Kò Mọ Tara Ẹ̀ Nìkan Láìka Àìlera Tó Ní Sí
Maria Lúcia tó wá láti orílẹ̀-èdè Brazil ní àìsàn kan tó máa ń jẹ́ kéèyàn dití, kó sì tún fọ́jú. Adití ni nígbà tí wọ́n bí i, torí náà àtikékeré ló ti kọ́ èdè àwọn adití. Nígbà tó fi máa pé ọmọ ọgbọ̀n (30) ọdún, ojú ẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí í daṣẹ́ sílẹ̀. Síbẹ̀, Maria Lúcia ò fìyẹn pè, ṣe ni inú ẹ̀ máa ń dùn láti wà pẹ̀lú àwọn èèyàn. Ní báyìí tó ti lé lẹ́ni àádọ́rin (70) ọdún, ó ń láyọ̀, ìgbésí ayé ẹ̀ sì nítumọ̀.
Ọdún 1977 ni Maria Lúcia pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, nígbà yẹn ó ṣì ríran. Ó sọ pé: “Mo pàdé Adriano tá a jọ lọ sílé ìwé, kò sì tíì pẹ́ tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó sọ fún mi nípa àwọn ìbùkún tá a máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Lára ohun tó sọ tó wọ̀ mí lọ́kàn ni pé gbogbo èèyàn máa ní ìlera tó dáa. Ohun tó sọ yìí wú mi lórí gan-an débi pé mi ò rò ó lẹ́ẹ̀mejì tí mo fi gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìjọ tó wà ní Rio de Janeiro, níbi tí wọ́n tí ń tú lára ohun tá à ń kọ́ nípàdé sí èdè àwọn adití. Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ kí n lè tẹ̀ síwájú, nígbà tó sì fi máa di July 1978 mo ṣèrìbọmi.”
Nígbà tó yá, Maria Lúcia lọ sí ìjọ míì tí kò ti sí Ẹlẹ́rìí kankan tó gbọ́ èdè àwọn adití. Kò kọ́kọ́ rọrùn níbẹ̀rẹ̀ torí kò gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ nípàdé. Àmọ́, àwọn arábìnrin méjì kan ràn án lọ́wọ́. Wọ́n máa ń jókòó tì í, wọ́n á sì máa kọ àwọn ohun tí wọ́n ń sọ nípàdé sínú ìwé fún un. Maria Lúcia sọ pé: “Tí mo bá délé, mo máa ń ka àwọn ìwé náà lákàtúnkà kí n lè lóye ohun tí wọ́n kọ sínú ẹ̀. Nígbà tó yá, àwọn arábìnrin náà kọ́ èdè àwọn adití, wọ́n sì máa ń bá mi túmọ̀ ohun tí wọ́n ń sọ nípàdé.”
Nígbà tó yá, Maria Lúcia ò ríran mọ́, ìyẹn ò sì jẹ́ kó lè rí ohun táwọn arábìnrin yẹn ń fi ọwọ́ túmọ̀ fún un lédè àwọn adití. Báwo wá ni wọ́n ṣe jọ ń sọ̀rọ̀? Ó sọ pé: “Mo máa ń gbé ọwọ́ mi lé ọwọ́ ẹni tó bá ń bá mi túmọ̀. Ìyẹn ló sì ń jẹ́ kí n lè lóye ohun tó ń sọ.”
Maria Lúcia mọrírì iṣẹ́ takuntakun táwọn tó ń bá a túmọ̀ ń ṣe. Ó sọ pé: “Jèhófà ló fi wọ́n jíǹkí mi, mo sì mọyì wọn gan-an. Bí wọ́n ṣe ń ràn mí lọ́wọ́ ti jẹ́ kí n máa gbádùn àwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká, àtàwọn àpéjọ agbègbè.”
Maria Lúcia ò kẹ̀rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ó máa ń lo èdè táwọn tó dití tó sì tún fọ́jú máa ń lò láti wàásù fáwọn adití tó bá pàdé, bó sì ṣe ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe yìí láti wàásù ìhìn rere fún wọn máa ń yà wọ́n lẹ́nu. Lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn Kòrónà, àbúrò Maria Lúcia tó ń jẹ́ José Antônio tóun náà fọ́jú tó sì dití ràn án lọ́wọ́ láti kọ ọ̀pọ̀ lẹ́tà ránṣẹ́ sáwọn adití. a
Báwo ló ṣe máa ń ṣe é? Ó sọ pé: “Ó ní ike pẹlẹbẹ kan tí wọ́n bá mi ṣe tó jẹ́ kó rọrùn fún mi láti máa kọ ọ̀rọ̀ ní ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan, kí ọ̀rọ̀ náà má sì wọ́. José Antônio máa ń rántí nǹkan dáadáa. Torí náà, ó máa ń sọ àwọn àkòrí àtàwọn ẹsẹ Bíbélì tí mo lè lò nínú lẹ́tà mi, máa sì kọ́ wọ́n sínú ẹ̀. Kì í ṣe gbogbo àwọn adití ló lè ka ohun tí wọ́n bá kọ sílẹ̀. Torí náà mo máa ń sapá láti kọ ọ́ lọ́nà táá fi yé wọn.”
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ojú Maria Lúcia ti fọ́ pátápátá báyìí, ó ṣì máa ń ṣiṣẹ́ kára. Karoline tó wà lára àwọn tó ń bá a túmọ̀ sọ pé: “Fúnra ẹ̀ ló máa ń túnlé ṣe, á ṣe gbogbo iṣẹ́ ilé, gbogbo ìgbà sì ni ilé ẹ̀ máa ń wà ní mímọ́ tónítóní. Bákan náà, ó fẹ́ràn láti máa dáná kó sì pe àwọn míì láti wá bá a jẹun.”
Jefferson tó jẹ́ alàgbà ní ìjọ tí Maria Lúcia wà tún sọ pé: “Maria Lúcia nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tọkàntọkàn. Ó tún nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Ohun tó máa ṣe àwọn míì láǹfààní ló máa ń ṣe ní gbogbo ìgbà, kò sì mọ tara ẹ̀ nìkan.”—Fílípì 2:4.
a José Antônio tó jẹ́ àbúrò Maria Lúcia náà ṣèrìbọmi, ó sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dún 2003. Bíi ti Maria Lúcia, adití lòun náà nígbà tí wọ́n bí i, nígbà tó sì yá, ó fọ́ lójú.