Ìwé Pélébé Lábẹ́ Ẹ̀rọ Ìfọṣọ
Lẹ́yìn tí Zarina ṣèrìbọmi, tó sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó kúrò ní Rọ́ṣíà lọ sí ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ ní Àárín Gbùngbùn Asia, kó lè kọ́ àwọn ọmọbìnrin ẹ̀ méjèèjì ní ẹ̀kọ́ òtítọ́. Torí pé kò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́, yàrá tí àwọn òbí ẹ̀ ń gbé pẹ̀lú àbúrò ẹ̀ àti ìyàwó àbúrò ẹ̀ lòun àtàwọn ọmọ ẹ̀ náà ń gbé. Àwọn òbí ẹ̀ pàṣẹ fún un pé kò gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Wọ́n sì sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀ pé kí wọ́n má bá ìyá wọn sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì.
Zarina ronú gan-an nípa bó ṣe máa kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀ nípa Jèhófà. (Òwe 1:8) Torí naa, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé kó tọ́ òun sọ́nà, kó sì fún òun ní òye. Zarina wá ṣiṣẹ́ lórí àdúrà tó gbà, ó ń mú àwọn ọmọbìnrin ẹ̀ rìn káàkiri, ó sì máa ń sọ fún wọn nípa àwọn ohun tó yani lẹ́nu lára àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá bí wọ́n ṣe jọ ń rìn. Ìrìn ráńpẹ́ tí wọ́n ń rìn yìí mú kí àwọn ọmọbìnrin ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ Ẹlẹ́dàá.
Zarina wá wọ́nà bó ṣe máa lo ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? a láti mú kí ìfẹ́ yìí túbọ̀ jinlẹ̀ lọ́kàn àwọn ọmọ ẹ̀. Ó kọ àwọn ìpínrọ̀ kan pẹ̀lú ìbéèrè wọn jáde ní tààràtà sínú àwọn ìwé pélébé kan. Ó fi ọ̀rọ̀ díẹ̀ kún un kí ẹ̀kọ́ náà lè yé àwọn ọmọ ẹ̀ dáadáa. Ó wá fi àwọn ìwé pélébé náà àti pẹ́ńsù pa mọ́ sábẹ́ ẹ̀rọ ìfọṣọ tó wà ní balùwẹ̀ wọn. Táwọn ọmọ náà bá wà nínú yàrá wọn, wọ́n máa ń ka àwọn ìpínrọ̀ náà, wọ́n á sì kọ ìdáhùn wọn sílẹ̀.
Ọgbọ́n tí Zarina ń dá sí i nìyẹn tó fi rọ́nà kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀ ní orí méjì nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, kí òun àtàwọn ọmọ ẹ̀ tó rí ibòmíì tí wọ́n kó lọ. Ibẹ̀ ló ti wá ráyè kọ́ wọn dáadáa láìsí ìdíwọ́ kankan mọ́. Àwọn ọmọ méjèèjì ṣèrìbọmi ní October 2016, inú wọn dùn pé ìyá wọn lo ọgbọ́n àti òye kó lè kọ́ wọn nípa Ọlọ́run.
a Ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! ni ọ̀pọ̀ èèyàn ń lò báyìí.