Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Pa Àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa Kan Pọ̀Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pa àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa kan pọ̀
Ní September 2012, a pa àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó lé ní mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] pọ̀, a sì ní káwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì tó tóbi máa bójú tó àwọn ilẹ̀ tọ́rọ̀ náà kàn.
Bákan náà, a ti dá àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun míì sílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Serbia àti Macedonia. Ohun méjì ló fà á tá a fi ṣe bẹ́ẹ̀.
1. Ẹ̀rọ ìgbàlódé mú kí iṣẹ́ túbọ̀ rọrùn
Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ti mú kó túbọ̀ rọrùn láti máa kàn síra ẹni àti láti máa tẹ ìwé. Èyí mú kó ṣeé ṣe láti dín àwọn tó ń ṣiṣẹ́ láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó tóbi kù. Bí àwọn èèyàn ṣe dín kù yìí mú kí àwọn yàrá kan ṣí sílẹ̀ fún àwọn ará wa tó wá láti àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì kéékèèké.
Ní báyìí tí àwọn ará ti kóra jọpọ̀ sójú kan láti ṣiṣẹ́, ó ti wá ṣeé ṣe láti rí àwọn ará tó nírìírí táá máa bójú tó iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, ní báyìí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Mẹ́síkò ló ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù láwọn orílẹ̀ èdè bíi Costa Rica, El Salvador, Guatemala, Honduras, Nicaragua, àti Panama. Èyí mú ká ti àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà láwọn orílẹ̀-èdè yẹn pa.
Ogójì [40] lára àwọn tó wá láti àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì mẹ́fà yìí ti kó lọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Mẹ́síkò. Àwọn márùndínlọ́gọ́rùn-ún [95] míì ṣì wà lórílẹ̀-èdè wọn, tí wọ́n ń bá iṣẹ́ ìwàásù lọ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.
Àwọn tó ṣẹ́ kù tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì láwọn orílẹ̀-èdè yẹn ń bá iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè lọ láwọn ibi tá a kọ́ fún àwọn atúmọ̀ èdè. Abẹ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì Mẹ́síkò làwọn náà sì wà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn atúmọ̀ èdè bí ogún [20] ló wà ní Panama tí wọ́n ń túmọ̀ àwọn ìwé wa sáwọn èdè tí wọ́n ń sọ lórílẹ̀-èdè náà. Àwọn mẹ́rìndínlógún míì ló ń túmọ̀ àwọn ìwé wa sí àwọn èdè ìbílẹ̀ mẹ́rin ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wà tẹ́lẹ̀ lórílẹ̀-èdè Guatemala. Torí náà, àtúntò tá a ṣe yìí ti mú kí iye àwọn tó ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì dín kù. Dípò ọ̀ọ́dúnrún [300] tó wà láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì mẹ́fà náà tẹ́lẹ̀, wọn ò ju márùndínlọ́gọ́rin [75] lọ báyìí.
2. A ti ní àwọn òṣìṣẹ́ tó fẹ́ lo àkókò púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù
Ní báyìí tá a ti pa àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì kan pọ̀, àwọn ará kan tó ti ń sìn tẹ́lẹ̀ láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì kéékèèké tí wọ́n sì tún tóótun láti ṣe iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ti wá gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù.
Arákùnrin kan nílẹ̀ Áfíríkà tí wọ́n ní kó lọ máa sìn ní pápá sọ pé: “Ó kọ́kọ́ ṣòro díẹ̀ fún bí oṣù mélòó kan lẹ́yìn tí mo kúrò ní Bẹ́tẹ́lì. Àmọ́, bí mo ṣe ń lọ sóde ẹ̀rí lójoojúmọ́ mú kínú mi máa dùn, mo sì rọ́wọ́ Jèhófà lára mi. Ní báyìí, ogún èèyàn ni mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn kan nínú wọn sì ti ń wá sípàdé.”