Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kárí Ayé

Greece

  • Monastiraki Square, Athens, Greece—Wọ́n ń fún ẹnì kan ní ìwé ìroyìn Jí!

Ìsọfúnni Ṣókí—Greece

  • 10,482,000—Iye àwọn èèyàn
  • 27,759—Iye àwọn òjíṣẹ́ tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
  • 345—Iye àwọn ìjọ
  • 379—Iye èèyàn tí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan máa wàásù fún

ÌRÒYÌN

Ìtàn Mánigbàgbé: A fi Odindi Àádọ́ta Ọdún Jà fún Ẹ̀tọ́ Tá A Ní Láti Wàásù

Lọ́dún1993, Minos Kokkinakis ja àjàṣẹ́gun nílé ẹjọ́ lẹ́yìn àádọ́ta (50) ọdún tó ti ń jà fún ẹ̀tọ́ tó ní láti wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ọdún yẹn nìgbà àkọ́kọ́ tí ilé ẹjọ́ ECHR máa dá ìjọba orílẹ̀-èdè èyíkéyìí lẹ́bi pé wọ́n fi ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn dù wọ́n, pé wọn ò jẹ́ kí wọ́n jọ́sìn Ọlọ́run fàlàlà.

ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́

Mo Pinnu Pé Ọmọ Ogun Kristi Ni Màá Jẹ́

Wọ́n ju Demetrius Psarras sẹ́wọ̀n torí pé ó kọ̀ láti wọṣẹ́ ológún. Síbẹ̀ kò fi Ọlọ́run sílẹ̀ láìka àwọn àdánwò lílekoko tó kojú.