa lójúmọ́.
Ìgbà wo ló yẹ kẹ́ ẹ dé? Kérò má bàa pọ̀ jù, ẹ jọ̀wọ́, ẹ dé ní ó kéré tán, wákàtí kan kó tó di pé wọ́n máa mú yín rìn yíká.
Báwo lẹ ṣe máa sọ fún wa ṣáájú? Tẹ bọ́tìnì tá a pè ní “Ṣàdéhùn Ọjọ́ Ìbẹ̀wò.”
Ṣé ẹ lè yí ọjọ́ tẹ́ ẹ fẹ́ wá pa dà tàbí kẹ́ ẹ sọ pé ẹ ò ní lè wá mọ́? Bẹ́ẹ̀ ni. Tẹ bọ́tìnì tá a pè ní “Wo Ọjọ́ Àdéhùn Tàbí Kó O Yí I Pa Dà.”
Tó bá ṣẹlẹ̀ pé kò sí àyè mọ́ lọ́jọ́ tẹ́ ẹ fẹ́ wá ńkọ́? Ẹ máa wo ìkànnì wa látìgbàdégbà. Àyè máa yọ táwọn kan bá yí ọjọ́ tí wọ́n fẹ́ wá pa dà tàbí tí wọn ò fẹ́ wá mọ́.
Àdírẹ́sì àti Nọ́ńbà Tẹlifóònù