Fọ́tò Iṣẹ́ Ìkọ́lé ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Apá 4 (March sí August 2017)
Nínú àwọn fọ́tò yìí, wàá rí ibi tí iṣẹ́ ìkọ́lé dé láàárín oṣù March sí August 2017 níbi ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ sí Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.
March 28, 2017—Ibi tí wọ́n ń kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí
Agbaṣẹ́ṣe kan ń fi irinṣẹ́ tí wọ́n fi ń gbé ẹrù já ilé kótópó kan tí wọ́n fi gíláàsì ṣe iwájú rẹ̀. Ilé yìí wà lára àwọn ilé tí wọ́n gbé sọ́wọ́ òkè, tí wọ́n sì ṣe ọgbà yí i ká níbì kan lórí ilẹ̀ tí wọ́n ń kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì náà sí. Àwọn tó bá wá wo àyíká ọ́fíìsì náà á lè máa rí ọgbà náà kedere látinú àwọn ilé yìí. May 2017 ni wọ́n kọ́kọ́ ṣí ibi ìgbàlejò àtàwọn ilé yìí, nígbà tó sì fi máa di August, àwọn àlejò tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún (17,000) ló ti forúkọ sílẹ̀ pé àwọn fẹ́ wá wo iṣẹ́ ìkọ́lé tó ń lọ.
March 29, 2017—Ilé Gbígbé F
Àwọn agbaṣẹ́ṣe ń fi irinṣẹ́ tí wọ́n fi ń gbé ẹrù yìí gbé tábìlì oníkọnkéré tí wọ́n ti dè nílẹ̀ sínú Ilé Gbígbé F. Ilé Gbígbé F ni ilé gbígbé tí wọ́n kọ́kọ́ kọ́. Torí pé àyè wà dáadáa ní àyíká àwọn ilé yìí, wọ́n lè gbé nǹkan láti ibì kan lọ síbòmíì láìsí pé wọ́n ń kọ́kọ́ tú u palẹ̀.
April 7, 2017—Àwọn ilé gbígbé
Ilé Gbígbé márùn-ún ni wọ́n ń kọ́ pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà. Lọ́wọ́ iwájú, àwọn agbaṣẹ́ṣe ń de irin pọ̀ kí wọ́n tó rọ kọnkéré sínú ìpìlẹ̀ Ilé Gbígbé B. Lọ́wọ́ ẹ̀yìn lápá ọ̀tún, àwọn agbaṣẹ́ṣe ń da kọnkéré tí wọ́n á fi ṣe àjà ìsàlẹ̀ pátápátá ní Ilé Gbígbé D. Lọ́wọ́ ẹ̀yìn lápá òsì, wọ́n ń fi irinṣẹ́ tí wọ́n fi ń gbé ẹrù yẹn gbé irin kan tí wọ́n máa ń rọ kọnkéré sínú ẹ̀ síbi tí ẹ̀rọ agbéniròkè àti àtẹ̀gùn máa wà ní Ilé Gbígbé E.
April 19, 2017—Ibi tí wọ́n ń kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí
Òṣìṣẹ́ kan ń fi irinṣẹ́ yọ èyí tí ò dáa kúrò níbi tí wọ́n ti jó páìpù méjì pọ̀. Omi ti wọ́n á fi máa paná ni wọ́n gbé gba inú àwọn páìpù yìí. Iná ni wọ́n fi máa ń jó àwọn páìpù náà pọ̀, ṣe ni iná yẹn máa ń yọ́ ọ, á sì mú kí wọ́n lẹ̀ mọ́ra. Wọ́n á wá fi irinṣẹ́ yọ èyí tó bá ṣe síbi eteetí ẹ̀ kúrò, wọ́n á sì yẹ ibi tí páìpù méjèèjì ti lẹ̀ pọ̀ wò láti mọ bó ṣe lágbára tó àtí bó ṣe lẹ̀ pọ̀ tó. Gbogbo irú páìpù yìí tí wọ́n rì fẹ́rẹ̀ẹ́ gùn tó kìlómítà mẹ́rin.
April 25, 2017—Àwọn ilé gbígbé
Òṣìṣẹ́ kan ń fọ ibi tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe kí omi máa gbà. Wọ́n máa ń gbé títì gba orí àwọn ibi tí wọ́n ṣe fún omi yìí, ó sì máa ń jẹ́ kí omi òjò ráyè ṣàn lọ sínú àwọn omi adágún tó wà nínú ọgbà náà, kí omíyalé má bàa ṣẹlẹ̀.
April 28, 2017—Ilé Gbígbé F
Tọkọtaya kan tí wọ́n jẹ́ ayàwòrán ilé ń sàmì síbi tí àwọn ògiri ọ̀dẹ̀dẹ̀ máa wà ní àjà ìsàlẹ̀ pátápátá.
May 5, 2017—Àwọn ilé gbígbé
Fọ́tò ilé gbígbé márùn-ún tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ rèé látòkè, lọ́wọ́ ìlà oòrùn. Oṣù September ni wọ́n parí iṣẹ́ lórí àwọn férémù kọnkéré, iṣẹ́ ń lọ lọ́wọ́ lórí àwọn ògiri inú ilé ní Ilé Gbígbé F nígbà yẹn (lọ́wọ́ ẹ̀yìn lápá ọ̀tún), wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ́ ilé yẹn, tí wọ́n sì ń kùn ún. Lẹ́sẹ̀ kan náà, àwọn òṣìṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ sí í ri àwọn ògiri ìta àtàwọn wíńdò ní Ilé Gbígbé E (lọ́wọ́ ẹ̀yìn lápá òsì). Ní Ilé Gbígbé B, C, àti D (lọ́wọ́ iwájú), wọ́n ń múra àtibẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yíyàwòrán ilé, iṣẹ́ iná, iṣẹ́ maṣíìnì àti iṣẹ́ àwọn tó ń to irin táwọn òṣìṣẹ́ máa gùn tí ọwọ́ á fi tó òkè.
May 18, 2017—Ibi tí wọ́n ń kó irinṣẹ́ sí
Robert Luccioni, tó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ Ìgbìmọ̀ Ìṣèwéjáde ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí àti alábòójútó Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ Kárí Ayé, ń fi àsọyé tó dá lórí Bíbélì gbé àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé ró. Ẹ̀ka tá a mẹ́nu bà yìí ló ń rí sí yíyàwòrán àti kíkọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun, àwọn ló ń rí sí i pé iṣẹ́ ń lọ bó ṣe yẹ, tí wọ́n sì ń rí i pé wọn ò lo owó nílòkulò.
May 25, 2017—Ibi tí wọ́n ń kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí
Àwọn òṣìṣẹ́ ń ṣètò kọnkéré tí wọ́n máa lò fún ilé tí wọ́n á máa kẹ́rù sí, bíi gáàsì tí wọ́n ń lò nínú ilé, ohun èlò iná àtàwọn nǹkan míì. Lápá ọ̀tún, àwọn òṣìṣẹ́ ń lo ẹ̀rọ kan tí wọ́n ń fọwọ́ yí láti rọ kọnkéré sínú ìpìlẹ̀ ògiri tí wọ́n fẹ́ ṣe síbẹ̀. Ògiri yìí ò ní jẹ́ kí ariwo ẹ̀rọ tó bá wà nínú ilé náà fi bẹ́ẹ̀ jáde síta.
June 7, 2017—Ilé Gbígbé E
Àwọn ayàwòrán ilé ń yẹ àwọn àwòrán wò kí wọ́n tó sàmì sí ibi tí wọ́n máa de férémù onírin mọ́ nílẹ̀.
June 13, 2017—Ilé Gbígbé F
Òṣìṣẹ́ kan ń de àwọn férémù onírin tí wọ́n máa lò fún àwọn ògiri ìta.
June 22, 2017—Ilé Gbígbé E
Wọ́n ń to irin tó ṣeé gùn yí ká Ilé Gbígbé E, èyí á jẹ́ kó rọrùn fáwọn òṣìṣẹ́ kọ́wọ́ wọn lè débi àwọn ògiri ìta.
July 11, 2017—Ilé Gbígbé F
Kunlékunlé kan ń fi oríṣi ọ̀dà kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ kun àwọn wíńdò tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe. Tí ọ̀dà yẹn bá ti gbẹ, ó máa di kiní kan tó rí bí ike lójú àwọn wíńdò náà, èyí ò ní jẹ́ káwọn gíláàsì ojú wíńdò náà fọ́ bí iṣẹ́ ìkọ́lé ṣe ń lọ lọ́wọ́. Tí wọn ò bá nílò ẹ̀ mọ́, ṣe ni wọ́n á kàn ṣí i kúrò lójú ẹ̀.
July 13, 2017—Ilé Gbígbé F
Wọ́n ń yẹ ẹ̀rọ abẹ́lẹ̀ amú-nǹkan-gbóná tó wà nínú yàrá kan wò bóyá ó ń ṣiṣẹ́ dáadáa. Tí wọ́n bá ti ṣàtúnṣe tó yẹ sí i, wọ́n á ṣẹ̀ṣẹ̀ wá da kọnkéré sílẹ̀ láti bo àwọn páìpù yẹn mọ́lẹ̀.
July 19, 2017—Ibi tí wọ́n ń kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí
Ẹnì kan tó ń tọ́jú àyíká ń gé lára koríko tó lalẹ̀ hù yìí níbi ojú ọ̀nà àlọyípo tó wà níwájú ibi àbáwọlé sínú ọgbà ẹ̀ka ọ́fíìsì náà. Koríko yìí kì í jẹ́ kí igbó hù, èyí á sì dín àkókò tí wọ́n á máa lò àti iṣẹ́ tí wọ́n á máa ṣe láti tọ́jú ibi tó bọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ títì ńlá yẹn.
August 1, 2017—Àwọn Ọ́fíìsì
Wọnlẹ̀wọnlẹ̀ kan ń fi ẹ̀rọ tó ń lo íńtánẹ́ẹ̀tì wọnlẹ̀, ó sì sàmì síbì kan tó máa jẹ́ ibi àbáwọlé síbi ilé táwọn ọ́fíìsì wà. Ó fi irin kan sàmì síbẹ̀, ó wá kun irin náà kó lè hàn kedere. Ilé ìdáná kan máa wà lápá ibí yìí, ibì kan sì máa wà níbẹ̀ tí wọ́n ṣètò láti máa lò bíi yàrá ìjẹun àti gbọ̀ngàn ńlá. Àwọn ilé gbígbé lẹ̀ ń wò lọ́wọ́ ẹ̀yìn yẹn.
August 8, 2017—Àwọn Ilé Gbígbé
Tọkọtaya kan ń ṣe ibì kan tí wọ́n máa rọ kọnkéré sí, ó wà lára ohun tí wọ́n á máa lò láti bójú tó ọ̀rọ̀ omi. Ilé Gbígbé E àti F ló wà lọ́wọ́ ẹ̀yìn yẹn, tí wọ́n da àtabojú oníke bò látòkè délẹ̀, káwọn òṣìṣẹ́ má bàa mọ òtútù lára, kí wọ́n sì máa báṣẹ́ lọ láwọn oṣù tí òtútù bá fi mú.
August 9, 2017—Ibi tí wọ́n ń kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí
Wọ́n ń kọ́ ẹnì kan bí á ṣe máa lo irinṣẹ́ yìí. Wọ́n máa ń fi irinṣẹ́ yìí gbé àwọn òkúta tí ìkọ̀ọ̀kan wọn wúwo tó àpò sìmẹ́ǹtì kan ààbọ̀ lọ síbi tó máa wà. Táwọn òkúta náà bá ti wà níbi tó yẹ kí wọ́n wà, wọ́n á rọ kọnkéré sí ẹ̀gbẹ́ wọn méjèèjì kó lè gbà wọn dúró.
August 16, 2017—Ibi tí wọ́n ń kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí
Bí wọ́n ṣe ń wọ́ páìpù omi yìí síbi tó máa wà gangan, òṣìṣẹ́ kan ń fọwọ́ dì í mú kó lè wà bó ṣe yẹ kó wà. Àwọn páìpù tó fẹ́rẹ̀ẹ́ gùn tó kìlómítà márùn-ún ni wọ́n máa nílò ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun yìí.
August 22, 2017—Ilé Gbígbé E
Ọ̀kan lára àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ìta ilé ń fi ẹ̀rọ oníná kan gé bíríkì. Wọ́n máa ń fi àwọn bíríkì tí wọ́n bá gé kù ní ààbọ̀ dárà sí igun àwọn ilé gbígbé náà. Àpapọ̀ bíríkì tí wọ́n máa lò láwọn ilé gbígbé náà máa lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300,000).