Kò Juwọ́ Sílẹ̀ Nígbà Àjálù
Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Virginia, àmọ́ àìsàn kan ń ṣe é tí wọ́n ń pè ní locked-in syndrome. Ó mú kí ara ẹ̀ rọ jọwọrọ. Ó ń ríran, ó ń gbọ́rọ̀, ó lè la ojú ẹ̀, ó sì lè pa á dé. Yàtọ̀ síyẹn, ó lè mi orí ẹ̀ díẹ̀díẹ̀. Àmọ́ kò lè sọ̀rọ̀, kò sì lè jẹun. Kì í ṣe bára Virginia ṣe rí tẹ́lẹ̀ nìyí, ara ẹ̀ le dáadáa, ó sì lágbára tẹ́lẹ̀. Àmọ́ láàárọ̀ ọjọ́ kan lọ́dún 1997, ṣàdédé ni ẹ̀yìn orí ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fà á, ìrora náà kò sì lọ bọ̀rọ̀. Ọkọ ẹ̀ gbé e, ó dilé ìwòsàn, àmọ́ nígbà tó fi máa dìrọ̀lẹ́, ńṣe ló dá kú lọ gbári. Ọ̀sẹ̀ méjì gbáko ló fi wà bẹ́ẹ̀ láìmọra níbi tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn tí àìsàn wọn díjú gan-an. Ara ẹ̀ ti rọ jọwọrọ, ẹ̀rọ ló sì fi ń mí. Nígbà tó jí, kò rántí nǹkan kan, ọjọ́ mélòó kan ló sì fi wà bẹ́ẹ̀, kódà kò dá ara ẹ̀ mọ̀.
Virginia sọ ohun tó wá ṣẹlẹ̀. Ó ní: “Díẹ̀díẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í rántí àwọn nǹkan. Mo gbàdúrà gan-an torí mi ò fẹ́ kú, mi ò sì fẹ́ fi ọmọ mi kékeré sílẹ̀ láìní ìyá. Kí n lè ṣọkàn akin, mo gbìyànjú láti rántí àwọn ẹsẹ Bíbélì tí mo ṣì lè rántí.
“Nígbà tó yá, àwọn dọ́kítà gbé mi kúrò níbi táwọn aláìsàn tọ́rọ̀ wọn díjú wà. Oṣù mẹ́fà ni wọ́n fi ń gbé mi látilé ìwòsàn kan lọ sí òmíì, kódà wọ́n gbé mi débi tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn tó lárùn ọpọlọ kí wọ́n tó dá mi pa dà sílé. Gbogbo ara mi ló rọ jọwọrọ nígbà yẹn, mi ò lè dá ṣe nǹkan kan. Gbogbo nǹkan ló tojú sú mi! Mi ò wúlò fẹ́nì kankan àti fún Jèhófà. Ìdààmú tún bá mi torí pé mi ò lè tọ́jú ọmọ mi.
“Mo bẹ̀rẹ̀ sí í kà nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tọ́rọ̀ wọn jọ tèmi, ohun tí wọ́n sì ń ṣe fún Jèhófà jọ mí lójú gan-an. Torí náà, mo tún èrò mi pa, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ro ohun témi náà lè ṣe. Kí àìsàn yìí tó bẹ̀rẹ̀, mi ò kì í fi bẹ́ẹ̀ ráyè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí n lọ sóde ẹ̀rí, kí n sì gbàdúrà. Àmọ́ ní báyìí, mi ò níbi lọ látàárọ̀ ṣúlẹ̀. Torí náà, dípò kí n máa kárí sọ, ńṣe ni mo wá kúkú tẹra mọ́ ìjọsìn Jèhófà.
“Mo kọ́ bí wọ́n ṣe ń lo kọ̀ǹpútà. Ètò orí kọ̀ǹpútà tó ń lo bí orí ṣe máa ń mì ni mo fi ń tẹ̀wé. Kò rọrùn, àmọ́ ó ń jẹ́ kí n lè máa ka Bíbélì, kí n sì máa wàásù fáwọn èèyàn nípasẹ̀ lẹ́tà tàbí lórí e-mail. Tí mo bá fẹ́ báwọn tó wà lọ́dọ̀ mi sọ̀rọ̀, mo máa ń lo bọ́ọ̀dù tí wọ́n kọ a-b-d sí lára. Ẹni náà á máa fọwọ́ kan àwọn lẹ́tà náà níkọ̀ọ̀kan. Tí kì í bá ṣe èyí tí mo ní lọ́kàn ló fọwọ́ kàn, màá ran ojú; àmọ́ tó bá gbà á, màá pa ojú dé. Bá a ṣe máa ń ṣe é nìyẹn títí á fi di ọ̀rọ̀ àti gbólóhùn. Àwọn arábìnrin kan tó sábà máa ń wà lọ́dọ̀ mi máa ń tètè mọ ohun tí mo fẹ́ sọ. Àmọ́ nígbà míì tí wọ́n bá ṣì í, a máa ń sọ ọ́ dàwàdà.
“Mo máa ń gbádùn kí n wà pẹ̀lú àwọn ará ìjọ. Mo máa ń wo ìpàdé lórí ẹ̀rọ. Màá tẹ ìdáhùn mi jáde, ẹnì kan á sì bá mi kà á jáde tí wọ́n bá béèrè ìbéèrè. Mo tún máa ń wo Ètò Tẹlifíṣọ̀n JW lóṣooṣù pẹ̀lú àwọn ará tá a jọ wà láwùjọ kan náà. a
“Ó ti pé ọdún mẹ́tàlélógún (23) báyìí tí àìsàn yìí ti ń bá mi fínra. Ó sì máa ń bà mí nínú jẹ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́ tó bá ti ń ṣe mí bẹ́ẹ̀, mo máa ń gbàdúrà, mo máa ń wà pẹ̀lú àwọn ará, mo sì máa ń tẹra mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run, ìyẹn kì í jẹ́ kíbànújẹ́ bò mí mọ́lẹ̀. Kódà, lọ́lá ìtìlẹyìn àwọn ará, ó ju ọdún mẹ́fà lọ tí mo fi ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Mò ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe kí n lè jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún Alessandro ọmọ mi, òun náà ti níyàwó báyìí, ó sì ti di alàgbà. Aṣáájú-ọ̀nà déédéé sì lòun àtìyàwó ẹ̀.
“Mo sábà máa ń ro àwọn nǹkan tí màá lè ṣe tí mo bá dé Párádísè. Ohun tí màá kọ́kọ́ fẹ́ ṣe ni pé kí n máa fi ẹnu mi sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà. Á wù mí kí n rìn gba ojú ọ̀nà tí omi ti ń ṣàn, tó láwọn igi lọ́tùn-ún lósì, kí n sì máa wo bí ibẹ̀ ṣe rẹwà. Láti ogún ọdún (20) sẹ́yìn báyìí, omi tó ní èròjà oúnjẹ nìkan ni wọ́n ń fà sí mi lára, torí náà, ó máa wù mí kí n fi ọwọ́ mi já èso ápù lórí igi, kí n sì fi eyín mi bù ú jẹ. Ọmọ ilẹ̀ Ítálì ni mí, torí náà, ó wù mí kí n fúnra mi se àwọn oúnjẹ ilẹ̀ wa tí mo fẹ́ràn, kí n sì gbádùn wọn, àní títí kan èyí tá a máa ń pè ní pizza!
“‘Ìrètí ìgbàlà’ tí mo ní kì í jẹ́ kí n ro èròkérò. (1 Tẹsalóníkà 5:8) Bí mo ṣe máa ń wo ara mi bíi pé mo wà nínú ayé tuntun máa ń fún mi láyọ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ara mi ò le. Àmọ́ ó dá mi lójú pé gbogbo ìyẹn máa tó dópin. Bẹ́ẹ̀ ni, ara mi ti wà lọ́nà láti gbádùn ‘ìyè tòótọ́’ tí Jèhófà ṣèlérí pé òun máa fún wa nínú Ìjọba rẹ̀.”—1 Tímótì 6:19; Mátíù 6:9,10.
a O lè rí ìlujá tó máa gbé ẹ lọ sí Ètò Tẹlifíṣọ̀n JW lórí ìkànnì jw.org.