Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

“Mò Ń Fi Ẹ̀mí Ara Mi Tàfàlà”

“Mò Ń Fi Ẹ̀mí Ara Mi Tàfàlà”
  • Ọdún Tí Wọ́n Bí Mi: 1978

  • Orílẹ̀-èdè Mi: El Salvador

  • Irú Ẹni Tí Mo Jẹ́ Tẹ́lẹ̀: Oníwà Ipá Ni Mí, Mo Wà Nínú Ẹgbẹ́ Ọmọ Ìta

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ

 Lọ́jọ́ kan, ẹnì kan sọ fún mi pé, “Tó bá jẹ́ pé òótọ́ lo fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló lè kọ́ ẹ, má fi wọ́n sílẹ̀ o.” Ẹnu yà mí nígbà tí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ yẹn. Lákòókò yẹn, ó ti ṣe díẹ̀ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ kẹ́ ẹ lè mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára mi, ẹ jẹ́ n ṣàlàyé díẹ̀ fún yín nípa ìgbésí ayé mi.

 Ìlú kan tó ń jẹ́ Quezaltepeque ni wọ́n bí mi sí lórílẹ̀-èdè El Salvador. Èmi ni ọmọ kẹfà nínú ọmọ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) táwọn òbí mi bí. Àwọn òbí mi gbìyànjú láti tọ́ mi kí n lè jẹ́ olóòótọ́, kí má sì máa rúfin. Yàtọ̀ sáwọn òbí mi, Leonardo àtàwọn míì tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà sábà máa ń wá kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ mi ò ka ohun tí wọ́n ń kọ́ mi sí, ohun tí kò dáa ni mò ń ṣe ṣáá. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá (14), mo bẹ̀rẹ̀ sí í mu ọtí, èmi àtàwọn ọmọ iléèwé mi sì jọ ń lo oògùn olóró. Ìkọ̀ọ̀kan làwọn ọmọ yẹn ń fi iléèwé sílẹ̀, tí wọ́n lọ ń wọ ẹgbẹ́ ọmọ ìta, bémi náà ṣe fara wé wọn nìyẹn, tí mo lọ wọ ẹgbẹ́ ọmọ ìta. Ṣe la máa ń fẹsẹ̀ gbálẹ̀ kiri ìgboro, tí àá máa fipá gbowó lọ́wọ́ àwọn èèyàn, tá a sì tún ń jalè. Ibẹ̀ la ti ń rówó ná sórí àwọn ìwà burúkú tá à ń hù.

 Àwọn ọmọ ìta ẹgbẹ́ mi ni mo kà sí mọ̀lẹ́bí. Mo gbà pé tiwọn ló yẹ kí n máa ṣe. Bí àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ kan, ọmọ ìta ẹgbẹ́ mi kan to ti yó lọ lu ẹnì kan tá a jọ ń gbé ládùúgbò. Lọ̀rọ̀ bá dìjà, àmọ́ ẹni yẹn rí ọ̀rẹ́ mi mú mọ́lẹ̀, ó sì pe ọlọ́pàá. Bínú ṣe bí mi nìyẹn, mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í kó kùmọ̀ bo mọ́tò ọkùnrin yẹn, lérò pé á fi ọ̀rẹ́ mi sílẹ̀ kó máa lọ. Bí mo ṣe ń fọ́ gíláàsì mọ́tò náà níkọ̀ọ̀kan, tí mo sì ń ba ara mọ́tò náà jẹ́ ni ọkùnrin yẹn ń bẹ̀ mí pé o ti tó, àmọ́ mi ò dá a lóhùn.

 Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìdínlógún (18), èmi àtàwọn ọmọ ẹgbẹ́ mi wọ̀jà pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá. Ni mo bá lọ mú bọ́ǹbù kan tá a ṣe fúnra wa, bí mo ṣe ní kí n jù ú báyìí ló bú gbàù mọ́ mi lọ́wọ́. Mi ò mọ bí mo ṣe ṣe é. Ohun tí mo rántí ò ju pé ọwọ́ mi já yánnayànna, bí mo ṣe dákú nìyẹn. Nígbà tí mo lajú nílé ìwòsàn, wọ́n sọ fún mi pé ọwọ́ ọ̀tún mi ti bà jẹ́ kọjá àtúnṣe, pé etí ọ̀tún mi ò gbọ́rọ̀ mọ́, díẹ̀ ló sì kù kí ojú ọ̀tún mi fọ́.

 Àmọ́ pẹ̀lú bí mo ṣe fara pa tó, lẹ́yìn tí wọ́n dá mi sílẹ̀ nílé ìwòsàn, ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ìta ẹgbẹ́ mi ni mo forí lé. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn tí ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá tẹ̀ mí, tí wọ́n sì rán mi lọ sẹ́wọ̀n. Ibẹ̀ ni èmi àtàwọn ọmọ ìta tá a jọ wà nínú ẹgbẹ́ ti wá mọwọ́ ara wa sí i. A jọ máa ń ṣe nǹkan ni látàárọ̀ ṣúlẹ̀, àá kọ́kọ́ jọ fagbó tá a bá fẹ́ jẹun láàárọ̀, àá sì jọ ṣe oríṣiríṣi nǹkan míì títí a fi máa sùn lálẹ́.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ

 Nígbà tí mo wà lẹ́wọ̀n, Leonardo wá wò mí. Bá a ṣe jọ ń sọ̀rọ̀, ó nàka sí àmì mẹ́ta kan tí mo fín sí apá mi ọ̀tún, ó wá bi mí pé, “Ṣó o mọ ohun tí àmì mẹ́ta tó o fín sápá yìí túmọ̀ sí?” Mo ní, “Mo mọ̀ ọ́n dáadáa, ìbálòpọ̀, oògùn olóró àti fàájì ló ń tọ́ka sí.” Àmọ́ Leonardo dá mi lóhùn pé: “Ohun tó túmọ̀ sí lójú tèmi ni, ilé ìwòsàn, ẹ̀wọ̀n àti ikú. Wọ́n ti gbé ẹ lọ sílé ìwòsàn, ẹ̀wọ̀n lo wà báyìí. Ìwọ náà mọ ohun tó kàn.”

 Àyà mi là gààrà bí Leonardo ṣe sọ̀rọ̀ yẹn. Òótọ́ ló kúkú sọ. Ṣe ni mò ń fi ẹ̀mí ara mi tàfàlà pẹ̀lú ìgbésí ayé tí mò ń gbé yìí. Leonardo ní kí n jẹ́ kóun máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo sì gbà. Ohun tí mo kọ́ látinú Bíbélì mú kí n yí ìgbésí ayé mi pa dà. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé “ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:33) Torí náà, ọ̀kan lára ohun tí mo gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣe ni pé kí n wá àwọn ọ̀rẹ́ tuntun. Ìyẹn ni ò jẹ́ kí n bá àwọn ọmọ ẹgbẹ́ mi ṣèpàdé mọ́, tí mo fi wá bẹ̀rẹ̀ sí í lọ síbi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣèpàdé nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n. Níbi ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yẹn, mo pàdé ẹlẹ́wọ̀n kan tó ń jẹ Andrés, inú ọgbà ẹ̀wọ̀n níbẹ̀ ló ti ṣèrìbọmi, ó sì ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó ní ká jọ jẹun àárọ̀. Látìgbà yẹn, bó ṣe di pé mi ò fagbó láàárọ̀ kùtùkùtù mọ́ nìyẹn. Dípò ìyẹn, ṣe ni èmi àti Andrés jọ máa ń jíròrò ẹsẹ Bíbélì kan láràárọ̀.

 Ojú ẹsẹ̀ làwọn ọmọ ẹgbẹ́ mi ti kíyè sí i pé mo ti ń yí pa dà. Bí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀gá ẹgbẹ́ wa ṣe sọ pé òun fẹ́ ká ríra sọ̀rọ̀ nìyẹn. Ẹ̀rù bà mí. Mi ò mọ ohun tó máa ṣe fún mi tó bá gbọ́ ohun tí mò ń gbèrò àtiṣe, ìdí sì ni pé ṣàṣà ni ẹni tó bá ti wọ ẹgbẹ́ ọmọ ìta tó máa ń lè kúrò nínú ẹgbẹ́ náà. Ó sọ fún mi pé: “A ti rí i pé o ò bá wa ṣèpàdé mọ́, ìpàdé àwọn Ajẹ́rìí lò ń lọ báyìí. Kí lò ń gbèrò àtiṣe gan-an?” Mo sọ fún un pé mo fẹ́ máa bá ẹ̀kọ́ tí mò ń kọ́ nínú Bíbélì lọ, mo sì fẹ́ yí ìgbésí ayé mi pa dà. Ó yà mí lẹ́nu nígbà tó sọ fún mi pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ yòókù á yọ̀ǹda mi, tí n bá ṣáà ti fẹ̀rí hàn pé lóòótọ́ ni mo fẹ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó wá sọ pé: “Tó bá jẹ́ pé òótọ́ lo fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló lè kọ́ ẹ, má fi wọ́n sílẹ̀ o. A retí pé kó o jáwọ́ nínú ìwà burúkú. Wò ó, mo bá ẹ yọ̀. O ò ṣìnà rárá, ojú ọ̀nà lo wà. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ gan-an. Wọ́n ti kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ rí ní Amẹ́ríkà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì làwọn mọ̀lẹ́bí mi kan. Má bẹ̀rù. Ìwọ ṣáà máa ṣe tìẹ lọ.” Ẹ̀rù ṣì ń bà mí o, àmọ́ lẹ́sẹ̀ kan náà, inú mi dùn dọ́ba. Ṣe ni mò ń fọkàn dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. Mo wá dà bí ẹyẹ tí wọ́n ṣí sílẹ̀ nínú àgò. Ìgbà yẹn lọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yé mi, pé: “Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.”​—Jòhánù 8:​32.

 Àwọn kan lára àwọn tá a jọ ń ṣọ̀rẹ́ tẹ́lẹ̀ tún fi oògùn olóró dán mi wò. Kí n má parọ́, àwọn ìgbà kan wà tí mo gbà á, tí mo sì lò ó. Àmọ́ nígbà tó yá, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ àdúrà àtọkànwá tí mo gbà sí Ọlọ́run, mo borí àwọn ìwàkiwà tí mò ń hù.​—Sáàmù 51:​10, 11.

 Lẹ́yìn tí wọ́n tú mi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, ọ̀pọ̀ ló gbà pé màá pa dà sí ìgbé ayé mi àtijọ́, àmọ́ mi ò ṣe bẹ́ẹ̀. Ńṣe ni ìgbé ayé mi yí pa dà. Mo sábà máa ń pa dà lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n láti fi ohun tí mo ti kọ́ nínú Bíbélì han àwọn ẹlẹ́wọ̀n míì. Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ló wá dá àwọn ọ̀rẹ́ mi àtijọ́ lójú pé mo ti yíwà pa dà. Àmọ́ ó ṣeni láàánú pé kò rí bẹ́ẹ̀ lára àwọn tó jẹ́ ọ̀tá mi nígbà yẹn.

 Lọ́jọ́ kan tí mo lọ wàásù, ṣàdédé ni ẹgbẹ́ ọmọ ìta kan tó jẹ́ ọ̀tá wa nígbà yẹn yí èmi àti ẹni tá a jọ lọ sóde ìwàásù ká, tàwọn ti ohun ìjà, wọ́n sì fẹ́ pa mí. Ẹni tá a jọ jáde fi sùúrù àti ìgboyà ṣàlàyé fún wọn pé mi ò sí nínú ẹgbẹ́ ọmọ ìta mọ́. Ṣe ni èmi náà rọra dúró jẹ́ẹ́. Wọ́n lù mí, wọ́n sì kìlọ̀ fún mi pé mi ò gbọ́dọ̀ dé àdúgbò yẹn mọ́. Wọn gbé ọwọ́ ìjà wọn wálẹ̀, wọ́n sì ní ká máa lọ. Bíbélì ti yí ìgbésí ayé mi pa dà gan-an o. Ká ní tẹ́lẹ̀ ni, màá ti wá bí màá ṣe gbẹ̀san. Àmọ́ ní báyìí, ìlànà Bíbélì tó wà ní 1 Tẹsalóníkà 5:​15 ni mò ń tẹ̀ lé, tó sọ pé: “Ẹ rí i pé ẹnì kankan kò fi ìṣeniléṣe san ìṣeniléṣe fún ẹnikẹ́ni mìíràn, ṣùgbọ́n nígbà gbogbo ẹ máa lépa ohun rere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì àti sí gbogbo àwọn ẹlòmíràn.”

 Àtìgbà tí mo ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mo ti ń sapá láti jẹ́ olóòótọ́. Kò rọrùn lóòótọ́, àmọ́ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run, ìmọ̀ràn Bíbélì àtàwọn ọ̀rẹ́ tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ní, mo ti ṣàṣeyọrí. Mi ò fẹ́ pa dà sídìí àwọn ìwà tí mò ń hù tẹ́lẹ̀ mọ́ láé.​—2 Pétérù 2:​22.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ

 Oníwà ipá ni mí tẹ́lẹ̀, mo sì máa ń bínú gan-an. Ó dá mi lójú pé ká ní mi ò jáwọ́ nínú ìwà ipá tí mò ń hù yẹn ni, mi ò bá ti kú dànù báyìí. Ohun tí mo kọ́ nínú Bíbélì ti yí ìgbésí ayé mi pa dà. Mo ti jáwọ́ nínú àwọn ìwà burúkú tí mò ń hù. Mo sì kọ́ bí mo ṣe lè máa wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn tó jẹ́ ọ̀tá mi tẹ́lẹ̀. (Lúùkù 6:​27) Mo sì ti ní àwọn ọ̀rẹ́ gidi báyìí tí wọ́n ń jẹ́ kí n lè máa hùwà tó dáa. (Òwe 13:20) Ìgbésí ayé mi nítumọ̀, mo sì ń láyọ̀, mò ń sin Ọlọ́run tó ti múra tán láti dárí gbogbo àìdáa tí mo ti ṣe jì mí.​—Aísáyà 1:​18.

 Lọ́dún 2006, mo lọ sílé ẹ̀kọ́ kan táwọn Kristẹni tó ń wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n ṣì jẹ́ àpọ́n, ti ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà ni èmi àti ìyàwó mi àtàtà ṣègbéyàwó, a sì jọ ń tọ́ ọmọbìnrin tá a bí. Ní báyìí, mò ń lo èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò mi láti kọ́ àwọn míì ní àwọn ìlànà Bíbélì tó ti ràn mí lọ́wọ́. Alàgbà tún ni mí nínú ìjọ tí mo wà, mo sì ń ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n má bàa ṣerú àṣìṣe tí mo ṣe nígbà tí mo kéré bíi tiwọn. Dípò kí n máa fẹ̀mí ara mi tàfàlà, ṣe ni mò ń múra sílẹ̀ báyìí de ìyè ayérayé tí Ọlọ́run ṣèlérí nínú Bíbélì.