Bí Wọ́n Ṣe Mọ Iná Pa
Sandra àti ọkọ ẹ̀ wà nílé àwọn àna ẹ̀, wọ́n ń jẹun àárọ̀. Ṣàdédé ni Sandra kígbe pé, “Iná! Iná!” Ó rí i tí èéfín ń jáde lábẹ́ ilẹ̀kùn abà kan tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé. Kíá, òun àti Thomas ọkọ ẹ̀ ti dìde kí wọ́n lè wá nǹkan ṣe sí i. Sandra lọ gbé ohun tí wọ́n fi ń paná, Thomas sì sáré lọ wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú abà yẹn. Sandra bá yára gbé ohun tí wọ́n fi ń paná fún Thomas, ó sì paná náà. Sandra ní, “Ká ní a ò ṣe ohun tá a ṣe yẹn ni, ṣe ni abà yẹn ò bá jóná kanlẹ̀.”
Báwo ló ṣe jẹ́ tí jìnnìjìnnì ò bo Thomas àti Sandra, tí wọ́n sì ṣe ohun tó tọ́? Ìdí ni pé àwọn méjèèjì àtàwọn ẹgbẹ̀rún kan (1,000) èèyàn míì tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Selters, lórílẹ̀-èdè Jámánì, ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ lórí ohun tí wọ́n lè ṣe tí iná bá dédé ṣẹ́ yọ.
Ẹ̀ka ọ́fíìsì oní àádọ́rin (70) éékà tó wà nílùú Selters ní àwọn ọ́fíìsì àti ilé gbígbé, ó sì tún ní yàrá ìfọṣọ, ibi ìtẹ̀wé àtàwọn ibi iṣẹ́ lóríṣiríṣi, iná sì lè ṣẹ́ yọ dáadáa láwọn ibi tá a dárúkọ yìí. Torí ẹ̀ ni Ẹ̀ka Tó Ń Rí sí Ààbò àti Àyíká ní ẹ̀ka ọ́fíìsì náà ṣe ṣètò láti dá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípa iná. Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn kan tí wọ́n ń pè ní Àwùjọ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Pàjáwìrì máa ń ṣe ìdánrawò pẹ̀lú ẹ̀ka tó ń rí sí ọ̀rọ̀ iná nílùú náà. Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì náà á máa ṣe àwọn nǹkan yìí déédéé:
Wọ́n á máa fi dánra wò bí wọ́n á ṣe sá jáde tí iná bá bẹ̀rẹ̀.
Wọ́n á máa wá sí ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀rọ̀ iná.
Wọ́n á kọ́ bí wọ́n ṣe lè pa iná tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀.
Èyí máa jẹ́ káwọn tó yọ̀ǹda ara wọn lè mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe tí ọ̀rọ̀ pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀.
Bí Wọ́n Ṣe Ń Fi Iná Pípa Dánra Wò Láìséwu
Láwọn àsìkò tí wọ́n bá ń fi iná pípa dánra wò, ṣe ni wọ́n máa ń ṣe é lọ́nà tí kò fi ní wu wọ́n léwu. Christin, tó jẹ́ pé ilé ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ ló ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀rọ̀ iná gbẹ̀yìn, ṣàlàyé nípa ìdálẹ́kọ̀ọ́ kan tí wọ́n gbà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì. Ó ní: “Nígbà tí mo gbé ohun tí wọ́n fi ń paná, mo ṣí i, mo sì dojú ẹ̀ kọ ibi tí atẹ́gùn ń fẹ́ gbà bí mo ṣe ń tẹ̀ ẹ́. Tí mi ò bá ṣe é bẹ́ẹ̀, ṣe ni iná yẹn ò bá gbì mọ́ mi lójú. Èmi fúnra mi náà ni mo pa iná yẹn! Mo tún kọ́ bí èmi àtàwọn bíi mẹ́rin tàbí márùn-ún ṣe lè jọ paná.”
Daniel, tó ń dá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀rọ̀ iná ní ẹ̀ka ọ́fíìsì sọ pé téèyàn bá ń fi iná pípa dánra wò, ó máa ń “dín ìbẹ̀rù iná kù.” Ó ṣàlàyé pé: “Tí iná bá ṣẹ́ yọ báyìí, àwọn èèyàn kì í sábà mọ ohun tí wọ́n máa ṣe. Ṣe ni jìnnìjìnnì á bò wọ́n, tí wọ́n á máa ronú pé, ‘Kí la mọ̀ tá a fẹ́ ṣe báyìí? Báwo la ṣe máa fi kiní pupa yìí paná?’ Ká ní wọ́n ti mọ nǹkan tí wọ́n máa ṣe ni, á rọrùn fún wọn láti pa iná tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ kó tó di ńlá mọ́ wọn lọ́wọ́.” Láwọn àsìkò ìdálẹ́kọ̀ọ́, ó sọ pé “àwọn tó ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà máa ń kọ́ bí wọ́n á ṣe di ohun tí wọ́n fi ń paná mú dáadáa, tí wọ́n á sì fi paná tó bá ṣẹlẹ̀ pé iná dédé ṣẹ́ yọ. Ọkàn wọn máa ń balẹ̀, wọ́n sì máa ń nígboyà láti gbé ìgbésẹ̀ tó bá ṣẹlẹ̀ pé ọ̀rọ̀ pàjáwìrì ṣẹlẹ̀.”
Ìdálẹ́kọ̀ọ́ Dáa Gan-an
Ọ̀pọ̀ ló ń fi hàn pé àwọn mọrírì ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà. Christin, tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Fúngbà àkọ́kọ́, èmi náà gbé ohun tí wọ́n fi ń paná dání. Ó yẹ kí gbogbo èèyàn gba irú ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí.” Nadja, tó yọ̀ǹda láti máa fi ọjọ́ mélòó kan ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì náà, tó sì tún ń ṣiṣẹ́ ní pápákọ̀ òfuurufú sọ pé: “Láti ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, orí ìwé nìkan ni wọ́n ti ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀rọ̀ iná ní pápákọ̀ òfuurufú tí mo ti ń ṣiṣẹ́. Àmọ́ ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó gbéṣẹ́ tí mo gbà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì ti jẹ́ kí ọkàn mi túbọ̀ balẹ̀. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé iná ṣẹ́ yọ, mo mọ ohun tí màá ṣe.”
Sandra gbà pé ìdálẹ́kọ̀ọ́ tóun ti gbà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì ló jẹ́ kóun lè tètè gbé ìgbésẹ̀ lọ́jọ́ tó lọ sílé àwọn àna ẹ̀ yẹn. Ó ní, “Ẹ̀rù kì í bà mí tó ti tẹ́lẹ̀ mọ́ láti lo ohun tí wọ́n fi ń paná. Ó dáa kéèyàn máa gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọọdún. Ó dájú pé òun ló ràn mí lọ́wọ́.”
Bí Wọ́n Ṣe Ń Ṣe Ìdánrawò Pẹ̀lú Ẹ̀ka Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Iná Nílùú Náà
Ẹ̀ka tó ń rí sí ọ̀rọ̀ iná nílùú náà máa ń ṣe ìdánrawò déédéé nínú ọgbà ẹ̀ka ọ́fíìsì náà. Theo Neckermann tó jẹ́ olórí àwọn panápaná ṣàlàyé ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀, ó ní: “Ẹ̀ka iṣẹ́ wa ló ń rí sí ohun tó ń lọ nílùú Selters. Iná tó bá ṣẹ́ yọ nínú ilé la sábà máa ń pa. Àmọ́ ti ẹ̀ka ọ́fíìsì yìí yàtọ̀ lágbègbè yìí torí pé ibẹ̀ tóbi, àwọn ilé ńláńlá ló wà níbẹ̀, iṣẹ́ tí wọ́n sì ń ṣe níbẹ̀ pọ̀. Àfi ká túbọ̀ jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ wa ká lè bójú tó ọ̀rọ̀ pàjáwìrì tó bá ṣẹlẹ̀ ní ọ́fíìsì yìí. Torí ẹ̀ ni inú wa ṣe ń dùn, tá a sì ń dúpẹ́ pé a lè ṣe ìdánrawò níbí.”
Àwọn tó lé ní ọgọ́rùn-ún (100) tó wà nínú Àwùjọ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Pàjáwìrì ní ẹ̀ka ọ́fíìsì náà máa ń bá ẹ̀ka tó ń rí sí ọ̀rọ̀ iná nílùú ṣe ìdánrawò bí wọ́n ṣe lè dóòlà ẹ̀mí tí iná bá wáyé. Ọ̀gbẹ́ni Neckermann sọ pé: “A kí Àwùjọ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Pàjáwìrì tẹ́ ẹ ní yìí. Láìsí ìrànlọ́wọ́ àti ìtọ́sọ́nà wọn, ìdánrawò àti iṣẹ́ tá à ń ṣe ì bá má lọ dáadáa.”
Ẹ̀ka tó ń rí sí ọ̀rọ̀ iná àti Àwùjọ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Pàjáwìrì pitú ọwọ́ wọn nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan ní February 2014. Ṣe ni èéfín gba inú yàrá kan nínú ọ̀kan lára àwọn ilé gbígbé tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì náà. Daniel tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan rántí pé, “Èéfín yẹn nípọn débi pé a ò ríran rí ọwọ́ wa bá a tiẹ̀ gbé e síwájú ojú wa báyìí. Kíá la kàn sí ẹ̀ka tó ń rí sí ọ̀rọ̀ iná, a sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún àwọn tó wà nínú gbogbo yàrá méjìdínláàádọ́rùn-ún (88) pé kí wọ́n jáde síta. Nígbà tí ẹ̀ka tó ń rí sí ọ̀rọ̀ iná fi máa dé, a ti kó gbogbo àwọn tó wà nínú ilé gbígbé náà jáde.” Ọ̀gbẹ́ni Neckermann sọ pé: “Ká sọ pé ìlú ńlá bíi Frankfurt ni irú èyí ti ṣẹlẹ̀, mi ò rò pé wọ́n máa lè tètè kó gbogbo eèyàn tó ń gbé adúrú ilé ńlá yìí jáde bẹ́ ẹ ṣe ṣe. Ẹ̀yin èèyàn yìí kì í fiṣẹ́ falẹ̀ rárá, a sì gbé òṣùbà ńlá fún Àwùjọ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Pàjáwìrì tẹ́ ẹ ní!” Àwọn panápaná náà rí ohun tó fa iná ọ̀hún, wọ́n sì bójú tó o. Kò sẹ́ni tó fara pa, nǹkan ò sì fi bẹ́ẹ̀ bà jẹ́.
Gbogbo àwọn tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì nílùú Selters ló ń retí pé ọ̀rọ̀ iná tó burú jáì ò ní ṣẹlẹ̀. Àmọ́ tó bá ṣẹlẹ̀, wọ́n ti múra tán láti gbé ìgbésẹ̀ torí wọ́n ti kọ́ bí wọ́n ṣe lè pa iná, kí wọ́n sì ṣàṣeyọrí.