BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ
Mo Rí Ọrọ̀ Tòótọ́
Ọdún Tí Wọ́n Bí Mi: 1968
Orílẹ̀-èdè mi: Amẹ́ríkà
Irú ẹni tí mo jẹ́ tẹ́lẹ̀: Ọ̀gá oníṣòwò tó gbàdúrà kí òun di ọlọ́rọ̀
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀
Inú ẹ̀sìn Kátólíìkì ni wọ́n tọ́ mi dàgbà sí nílùú Rochester, ní ìpínlẹ̀ New York. Àwọn òbí mi bẹ̀rẹ̀ sí í gbé lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́jọ. Torí náà, mò ń gbé pẹ̀lú màmá mi ní àárín ọ̀sẹ̀ nínú ilé tí wọ́n kọ́ fún àwọn tálákà, tó bá sì di òpin ọ̀sẹ̀, màá lọ sọ́dọ̀ bàbá mi níbi táwọn olówó ń gbé. Mo rí bó ṣe nira tó fún màmá mi láti tọ́ àwa ọmọ mẹ́fà, torí náà ó ń wù mí kí n di olówó kí n lè gbọn ìyà nù kúrò lára ìdílé mi.
Bàbá mi fẹ́ kí n di ẹni ńlá, torí náà wọ́n mú mi lọ sí ilé ìwé kan tó lórúkọ táwọn èèyàn ti ń kọ́ iṣẹ́ àbójútó òtẹ́ẹ̀lì. Ilé ìwé náà wù mí mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀. Èrò mi ni pé Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí í dáhùn àdúrà mi láti di ọlọ́rọ̀ kí n sì máa láyọ̀. Ọdún márùn-ún ni mo fi kẹ́kọ̀ọ́ nípa àbójútó òtẹ́ẹ̀lì, òfin ìṣòwò àti ètò ìnáwó ilé iṣẹ́, mo sì tún ń ṣiṣẹ́ ní òtẹ́ẹ̀lì kan tí wọ́n ti ń ta tẹ́tẹ́ ní ìlú Las Vegas, ní ìpínlẹ̀ Nevada.
Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún méjìlélógún [22], mo ti di igbá kejì ààrẹ òtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ti ń ta tẹ́tẹ́ náà. Olówó àti ẹni tó rí tajé ṣe làwọn èèyàn ń pè mí, oúnjẹ tó dáa jù lọ ni mo fi ń ṣara rindin ọtí àti wáìnì tó gbówó lórí jù lọ ni mo sì fi ń lògbà. Àwọn ọ̀rẹ́ mi tá a jọ ń ṣiṣẹ́ á ní, “Iṣẹ́ owó yìí ni kó o gbájú mọ́ o, torí pé kò sówó kò séèyàn.” Lójú tiwọn, èèyàn ò lè ní ojúlówó ayọ̀ àfi tó bá lówó lọ́wọ́.
Èmi ni mò ń gbọ́únjẹ fáwọn ọlọ́rọ̀ tó bá wá ta tẹ́tẹ́ nílùú Las Vegas. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lówó lọ́wọ́, ó jọ pé wọn ò láyọ̀. Ìgbà tó yá, èmi náà ò láyọ̀ mọ́. Kódà, bí owó tó ń wọlé fún mi ṣe ń pọ̀ sí i náà ni àníyàn mi ṣe ń pọ̀ sí i, mi ò sì rí oorun sùn. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé bóyá kí n kúkú gbẹ̀mí ara mi. Nígbà tí ọ̀rọ̀ ara mi sú mi, mo gbàdúrà sí Ọlọ́run, mo bi í pé, “Ibo ni mo ti lè rí ojúlówó ayọ̀?”
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ
Nígbà tí mo wà lẹ́nu iṣẹ́ yẹn, méjì lára àwọn ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tí wọ́n ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó wá sí ìlú Las Vegas. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi kì í gba ìwé wọn, mo gbà kí wọ́n máa fi Bíbélì mi kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́tà pupa ni wọ́n fi kọ àwọn ọ̀rọ̀ Jésù nínú Bíbélì mi. Torí pé mo gba gbogbo ọ̀rọ̀ Jésù gbọ́, ọ̀rọ̀ rẹ̀ làwọn ẹ̀gbọ́n mi fi máa ń kọ́ mi. Èmi náà tún máa ń ka Bíbélì tí mo bá dá wà.
Ọ̀pọ̀ ohun tí mo kà yà mí lẹ́nu. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ pé: “Tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ má ṣe máa sọ̀rọ̀ yàùyàù bí àwọn kèfèrí, tí wọ́n rò pé a ó torí ọ̀rọ̀ púpọ̀ gbọ́ tiwọn.” (Mátíù 6:7, Bíbélì The New American Bible) Àlùfáà kan sì ti fún mi ní àwòrán Jésù rí, ó sọ pé tí mo bá gbàdúrà sí àwòrán náà, tí mo ka Àdúrà Olúwa àti Ẹ Yin Màríà Mímọ́ nígbà mẹ́wàá, Ọlọ́run máa fún mi ní iyekíye tí mo bá fẹ́. Ṣùgbọ́n tí mo bá ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ yẹn ní àsọtúnsọ, ṣe kì í ṣe pé mò ń sọ̀rọ̀ yàùyàù nìyẹn? Mo tún ka ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Ẹ má ṣe pe ẹnikẹ́ni ní baba yín ní ayé; nítorí Baba kan lẹ ní ní ọ̀run.” (Mátíù 23:9, Bíbélì NAB) Ni mo bá tún bi ara mi pé, ‘Kí nìdí tí èmi àti àwọn tá a jọ jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì fi ń pe àlùfáà wa ni “Fadá” tó túmọ̀ sí Baba?’
Ìgbà tí mo ka ìwé Jémíìsì ni mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í tún inú rò nípa ọrọ̀ tí mò ń lé. Ní orí 4, Jémíìsì kọ̀wé pé: “Ṣé ẹ ò mọ̀ pé ọ̀tá Ọlọ́run ni jíjẹ́ ọ̀rẹ́ ayé ń sọni dà? Torí náà, ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé ń sọ ara rẹ̀ di ọ̀tá Ọlọ́run.” (Jémíìsì 4:4, Bíbélì NAB) Ẹsẹ 17 ló tiẹ̀ wá wọ̀ mí lákínyẹmí ara jù, ó ní: “Torí pé bí ẹnì kan bá mọ ohun tó dáa láti ṣe tí kò sì ṣe é, ẹ̀ṣẹ̀ ni.” Bí mo ṣe pe àwọn ẹ̀gbọ́n mi nìyẹn tí mo sì sọ fún wọn pé màá fi iṣẹ́ tí mò ń ṣe ní òtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ti ń ta tẹ́tẹ́ sílẹ̀ torí pé ó ń mú kí n lọ́wọ́ sí àwọn ohun tí mo ti wá mọ̀ báyìí pé kò bá Bíbélì mu, tó fi mọ́ tẹ́tẹ́ títa àti ìwọra.
“Ìgbà tí mo ka ìwé Jémíìsì ni mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í tún inú rò nípa ọrọ̀ tí mò ń lé”
Mo fẹ́ kí àjọṣe mi pẹ̀lú Ọlọ́run, pẹ̀lú àwọn òbí mi, àtàwọn tẹ̀gbọ́n tàbúrò mi dán mọ́rán sí i. Kí n lè ní àkókò tó pọ̀ tó láti ṣe bẹ́ẹ̀, mo pinnu pé màá jẹ́ kí ohun tara díẹ̀ tẹ́ mi lọ́rùn. Ṣùgbọ́n kò rọrùn fún mi láti ṣe àtúnṣe. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n fẹ́ fún mi ní ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́ tí mò ń ṣe ni òtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ti ń ta tẹ́tẹ́ náà kí n sì máa gba ìlọ́po méjì tàbí ìlọ́po mẹ́ta owó oṣù tí wọ́n ń ṣan fún mi tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí mo fi ọ̀rọ̀ náà sínú àdúrà, mo pinnu pé mi ò fẹ́ gbé irú ìgbésí ayé yẹn mọ́. Mo fiṣẹ́ sílẹ̀, mo sọ ibi tí màmá mi ń gbé ọkọ̀ sí di ibùgbé àti ibi iṣẹ́. Mo bẹ̀rẹ̀ òwò kékeré, mo máa ń bá àwọn ilé oúnjẹ tẹ ìwé, mo sì ń lẹ̀ ẹ́ mọ́ inú ike dídán pẹlẹbẹ.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ti mú kí n mọ bí mo ṣe lè ṣe ìpinnu tó tọ́, mi ò tíì máa lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn ẹ̀gbọ́n mi béèrè ohun tó fà á tí mi ò fi nífẹ̀ẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo dá wọn lóhùn pé: “Ohun tó fà á ni pé Jèhófà, Ọlọ́run yín, ń tú ìdílé ká. Ọjọ́ kan ṣoṣo tí èmi àti ìdílé mi fi ń gbádùn ara wa ni ọjọ́ Kérésìmesì àti ìgbà tí wọ́n bá ń ṣe ọjọ́ ìbí, ẹ kì í sì í ṣe Kérésìmesì àti ọjọ́ ìbí.” Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀gbọ́n mi bá bú sẹ́kún, ó sì bi mí pé: “Ibo lò ń wà láwọn ọjọ́ yòókù nínú ọdún? A fẹ́ kó o wà pẹ̀lú wa láwọn ọjọ́ yẹn náà. Ṣùgbọ́n ìgbà Kérésìmesì àti ọjọ́ ìbí nìkan lo máa ń wálé, torí pé ìgbà yẹn nìkan ṣoṣo lo rò pé ó yẹ kó o wá.” Ọ̀rọ̀ tó sọ yẹn wọ̀ mí lágbárí, ni èmi náà bá ń bá a sunkún.
Nígbà tí mo wá lóye bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe fẹ́ràn ìdílé wọn tó àti pé ohun tí mo sọ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Mo pinnu pé màá lọ wo bi ìpàdé wọn ṣe máa ń rí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Níbẹ̀ ni mo ti pàdé Kevin, tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́.
Kevin àti ìyàwó rẹ̀ jẹ́ kí ohun tara díẹ̀ tẹ́ wọn lọ́rùn kí wọ́n lè máa fi àkókò tó pọ̀ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye Bíbélì. Lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn, wọ́n rí owó tó tó láti rìnrìn àjò lọ sí Áfíríkà àti Àárín gbùngbùn Amẹ́ríkà kí wọ́n lè lọ máa bá wọn kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n máa ń láyọ̀ gan-an, wọ́n sì fẹ́ràn ara wọn. Mo rò ó lọ́kàn ara mi pé’, ‘Irú ìgbésí ayé tó wù mí rèé.’
Kevin fi fídíò kan hàn mí tó sọ béèyàn ṣe máa ń láyọ̀ tó bá ń ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì, mo sì pinnu pé ohun tí èmi náà á ṣe nìyẹn. Lẹ́yìn tí mo ti fi taratara kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún oṣù mẹ́fà, mo ṣèrìbọmi lọ́dún 1995, mo sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Dípò kí n máa bẹ Ọlọ́run pé kó fún mi ní ọrọ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà pé: “Má ṣe fún mi ní òṣì tàbí ọrọ̀.”—Òwe 30:8.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ
Mo ti ní ọrọ̀ tòótọ́ báyìí—kì í ṣe ọrọ̀ nípa tara o, ọrọ̀ nípa tẹ̀mí ni. Mo pàdé ìyàwó mi ọ̀wọ́n, Nuria, ní orílẹ̀-èdè Honduras, àwa méjèèjì sì ti ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò àti Pànámà. Òótọ́ lọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ pé: “Ìbùkún Jèhófà ló ń sọni di ọlọ́rọ̀, Kì í sì í fi ìrora kún un”!—Òwe 10:22.