Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

Ẹ̀bùn Tó Dáa Jù Tí Mo Gbà Láyé Mi

Ẹ̀bùn Tó Dáa Jù Tí Mo Gbà Láyé Mi
  • ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI 1967

  • ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI FINLAND

  • IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀ Ọ̀GÁ NI MÍ NÍDÌÍ TẸNÍÌSÌ

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ

 Ìgbèríko ìlú Tampere tó pa rọ́rọ́ ni mo dàgbà sí lórílẹ̀-èdè Finland. Ìdílé mi ò gba ti ẹ̀sìn tó bẹ́ẹ̀, àmọ́ a fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀kọ́ ìwé, a ò sì fojú kéré kéèyàn níwà tó dáa. Ọmọ ilẹ̀ Jámánì ni mọ́mì mi, nígbà tí mo sì kéré, mo sábà máa ń lọ sí Ìwọ̀ Oòrùn Jámánì, níbi táwọn òbí mi àgbà ń gbé.

 Àtikékeré ni mo ti fẹ́ràn eré ìdárayá. Nígbà tí mo ṣì kéré, oríṣiríṣi eré ìdárayá ni mo máa ń ṣe, àmọ́ nígbà tí mo tó nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́rìnlá (14), mo pinnu pé ìkan ni màá fọwọ́ mú, bọ́ọ̀lù tẹníìsì ni mo wá gbájú mọ́. Nígbà tí mo fi máa pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16), mo ti ń fi dánra wò lẹ́ẹ̀méjì sí ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lójúmọ́. Àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ máa ń kọ́ mi lẹ́ẹ̀méjì, èmi nìkan á wá fi dánra wò tó bá di ìrọ̀lẹ́. Gbígbá tẹníìsì dùn mọ́ mi gan-an, iṣẹ́ ọpọlọ ni, ó sì máa ń jẹ́ kí n lè sáré síbí, sáré sọ́hùn-ún. Lóòótọ́, mo fẹ́ràn kí èmi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi máa jayé, ká ṣáà máa ṣeré jáde lọ mu bíà, mi ò kó síṣòro rí torí ọ̀rọ̀ ọtí àbí oògùn olóró. Tẹníìsì gbígbá ni ṣáá, òun ni mo gbájú mọ́.

 Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17), mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbá tẹníìsì níbi àwọn ìdíje àjọ ATP. a Lẹ́yìn tí mo gbégbá orókè nínú àwọn ìdíje kan, káàkiri ni wọ́n ti mọ̀ mí ní orílẹ̀-èdè wa. Nígbà tí mo di ọmọ ọdún méjìlélógún (22), mo ti wà lára àwọn àádọ́ta (50) tó mọ tẹníìsì gbá jù lọ lágbàáyé.

 Ọ̀pọ̀ ọdún ni tẹníìsì gbígbá fi gbé mi rìnrìn àjò káàkiri ayé. Mo rí àwọn ibi tó rẹwà gan-an, àmọ́ ìrìn-àjò mi yẹn tún jẹ́ kí n rí i bí ìṣòro ṣe pọ̀ tó láyé, àwọn ìṣòro bí ìwà ọ̀daràn, lílo oògùn nílòkulò àti bíba àyíká jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí mo wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, wọ́n sọ fún wa pé ká má dé àwọn ibì kan láwọn ìlú kan torí pé ìwà ọ̀daràn pọ̀ gan-an níbẹ̀. Gbogbo àwọn nǹkan yìí ò múnú mi dùn. Àti pé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tí mo fẹ́ràn ni mò ń ṣe, síbẹ̀ náà, ó ń ṣe mí bíi pé nǹkan kan ṣì wà tí mi ò tíì ṣe.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ

 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ Sanna ọ̀rẹ́bìnrin mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó pa mi lẹ́rìn-ín pé Sanna lè gba ti ẹ̀sìn tóyẹn, àmọ́ mi ò dí i lọ́wọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ tó ń ṣe. Nígbà tó di ọdún 1990, a ṣègbéyàwó, ọdún tó tẹ̀ lé e ló sì ṣèrìbọmi, tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́ èmi ò ka ara mi sí ẹni tó gba ti ẹ̀sìn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo gbà pé Ọlọ́run wà lóòótọ́. Mo rántí pé ìyá mi àgbà tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Jámánì máa ń ka Bíbélì gan-an, kódà wọ́n kọ́ mi bí wọ́n ṣe ń gbàdúrà.

 Lọ́jọ́ kan, èmi àti Sanna lọ kí tọkọtaya kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílé. Èyí ọkọ tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Kari wá fi àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” hàn mí. (2 Tímótì 3:​1-5) Ó wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, torí mo rí i pé àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ló jẹ́ kí n lóye ìdí tí nǹkan fi bà jẹ́ tó báyìí láyé. Lọ́jọ́ yẹn, a ò fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹ̀sìn. Àtìgbà yẹn ni èmi àti Kari ti wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì, gbogbo ohun tí mo sì kọ́ ló nítumọ̀ sí mi. Torí pé ọwọ́ mi máa ń dí gan-an, tí mo sì sábà máa ń rìnrìn àjò, ó jẹ́ kó ṣòro fún wa láti máa ríra déédéé, àmọ́ Kari ò jẹ́ kó sú òun. Ṣe ló máa ń kọ lẹ́tà sí mi láti dáhùn àwọn ìbéèrè tí mo bá béèrè nígbà tá à ń kẹ́kọ̀ọ́. Gbogbo àwọn ìbéèrè pàtàkì nígbèésí ayé ni Bíbélì dáhùn lọ́nà tó mọ́gbọ́n dání. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í rí ohun tí Bíbélì dá lé gan-an, ìyẹn ni pé Ìjọba Ọlọ́run máa mú kí ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn ṣẹ. Ó wú mi lórí gan-an nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ nípa orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, tí mo sì rí ohun tó ti ṣe fún wa. (Sáàmù 83:18) Èyí tó wọ̀ mí lọ́kàn jù ni ti ẹbọ ìràpadà tó pèsè, kì í ṣe ohun kan tá a lẹ́tọ̀ọ́ sí lọ́nà ti òfin tàbí tí kò ná Ọlọ́run ní nǹkan kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa ló jẹ́ kó pèsè ẹ̀. (Jòhánù 3:​16) Mo tún kẹ́kọ̀ọ́ pé àǹfààní wà fún mi láti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, kí n sì wà láàyè títí láé nínú párádísè ní àlàáfíà. (Jákọ́bù 4:8) Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í bi ara mi pé, “Báwo ni mo ṣe lè fi hàn pé mo mọrírì àwọn nǹkan yìí?”

 Mo jókòó, mo ro ọ̀rọ̀ ayé mi. Mò ń kọ́ ọ nínú Bíbélì pé ohun tó ń fúnni láyọ̀ jù lọ ni kéèyàn máa fúnni, ó wá wu èmi náà láti máa sọ ohun tí mo gbà gbọ́ fáwọn míì. (Ìṣe 20:35) Torí pé mo gbóná gan-an nídìí eré ìdárayá tí mò ń ṣe, nǹkan bí àròpọ̀ oṣù méje ni mi ò kí ń fi gbélé láàárín ọdún, tí màá máa díje káàkiri. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí mò ń ṣe, iṣẹ́ mi àtàwọn ohun tí mò ń fi àkókò ṣe ló wá ṣe pàtàkì jù, tó ń pinnu bí ìgbésí ayé ìdílé wa ṣe máa rí. Mo rí i pé àfi kí n yí àwọn nǹkan kan pa dà.

 Mo mọ̀ pé tí mo bá tìtorí ẹ̀sìn sọ pé mi ò ṣe eré ìdárayá tó ń mówó wọlé fún mi mọ́, kò ní yé ọ̀pọ̀ èèyàn ìdí tí mo fi ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ àǹfààní tí mo ní láti mọ Jèhófà dáadáa, kí n sì ní ìyè àìnípẹ̀kun ṣeyebíye gan-an ju ẹ̀bùn èyíkéyìí kí n gbà nídìí tẹníìsì, torí náà ó rọrùn fún mi láti pinnu ohun tí màá ṣe. Mo pinnu lọ́kàn mi pé mi ò ní fọkàn sí ohun táwọn míì bá ń sọ, ó ṣe tán, èmi ni mo nìpinnu. Ẹsẹ Bíbélì kan tó ràn mí lọ́wọ́ gan-an tí mo fi borí ìṣòro yẹn ni Sáàmù 118:​6, ó ní: “Jèhófà ń bẹ ní ìhà ọ̀dọ̀ mi; èmi kì yóò bẹ̀rù. Kí ni ará ayé lè fi mí ṣe?”

 Àárín àkókò yìí ni àwọn onígbọ̀wọ́ kan gbéṣẹ́ wá, wọ́n ní tí mo bá ṣe é, màá lè máa gbá tẹníìsì mi lọ fún ọ̀pọ̀ ọdún láìsí ìyọlẹ́nu kankan. Àmọ́ èmi ti pinnu ohun tí mo fẹ́ ṣe ná, bí mo ṣe sọ fún wọn pé mi ò ṣe nìyẹn, mi ò sì lọ́wọ́ sí àwọn ìdíje àjọ ATP mọ́ nígbà tó yá. Mò ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìṣó, nígbà tó sì di July 2, 1994, mo ṣèrìbọmi, mo sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ

 Àjálù kọ́ ló ṣẹlẹ̀ sí mi tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa Ọlọ́run. Kì í sì í ṣe pé mò ń wá òtítọ́. Lójú tèmi, ìgbésí ayé mi dáa níwọ̀ǹba, kò sí nǹkan tí mo tún ń wá. Àmọ́ ṣe ló dà bíi pé mo rìnnà ko òtítọ́. Èmi fúnra mi rí i pé ó nídìí táwa èèyàn fi wà láyé, ìgbésí ayé mi sì ti wá dáa gan-an ju bí mo ṣe rò lọ! Àjọṣe èmi àti ìdílé mi ti lágbára sí i, a sì ti sún mọ́ra ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Inú mi sì dùn gidigidi pé ìpinnu tí mo ṣe làwọn ọmọkùnrin mi mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ṣe, kì í ṣe láti di eléré ìdárayá o, àmọ́ láti di Kristẹni.

 Mo ṣì máa ń gbádùn kí n máa gbá tẹníìsì. Látọdún yìí wá, àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ tẹníìsì gbígbá náà ni mo fi ń gbọ́ bùkátà ìdílé mi, bí àpẹẹrẹ, mò ń ṣe kóòṣì níbì kan tí wọ́n ti ń gbá tẹníìsì, èmi sì ni máníjà ibẹ̀. Àmọ́ kì í ṣe eré ìdárayá ni mo gbájú mọ́ lọ́tẹ̀ yìí. Tẹ́lẹ̀, ọ̀pọ̀ wákàtí ni mo fi máa ń dára mi lẹ́kọ̀ọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ kí n lè mọ tẹníìsì gbá sí i, kí n sì lè mókè. Àmọ́ ní báyìí, mo ti di òjíṣẹ́ tó ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù, inú mi sì ń dùn láti fi àkókò mi kọ́ àwọn míì ní àwọn ìlànà Bíbélì tó yí ìgbésí ayé mi pa dà kí àwọn náà lè fi sílò. Ohun tó ń múnú mi dùn jù lọ ni bí mo ṣe fi àjọṣe èmi àti Jèhófà Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ láyé mi, tí mo sì gbájú mọ́ sísọ fún àwọn míì nípa ìrètí tí mo ní pé ọ̀la ṣì ń bọ̀ wá dáa.​—1 Tímótì 6:​19.

a Àjọ àwọn tó mọ tẹníìsì gbá jù ló ń jẹ́ ATP (Association of Tennis Professionals). Àjọ yìí ló ń darí ẹgbẹ́ àwọn ọkùnrin tó mọ tẹníìsì gbá ní àgbègbè kọ̀ọ̀kan. Oríṣiríṣi ìdíje ni wọ́n máa ń ṣe, wọ́n sì máa ń fún àwọn tó bá gbégbá orókè ní máàkì àti owó. Bí máàkì tí ẹnì kan gbà nínú gbogbo ìdíje tí wọ́n ṣe bá ṣe pọ̀ tó ló máa pinnu ipò tí ẹni náà máa wà nínú àwọn tó mọ tẹníìsì gbá lágbàáyé.