Àpéjọ Àgbègbè Táwọn Tagalog ṣe ní Róòmù—“Gbogbo Ìdílé Tún Wà Pa Pọ̀!”
Ilé àwọn ará Tagalog sí ìlú Róòmù lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] kìlómítà (ibùsọ̀ 6,200) láti ìlú Philippines, ibẹ̀ sì ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń sọ èdè Tagalog ti wá, wọ́n pàdé ní orílẹ̀-èdè Ítálì ní ìlú Róòmù láti wá ṣe àpéjọ àgbègbè alárinrin kan ní July 24 sí 26, 2015.
Àwọn kan fojú bù ú pé, ó ti lé ní 850,000 ará ilẹ̀ Philippines tó ń gbé ní ìlú Yúróòpù báyìí. Nítorí náà, ìjọ tó tó nǹkan bí ọgọ́ta [60] àti àwọn àwùjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kéékèèké tó wà ní ìlú Yúróòpù ló ń ṣe ìpàdé ní Tagalog tí wọ́n sì ń wàásù fún àwọn ará ilẹ̀ Philippines tó wà ní àgbègbè wọn.
Gbogbo àwọn ìjọ àti àwùjọ yìí ló pàdé pọ̀ ní ìlú Róòmù fún àpéjọ àgbègbè ọlọ́jọ́ mẹ́ta yìí, èyí sì jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa ṣèpàdé ní èdè wọn. Inú àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún méjì àti mọ́kàn dín lógójì [3,239] tó pé jọ dùn bí Arákùnrin Mark Sanderson, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń sìn ní orílẹ̀-èdè Philippines tẹ́lẹ̀, ṣe ń sọ àsọyé tó parí ìpàdé ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.
“Ó Wọ̀ Mí Lọ́kàn Ṣinṣin”
Kí ni ìyàtọ̀ tó wà nínú kéèyàn ṣe àpéjọ àgbègbè lédè abínibí rẹ̀ tàbí kó ṣe é lédè míì? Òbí anìkàntọ́mọ kan tó ń jẹ́ Eva sọ pé: “Mi ò gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì dáadáa, àmọ́ ọpẹ́lọpẹ́ àpéjọ àgbègbè yìí, ńṣe ni ẹ̀kọ́ Bíbélì wọ̀ mí lọ́kàn ṣinṣin.” Torí kó lè rówó rìnrìn àjò láti ilé rẹ̀ ní Sípéènì lọ sí Ítálì, ńṣe ní òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì pinnu pé àwọn ò ní máa jẹun lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ níta mọ́, gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn, àmọ́ ẹ̀ẹ̀kan ni wọ́n á máa ṣe bẹ́ẹ̀ lóṣù. Eva sọ pé: “Ó tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ, torí gbogbo ohun tí wọ́n sọ ní àpéjọ àgbègbè yìí ló yé mi!”
Jasmin, tó ń gbé nílùú Jámánì, gba àyè lẹ́nu iṣẹ́ kó lè wá sí àpéjọ àgbègbè náà. Ó sọ pé: “Kí ń tó kúrò níbi iṣẹ́, wọ́n sọ fún mí pé mo lè má lè lọ, torí iṣẹ́ pọ̀ fún wa láti ṣe. Mo gbàdúrà sí Jèhófà, lẹ́yìn náà mo lọ bá ọ̀gá mi. Bá a ṣe ṣàtúntò àwọn iṣẹ́ wa nìyẹn, kí ń lè lọ sí àpéjọ náà! Inú mi dùn gan-an ni pé mo ní àǹfààní láti wà pẹ̀lú àwọn ará ilẹ̀ Philippines yòókù, àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó wá láti ilẹ̀ Yúróòpù.”
Lóòótọ́, kì í ṣe àárò ilé nìkan ló ń sọ ọ̀pọ̀ àwọn ará ilẹ̀ Philippines tó wà ní Yúróòpù, wọ́n tún ṣàárò àwọn ọ̀rẹ́ wọn tó ti ṣí lọ sí ilẹ̀ Yúróòpù. Àpéjọ àgbègbè yìí tún jẹ́ kí àwọn ọ̀rẹ́ yìí tún pa dà ríra, wọ́n tún wá di arákùnrin àti arábìnrin nípa tẹ̀mí. (Mátíù 12:48-50) Fabrice sọ pé: “Bí mo ṣe ń rí àwọn ẹni mímọ̀ mí fún mi láyọ̀!” Nígbà tí àpéjọ àgbègbè náà fi máa parí, arábìnrin kan wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Gbogbo ìdílé ló tún ti wà pa pọ̀!”