Ọ̀pọ̀ Èèyàn Wá Wo Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa ní Central America
Lọ́dún 2015, àwọn tó tó ẹgbẹ̀rún márùndínlọ́gọ́sàn-án [175,000] ló wá wo ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Central America, èyí tó wà lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Tá a bá pín iye yẹn sí ọjọ́ márùn-ún láàárín ọ̀sẹ̀, ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé àádọ́rin [670] ló ń wá lójoojúmọ́! Ọ̀pọ̀ nínú àwọn àlejò yìí ló máa ń wá pa pọ̀, wọ́n á lọ gba àwọn bọ́ọ̀sì akérò, wọ́n á sì fi ọ̀pọ̀ ọjọ́ rìnrìn àjò. Ọ̀pọ̀ oṣù ṣáájú làwọn kan ti ń múra sílẹ̀ kí wọ́n tó wá.
“Ètò Àtilọ Bẹ́tẹ́lì”
Ó gba ìsapá káwọn kan tó lè wá wo ẹ̀ka ọ́fíìsì wa yìí, tá à ń pè ní Bẹ́tẹ́lì. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ nínú àwọn ará ìjọ kan ní ìpínlẹ̀ Veracruz lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò ni kò lówó mọ́tò. Bẹ́ẹ̀, ọ̀nà jìn, bọ́ọ̀sì á gbé wọn rin ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé àádọ́ta [550] kìlómítà. Wọ́n wá ṣètò kan, wọ́n pè é ní “Ètò Àtilọ Bẹ́tẹ́lì.” Wọ́n pínra wọn sí àwùjọ-àwùjọ, wọ́n wá ń se oúnjẹ tà. Wọ́n tún ń ta ike fún àwọn tó máa tún un lò. Lẹ́yìn oṣù mẹ́ta, wọ́n ti pawó tó máa tó wọn fi rìnrìn àjò náà.
Ṣé wọ́n tiẹ̀ jàǹfààní kankan nínú gbogbo ohun tí wọ́n ṣe yìí? Wọ́n gbà pé ohun táwọn ṣe tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Lucio nínú ìjọ yẹn kọ̀wé pé: “Wíwá tá a wá sí Bẹ́tẹ́lì yẹn ti jẹ́ kí n fi kún àwọn ohun tí mo fẹ́ ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, mo sì ti ń lo àkókò tó pọ̀ láti ran ìjọ mi lọ́wọ́ báyìí.” Elizabeth, tó jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlógún [18] náà sọ pé: “Nígbà tá a lọ sí Bẹ́tẹ́lì, mo fojú ara mi rí ìfẹ́ tòótọ́ tó wà láàárín àwọn tó ń sin Jèhófà, èmi náà sì mọ̀ ọ́n lára. Àbẹ̀wò yẹn sún mi láti fi kún iṣẹ́ ìsìn mi sí Ọlọ́run, mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi àkókò tó pọ̀ wàásù.”
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún Èèyàn Ló Máa Ń Wá Nígbà Míì
Nígbà míì, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn ló máa ń wá wo ọ́fíìsì yìí lọ́jọ́ kan náà. Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Rí sí Rírìn Yí Ká Ọgbà ṣiṣẹ́ takuntakun kí wọ́n lè bójú tó gbogbo wọn. Lizzy sọ pé, “Ó máa ń wú mi lórí tí mo bá rí iye àwọn tó wá. Ó sì máa ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ mi lágbára tí mo bá rí i bí àwọn èèyàn yìí ṣe mọrírì iṣẹ́ tá à ń ṣe, témi náà sì gbọ́ nípa ìsapá tí wọ́n ṣe kí wọ́n tó lè wá wo ẹ̀ka ọ́fíìsì wa.”
Táwọn tó wá bá ti pọ̀ gan-an bẹ́yẹn, ṣe làwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka míì ní Bẹ́tẹ́lì náà máa ń mú àwọn èèyàn yí ká. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àfikún ni ìyẹn jẹ́ fún iṣẹ́ tiwọn gangan, inú wọn máa ń dùn láti mú àwọn àlejò yìí yí ká ọgbà. Juan sọ pé, “Lẹ́yìn tí mo bá mú àwọn èèyàn rìn yí ká ọgbà wa, mo máa ń rí i bínú wọn ṣe ń dùn, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí n rí i pé ìsapá mi ò já sásán.”
“Àwọn Ọmọdé Ti Fẹ́ràn Ẹ̀ Jù”
Inú àwọn ọmọdé náà máa ń dùn tí wọ́n bá wá sí Bẹ́tẹ́lì. Noriko, tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Kọ̀ǹpútà sọ pé: “Mo máa ń bi àwọn ọmọ tó bá wá wo ọ́fíìsì wa bóyá wọ́n máa fẹ́ ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì tí wọ́n bá dàgbà. Ohun tí gbogbo wọn máa ń sọ ni pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni!’” Ọ̀kan lára ibi táwọn ọmọdé fẹ́ràn jù ni ibi tá a pè ní “Yàrá Kọ́lá.” A gbé àwòrán Kọ́lá àti Tósìn síbẹ̀, ìyẹn àwọn ọmọ tó wà nínú fídíò bèbí tá à ń pè ní Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà. Àwọn ọmọdé máa ń fi àwọn àwòrán yìí ya fọ́tò. Noriko sọ pé, “Àwọn ọmọdé ti fẹ́ràn ẹ̀ jù.”
Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé sọ bí wọ́n ṣe mọrírì iṣẹ́ tí à ń ṣe ní Bẹ́tẹ́lì tó. Bí àpẹẹrẹ, Henry, ọmọ kékeré kan láti orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, fi owó pa mọ́ sínú kóló, ó sì pinnu pé òun máa fi ṣe ọrẹ tóun bá ti wá sí Bẹ́tẹ́lì. Ó fi ìwé kékeré kan sínú owó tó fi ṣe ọrẹ yìí, ohun tó kọ síbẹ̀ ni pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ fi owó yìí ṣe ìwé púpọ̀ sí i.” Ó tún sọ pé, “Ẹ ṣeun tẹ́ ẹ̀ ń ṣiṣẹ́ fún Jèhófà.”
A Pè Ẹ́ Kó O Wá
Kárí ayé làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti máa ń mú àwọn èèyàn rìn yí ká ọgbà wa lọ́fẹ̀ẹ́, láwọn ọ́fíìsì wa àtàwọn ibi tá a ti ń tẹ̀wé. Tó o bá fẹ́ wá wo ẹ̀ka ọ́fíìsì wa kan, tayọ̀tayọ̀ la pè ẹ́ kó o wá. Ó dá wa lójú pé o máa gbádùn ẹ̀ tó o bá wá. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ètò tá a ṣe láti mú àwọn èèyàn yí ká ọgbà wa, lọ sórí ìkànnì wa, kó o tẹ NÍPA WA > Ọ́FÍÌSÌ ÀTI RÍRÌN YÍ KÁ ỌGBÀ.