Sọ fún Wọn Pé O Nífẹ̀ẹ́ Wọn
Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Ong-li lórílẹ̀-èdè Bọ̀géríà. Ó kọ́ obìnrin kan tó ń jẹ́ Zlatka lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ ọkọ obìnrin náà ò bá wọn kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní tiẹ̀. Ong-li sọ pé: “Nígbà tá à ń jíròrò nípa ìdílé, mo ṣàlàyé fún un pé ó ṣe pàtàkì gan-an káwa lọ́kọláya máa sọ fún ẹnì kejì wa àtàwọn ọmọ wa pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. Zlatka wò mí sùnsùn, ó bojú jẹ́; ó sọ pé òun ò sọ fún ọkọ òun àti ọmọbìnrin òun tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án rí pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn!”
Zlatka sọ pé, “Kò sóhun tí mi ò lè ṣe fún wọn, àmọ́ àtisọ fún wọn pé mo nífẹ̀ẹ́ wọn yẹn, mi ò lè ṣe é.” Ó tún sọ pé, “Ìyá mi ò sọ fún mi rí pé àwọn nífẹ̀ẹ́ mi, màámi àgbà náà ò sì sọ fún ìyá mi rí pé àwọn nífẹ̀ẹ́ wọn.” Ong-li fi han Zlatka nínú Bíbélì pé Jèhófà sọ ọ́ ketekete fún Jésù pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Mátíù 3:17) Ó wá gba Zlatka níyànjú pé kó gbàdúrà sí Jèhófà lórí ọ̀rọ̀ náà, kó sì fi ṣe àfojúsùn pé òun máa sọ fún ọkọ òun àti ọmọbìnrin òun pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn.
Ong-li sọ pé: “Lẹ́yìn ọjọ́ méjì, tayọ̀tayọ̀ ni Zlatka sọ fún mi pé òun gbàdúrà sí Jèhófà kó ran òun lọ́wọ́. Nígbà tí ọkọ ẹ̀ délé, ó sọ fún un pé òun ti kọ́ ọ nínú Bíbélì pé ó ṣe pàtàkì kí ìyàwó máa bọ̀wọ̀ fún ọkọ ẹ̀, kó sì máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó wá dákẹ́ díẹ̀, ló bá sọ fún ọkọ ẹ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an! Nígbà tí ọmọbìnrin ẹ̀ náà délé, Zlatka dì mọ́ ọn, ó sì sọ fún un pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀! Zlatka sọ fún mi pé: ‘Ṣe lara tù mí pẹ̀sẹ̀. Nǹkan kékeré kọ́ ni mo ti ń bò mọ́ra látọdún yìí wá, ọpẹ́lọpẹ́ Jèhófà, mo ti wá lè sọ fún ọkọ mi àti ọmọ mi bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn tó.’
Ong-li ń bá ọ̀rọ̀ ẹ̀ lọ pé, “Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan, mo pàdé ọkọ Zlatka, ó sì sọ fún mi pé: ‘Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti sọ fún mi pé kí n má jẹ́ kó o kọ́ Zlatka lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́, àmọ́ mo gbà pé ohun tó ń kọ́ nínú Bíbélì ń ṣe ìdílé wa láǹfààní gan-an. A ti wá nífẹ̀ẹ́ ara wa sí i, ilé wa sì ti túbọ̀ tòrò.’”