Fọ́tò Iṣẹ́ Ìkọ́lé ní Britain, Apá 6 (March sí August 2018)
Nínú àwọn fọ́tò yìí, wàá rí ibi tí iṣẹ́ dé lórí ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Britain láàárín oṣù March sí August 2018.
March 8, 2018—Ọgbà ẹ̀ka ọ́fíìsì
Ọ̀kan lára àwọn tó ń yẹ àyíká wò ń ṣàyẹ̀wò omi tó ń ṣàn bọ̀ láti odò tó wà nítòsí ibi àbáwọlé ọgbà. Àyẹ̀wò yìí máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ bóyá àwọn ohun èlò tó ń dènà ìdọ̀tí nínú omi náà ń ṣiṣẹ́ dáadáa.
March 13, 2018—Ilé Gbígbé B
Wọ́n ń kọ́ ẹnì kan bó ṣe lè fi ẹ̀rọ tó ń yẹ ojú ọjọ́ wò sára ilé. Ẹ̀rọ yìí wà nínú ògiri iwájú ìta àwọn ilé gbígbé.
April 5, 2018—Ilé Iṣẹ́ Apá Gúúsù
Ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń ki ilẹ̀ ń ṣiṣẹ́ lójú ọ̀nà kan kí wọ́n tó da ọ̀dà sí i.Apá tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ilé Iṣẹ́ Apá Gúúsù yìí ló parí ọ̀nà tó yí gbogbo ọgbà náà po.
May 1, 2018—Àwọn Ọ́fíìsì
Bó ṣe rí látòkè téèyàn bá wò ó láti àríwá-ìwọ̀ oòrùn. Ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń gbé nǹkan látòkè wà níwájú ibi ìgbàlejò ọ́fíìsì. Kankéré ilẹ̀ Àwọn Ọ́fíìsì wà lápá ọ̀tún ẹ̀rọ náà, ìpìlẹ̀ ilé ìdáná, ilé ìjẹun àti gbọ̀ngàn kan sì wà lápá òsì ẹ̀rọ náà. Wọ́n ti gbé ibi téèyàn ti lè wo àyíká kúrò níbi tó wà lápá òkè yìí kí àwọn tó wá ṣèbẹ̀wò lè rí gbogbo iṣẹ́ ìkọ́lé tó ń lọ lọ́wọ́.
May 9, 2018—Àwọn Ọ́fíìsì
Wọ́n ń to àwọn irin òrùlé sáyè wọn torí àwọn ni òpómúléró ilé ìdáná, ilé ìjẹun àti ti gbọ̀ngàn tó wà nínú ilé tí ọ́fíìsì wà.
May 14, 2018—Àwọn Ọ́fíìsì
Ọ̀kan lára àwọn tó ń yẹ àyíká wò ń kíyè sí ilẹ̀ tí wọ́n ń fá nítòsí igi kan. Àwọn tó ń fá ilẹ̀ fi nǹkan bo ìdí igi náà kí wọ́n lè dáàbò bo gbòǹgbò rẹ̀. Wọ́n dáàbò bo gbòǹgbò àwọn igi tó kù torí wọ́n ṣe ọgbà yí wọn ká, wọn ò sì gba ẹnikẹ́ni láyè láti ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé níbẹ̀.
May 24, 2018—Ilé Gbígbé E
Wọ́n ń gbin ewéko sétí ọ̀nà. Wọ́n fi igi kàn án mọ́lẹ̀ kó lè ta gbòǹgbò.
June 19, 2018—Ilé Gbígbé D
Ẹnì kan ń fi ọ̀dà kọ nọ́ńbà sára igi tí wọ́n fi dárà sára ilé náà ní àjà kẹta. Oṣù tó tẹ̀ lé e làwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé bẹ̀rẹ̀ sí í kó wọnú Ilé Gbígbé D.
June 20, 2018—Àwọn Ọ́fíìsì
Àwọn agbaṣẹ́ṣe ń gbé kankéré àtẹ̀gùn tí wọ́n ti ṣe sílẹ̀ sí àyè rẹ̀.
June 26, 2018—Àwọn Ọ́fíìsì
Àwọn tó ń mọ ògiri ń to ohun tí wọ́n ti mọ sílẹ̀ sí àyè rẹ̀. Ohun tó wà lápá ọ̀tún yìí làwọn oníṣẹ́ ẹ̀rọ fi gbé apá kan lára ẹ̀rọ amúlétutù sókè nígbà tí wọ́n fẹ́ fi sára ilé náà.
July 10, 2018—Àwọn Ọ́fíìsì
Lára àwọn oníṣẹ́ ẹ̀rọ ń fi nǹkan tó máa di àwọn páìpù mú sábẹ́ ibi ìgbàlejò ní ilé táwọn ọ́fíìsì wà.
July 10, 2018—Àwọn Ilé Iṣẹ́
Àwọn òṣìṣẹ́ ń ṣètò ojú ibi tí omi á máa ṣàn gbà láàárín Ilé Iṣẹ́ Apá Àríwá àti Ilé Iṣẹ́ Apá Gúúsù.
July 17, 2018—Àwọn Ọ́fíìsì
Àwọn agbaṣẹ́ṣe ń parí ibi tó kù lára etí òrùlé ilé ìjẹun. Ọ̀nà tó ní òrùlé tó wà nísàlẹ̀ yìí lọ títí dé Ilé Gbígbé A.
July 19, 2018—Ilé Iṣẹ́ Apá Àríwá
Wọ́n ń fi irin ṣe òrùlé. Àwọn yàrá iṣẹ́ àtàwọn ọ́fíìsì ló máa wà nínú ilé yìí.
August 2, 2018—Ọgbà ẹ̀ka ọ́fíìsì
Bó ṣe rí rèé téèyàn bá wò ó látòkè láti apá àríwá-ìwọ̀ oòrùn. Lọ́wọ́ àárín, iṣẹ́ ti parí lórí irin tó máa gbé Ilé Iṣẹ́ Apá Gúúsù dúró, wọ́n sì ti ń báṣẹ́ lọ lórí ògiri tó wà níwájú rẹ̀. Lápá iwájú, iṣẹ́ ń lọ lọ́wọ́ lórí Ilé Iṣẹ́ Apá Àríwá, wọ́n sì ti parí ọ̀dà tí wọ́n yọ́ sórí ìpìlẹ̀ iwájú ilé náà. Àwọn ọ́fíìsì ló wà ní àárín lọ́wọ́ òsì, àwọn ilé gbígbé sì wà lẹ́yìn rẹ̀.
August 3, 2018—Àwọn Ilé Gbígbé
Bó ṣe rí rèé téèyàn bá wò ó látòkè láti ìlà oòrùn nígbà tí oòrùn bá ń yọ. Ilé Gbígbé D, E àti F tí wọ́n ti parí ló wà lápá iwájú. Iṣẹ́ máa parí lórí Ilé Gbígbé C lóṣù October.
August 7, 2018—Àwọn Ọ́fíìsì
Àwọn òṣìṣẹ́ ń fi òkúta ẹfun mọ ògiri yí ká odò kan. Ibí yìí máa jẹ́ kí àbáwọlé àwọn ọ́fíìsì lẹ́wà gan-an, bẹ́ẹ ṣe ń wò ó láti àárín àwọn igi.
August 7, 2018—Àwọn Ọ́fíìsì
Àwọn káfíńtà ń fi ojú ẹ̀rọ amúlétutù àti iná sí òkè ọ́fíìsì kan. Ọ́fíìsì yìí ni wọ́n ti ń ṣètò bí àwùjọ àwọn òṣìṣẹ́ kọ̀ọ̀kan ṣe wá ń ṣe iṣẹ́ wọn ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé láwọn ilé tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́.
August 21, 2018—Àwọn Ọ́fíìsì
Wọ́n ń gbé àwọn ògiri oníkankéré tí wọ́n ti mọ sílẹ̀ sí àyè wọn ní Àwọn Ọ́fíìsì. Ògiri tí wọ́n lò yìí mú kí iṣẹ́ ilé náà yá, kí wọ́n lè yanjú gbogbo ògiri ìta Àwọn Ọ́fíìsì títí ìparí oṣù August. Àwọn wíńdò ńláńlá tó wà ní àwọn ọ́fíìsì náà á jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wọlé dáadáa láti ìta. Wọ́n jẹ́ kí àwọn wíńdò náà wọnú dáadáa kí ìtànṣán oòrùn ìgbà òtútù má bàa pọ̀ nínú ilé, kí ooru má sì pọ̀ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn.
August 24, 2018—Àwọn Ọ́fíìsì
Àwọn òṣìṣẹ́ ń ṣètò ohun tí wọ́n máa fi ró òrùlé ilé ìjẹun àti gbọ̀ngàn tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Àwọn ògiri ibẹ̀ ò ní jẹ́ kí ìró ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní ilé ìjẹun wọnú gbọ̀ngàn náà nígbà tí wọ́n bá ń lo ibi méjèèjì lọ́wọ́.