Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Fọ́tò Iṣẹ́ Ìkọ́lé ní Britain, Apá 5 (September 2017 sí February 2018)

Fọ́tò Iṣẹ́ Ìkọ́lé ní Britain, Apá 5 (September 2017 sí February 2018)

Nínú àwọn fọ́tò yìí, wàá rí ibi tí iṣẹ́ dé lórí ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Britain láàárín September 2017 sí February 2018.

Bí ẹ̀ka ọ́fíìsì Britain tó wà ní Chelmsford ṣe máa rí tá a bá kọ́ ọ tán.

  1. Ilé Iṣẹ́ Apá Àríwá

  2. Ilé Iṣẹ́ Apá Gúúsù

  3. Àwọn Ọ́fíìsì

  4. Ilé Gbígbé A

  5. Ilé Gbígbé B

  6. Ilé Gbígbé C

  7. Ilé Gbígbé D

  8. Ilé Gbígbé E

  9. Ilé Gbígbé F

September 6, 2017​—Ilé Gbígbé C

Àwọn òṣìṣẹ́ ń fi irinṣẹ́ yọ bíríkì pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ. Wọ́n á wá lẹ àwọn bíríkì yìí mọ́ ara irin yí ká, irin yẹn ló ń mú kí ògiri lágbára.

September 20, 2017​—Ilé Gbígbé D

Ọ̀kan lára àwọn tó ń yàwòrán ilé ń fi irinṣẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́ta àti ọ̀pá gbọọrọ kan sàmì sí ibi tí ògiri ìta ilé máa wà. Ilé Gbígbé F lẹ̀ ń wò láàárín nínú fọ́tò yẹn, àwọn káfíńtà ti ń báṣẹ́ lọ nínú ilé níbẹ̀.

September 27, 2017​—Ilé Gbígbé F

Ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ tó ń rẹ́lé ń wọ́n omi sára ògiri tí wọ́n ti rẹ́, ó wá ń fi ọ̀bẹ ìrẹ́lé dán an. Ohun tí Ẹ̀ka Tó Ń Parí Iṣẹ́ máa ń ṣe láti ṣọ́ omi lò ni pé wọ́n máa ń gba omi látinú ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń fa omi kúrò nínú afẹ́fẹ́, omi yẹn ni wọ́n á wá fi po sìmẹ́ǹtì tí wọ́n fi ń lẹ àwo mọ́ ara ilé tàbí ilẹ̀.

October 3, 2017​—Ọgbà ẹ̀ka ọ́fíìsì

Níwájú ìta Ilé Gbígbé E, àwọn agbaṣẹ́ṣe ń da ọ̀dà sójú títì. Títì yìí àtàwọn míì já pọ̀ mọ́ra.

October 10, 2017​—Ilé Gbígbé F

Bíríkílà kan tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànléláàádọ́rin (71) ń mọ ògiri Ilé Gbígbé F. Látìgbà tí iṣẹ́ ìkọ́lé yìí ti bẹ̀rẹ̀, ó lé ní ọgọ́rùn-ún (100) Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ti lé lẹ́ni àádọ́rin ọdún tí wọ́n ti fi ohun tí wọ́n mọ̀ ọ́n ṣe ṣèrànwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà.

November 16, 2017​—Àwọn Ilé Gbígbé

Bí àwọn ilé gbígbé náà ṣe rí rèé tá a bá wò ó látòkè láti apá ìwọ̀ oòrùn. Wọ́n máa gbin koríko sórí òrùlé gbogbo àwọn ilé gbígbé yìí. Tí wọ́n bá ti ṣe àwọn òrùlé náà lọ́nà tí kò fi ní máa gbóná wọnú ilé, tí kò sì ní máa rin, tí wọ́n sì ti ṣe ibi tí omi á máa gbà ṣàn jáde, wọ́n máa gbin àwọn ewéko tó wọ́pọ̀ ládùúgbò yẹn síbẹ̀. Irú àwọn òrùlé tí wọ́n bá ṣe lọ́nà yìí máa ń ṣàǹfààní fáwọn ẹranko, ó máa ń dín ìnáwó kù, ó sì máa ń darí omi òjò síbi tó yẹ. Lọ́wọ́ iwájú nínú fọ́tò yìí, ẹ máa rí ìpìlẹ̀ Ilé Gbígbé A àti díẹ̀ lára ìpìlẹ̀ àwọn ọ́fíìsì.

November 21, 2017​—Ilé Gbígbé F

Àwọn káfíńtà ń gbé férémù onírin sí ẹnu ọ̀nà yàrá kan. Tí wọ́n bá ti ṣe àwọn férémù àtàwọn ilẹ̀kùn sílẹ̀, kò ṣẹ̀ṣẹ̀ nílò pé wọ́n ń kùn ún tàbí pé wọ́n ń fi híǹjì sí i níbi tí wọ́n ti fẹ́ lò ó. Wọ́n ti máa ń ṣe gbogbo ìyẹn mọ́ ọn wá, ìyẹn máa ń jẹ́ kó rọrùn láti dè mọ́ ẹnu ọ̀nà.

November 28, 2017​—Àwọn Ọ́fíìsì

Bílẹ̀ ṣe ń ṣú lọ, àwọn agbaṣẹ́ṣe ń gbé ìpìlẹ̀ tí wọ́n ti ṣe sílẹ̀ sí ibi tí wọ́n fẹ́ kọ́ àwọn ọ́fíìsì sí. Láàárín fọ́tò náà, àwọn agbaṣẹ́ṣe ń gbé irin sínú àwọn ihò tó jìn tó ogún (20) mítà, tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ da kọnkéré sí. Ilé Gbígbé B lẹ̀ ń wò lọ́ọ̀ọ́kán yẹn.

December 5, 2017​—Ilé Gbígbé E

Ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ń de àwọn nǹkan tó ń jẹ́ kí páìpù gbóná mọ́ òrùlé ibi tí wọ́n ń páàkì mọ́tò sí. Wọ́n fi àwọn bọ́ọ̀dù kan sínú òrùlé yẹn táá jẹ́ kíbẹ̀ máa gbóná. Èyí ò ní jẹ́ káwọn yàrá tó wà lókè máa tutù.

December 8, 2017​—Ilé Gbígbé F

Ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ka tó ń parí iṣẹ́ ń fi irinṣẹ́ kan fa gbogbo òkúta àti yẹ̀pẹ̀ tó wà lára àwọn ògiri tí wọ́n ti rẹ́. Ó ń fi èyí múra ògiri náà sílẹ̀ fún iṣẹ́ tó kàn tí wọ́n fẹ́ ṣe lára ẹ̀. Ibi tó rí roboto lára irinṣẹ́ náà ní àwọn ihò wínwìnwín tó máa jẹ́ kí yẹ̀pẹ̀ àti òkúta kéékèèké lè ráyè gbabẹ̀ wọlé.

December 21, 2017​—Ọgbà ẹ̀ka ọ́fíìsì

Àwọn òṣìṣẹ́ méjì ń tún ojú ọ̀nà yìí ṣe. Irinṣẹ́ ọwọ́ wọn ń yọ iná, iná yẹn ni wọ́n fi ń jó àwọn ìdọ̀tí díẹ̀díẹ̀ tó wà níbi tí wọ́n ti da kọnkéré sí, èyí á sì jẹ́ kí wọ́n lè palẹ̀ mọ́ àwọn ohun tó lè dí ojú àwọn ihò tó wà lójú ọ̀nà náà, torí koríko ló máa hù jáde níbẹ̀. Tí wọ́n bá ṣe é bẹ́ẹ̀, á tún lè máa fa díẹ̀ lára omi òjò tó ń ṣàn gbabẹ̀ mu.

December 26, 2017​—Ilé Gbígbé F

Àwọn kunlékunlé ń fín ọ̀dà sára ògiri àti òrùlé nínú ilé ìdáná kí wọ́n lè parí iṣẹ́ níbẹ̀.

December 28, 2017​—Ilé Gbígbé F

Àwọn òṣìṣẹ́ ń tú àwọn irin tí wọ́n dè pọ̀ láti máa fi gùnkè, kí wọ́n lè ráyè ṣe àwọn ọ̀dẹ̀dẹ̀ kéékèèké síwájú àwọn yàrá ilé náà. Àwọn páìpù pupa tẹ́ ẹ̀ ń wò láàárín fọ́tò yìí ni wọ́n fi máa ń gbé ooru gbígbóná wọlé nígbà òtútù láti máa fi jẹ́ kí àwọn ilẹ̀ onísìmẹ́ǹtì gbẹ, tó fi mọ́ àwọn ògiri tí wọ́n ti rẹ́ àtàwọn ibi tí wọ́n ti kùn.

January 16, 2018​—Ilé Gbígbé F

Ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ka tó ń parí iṣẹ́ ń fi irinṣẹ́ rẹ̀ dán ara ògiri kó má bàa sí ihò níbẹ̀, bó ti wù kó kéré mọ. Wọ́n ṣe ògiri yìí lọ́nà tó fi máa ṣeé fọ̀, táá sì lálòpẹ́, tó bá ṣẹlẹ̀ pé ibi táwọn èrò sábà máa ń gbà ló wà. Ẹ tún máa rí àwọn òṣìṣẹ́ míì nínú fọ́tò yìí tí wọ́n ń kun ògiri, tí wọ́n sì ń parí iṣẹ́ lára rẹ̀.

January 27, 2018​—Ilé Gbígbé E

Àwọn òṣìṣẹ́ ń ṣèpàdé kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ojọ́ yẹn. Ẹni tó ń kó wọn ṣiṣẹ́ ń sọ fún wọn pé ọ̀rọ̀ ààbò ṣe pàtàkì gan-an, ó sì ń ṣàlàyé gbogbo àwọn ibi tí ewu lè wà fún wọn. Àwọn òṣìṣẹ́ láti oríṣiríṣi ẹ̀ka iṣẹ́ ń yọ̀ǹda ara wọn láti ṣiṣẹ́ lẹ́yìn iṣẹ́ àyànfúnni wọn ojúmọ́ láti tún Ilé Gbígbé F ṣe àtàwọn ibi tó yí i ká kó tó di pé àwọn tó máa kọ́kọ́ kó síbẹ̀ á dé.

February 1, 2018​—Ilé Gbígbé F

Àwọn agbaṣẹ́ṣe ń fi ẹ̀rọ gbé ọ̀dẹ̀dẹ̀ tí wọ́n ti ṣe sílẹ̀ sí ìta Ilé Gbígbé F. Ìdí tí wọ́n ṣe fi kọ́lọ̀ yẹn kun àwọn ọ̀dẹ̀dẹ̀ náà ni kí wọ́n lè máa fi dá ilé gbígbé náà mọ̀, kó sì lè dà bíi gíláàsì tí àwọ̀ àwọn ewé tó rẹwà láyìíká á máa hàn lára ẹ̀ nígbà ìwọ́wé. Lọ́wọ́ ọ̀tún fọ́tò yìí, wọ́n ń ká ọ̀rá tí wọ́n ta bo Ilé Gbígbé E kúrò kó tó di pé wọ́n máa tú irin tí wọ́n dè pọ̀ láti máa gùnkè.

February 3, 2018​—Àwọn Ilé Gbígbé

Lẹ́yìn táwọn òṣìṣẹ́ parí iṣẹ́ lọ́jọ́ kan, tọkọtaya kan ń kó ẹrù wọn lọ sínú yàrá kan ní Ilé Gbígbé F tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ní ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ yẹn. Bí wọ́n ṣe ń jẹ́ káwọn òṣìṣẹ́ ìkọ́lé ṣì máa gbé nínú àwọn ilé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ tán ń jẹ́ kí wọ́n lè dín owó tí wọ́n ń ná kù, bí owó ilé àti owó ìrìn àjò, èyí sì ń jẹ́ káwọn òṣìṣẹ́ lè túbọ̀ ṣiṣẹ́ dáadáa.

February 12, 2018​—Ilé Gbígbé A

Nírọ̀lẹ́, àwọn agbaṣẹ́ṣe ń rọ kọnkéré síbi tí wọ́n fẹ́ máa gbọ́kọ̀ sí. Ilé Gbígbé B lẹ̀ ń wò lọ́wọ́ ẹ̀yìn nínú fọ́tò yìí.

February 15, 2018​—Ilé Gbígbé E

Tọkọtaya kan tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ káfíńtà ń gé pákó orí tábìlì tó máa ń wà nílé ìdáná. Ẹ̀rọ tó ní ayùn ìrẹ́gi roboto, tó sì máa ń fi páìpù fa èrúnrún igi tí wọ́n bá ń rẹ́gi lọ́wọ́ ni wọ́n ń lò. Gígé tí wọ́n ń gé pákó orí àwọn tábìlì yìí nínú ilé ìdáná tí wọ́n máa gbé e sí dáa gan-an torí kò ní jẹ́ kó máa bù tàbí kán ká sọ pé wọ́n ti gé e tẹ́lẹ̀, tí wọ́n wá ṣẹ̀ṣẹ̀ kó o lọ síbi tí wọ́n ti fẹ́ lò ó.