Àwọn Fọ́tò Iṣẹ́ Ìkọ́lé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa ní Philippines, Apá 1 (February 2014 sí May 2015)
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ àwọn ilé tuntun sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà nílùú Quezon ní Philippines, a sì ń tún àwọn tó ti wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ ṣe. Nígbà tó ti jẹ́ pé ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Japan ló ń tẹ àwọn ìwé ìròyìn tá a ń lò ní Philippines báyìí, a ti ṣàtúnṣe sí ilé ìtẹ̀wé tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Philippines, a sì ti sọ ọ́ di tuntun. Àwọn ẹ̀ka tó ń lò ó báyìí ni ẹ̀ka tó ń bójú tó kọ̀ǹpútà, ẹ̀ka tó ń yàwòrán ilé tí wọ́n sì ń kọ́ ọ, ẹ̀ka tó ń ṣàtúnṣe ilé, ẹ̀ka tó ń kó ìtẹ̀jáde ránṣẹ́ àti ẹ̀ka àwọn atúmọ̀ èdè. Ara àwọn àtúnṣe tá a ṣe sí ilé tá à ń lò fún ìtẹ̀wé tẹ́lẹ̀ àtàwọn ilé míì láti February 2014 sí May 2015 ló wà nínú àwọn fọ́tò tó wà nísàlẹ̀ yìí. A ṣètò pé a máa parí ìṣẹ́ yìí ní October 2016.
February 28, 2014—Ilé 7
Àwọn tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn fúngbà díẹ̀ ń fi nǹkan wé àwọn ohun tó ń múlé gbóná, kí omi má bàá wọnú ẹ̀. Wọ́n wọ aṣọ tó máa bo gbogbo ara wọn kó má bàá yún wọn lára.
April 2, 2014—Ilé 7
Àwọn òṣìṣẹ́ ti parí òrùlé yàrá ìgbohùnsílẹ̀ fún Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Filipino. Àwọn ihò onígun mẹ́rin yìí ni wọ́n máa gbé àwọn ẹ̀rọ tó máa mú kí gbogbo yàrá ìgbohùnsílẹ̀ náà tutù sí.
October 21, 2014—Ibi tá a ti ń ṣiṣẹ́ ní ìlú Quezon
Wọ́n ń wa ilẹ̀ tí wọ́n á gbé àwọn páìpù táá máa gbé omi tútù káàkiri sí. Omi yìí ní gbogbo ilé tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì náà á máa lò.
December 19, 2014—Afárá tí èèyàn lè gbà dé Ilé 1, 5, àti 7
Èèyàn máa lè gba afárá tuntun tá a ṣẹ̀ kọ́ tán yìí dé àwọn ilé kan bíi Ilé 1 tí wọ́n kọ́ ibi tá a ti ń jẹun sí. Àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní Ilé 7 ni afárá yìí á wúlò fún jù.
January 15, 2015—Ilé 5
Ọkọ̀ ńlá tí wọ́n fi ń gbé ẹrù gòkè ń kó àwọn páànù tí wọ́n á fi kanlé gòkè. Àwọn agbaṣẹ́ṣe ló ń wa oríṣiríṣi àwọn ọkọ̀ tó ń gbé nǹkan gòkè yìí.
January 15, 2015—Ilé 5A (Àfikún ilé)
Àwọn nǹkan tó lè gbàyè tàbí ṣèdíwọ́ nínú Ilé 5 la kọ́ sínú ibi tá a pè ní àfikún ilé yìí. Ilé yìí fẹ̀ dáadáa, àjà méjì ló ní, ó ní ilé ìtura méjì, àtẹ̀gùn àti ẹ̀rọ agbéniròkè. Bí àfikún ilé yìí ṣe ní ilé ìtura àti àwọn àtẹ̀gùn nínú máa jẹ́ kí ayé túbọ̀ wà ní Ilé 5 tó wà lódìkejì rẹ̀. Bí wọ́n ṣe gbé ẹ̀rọ agbéniròkè sínú àfikún ilé yìí kò ní jẹ́ kí ariwo ẹ̀rọ náà máa yọ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú yàrá ìgbohùnsílẹ̀ tó wà ní Ilé 5 lẹ́nu.
January 15, 2015—Ilé 5A (Àfikún ilé)
Àwọn òṣìṣẹ́ ń to irin sáàárín àjà ilé. Wọ́n ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìbòji torí òòrùn tó ń mú gan-an. Òòrùn máa ń mu gan-an lóṣù January àti April.
March 5, 2015—Ilé 5
Àwọn òṣìṣẹ́ ń to pákó sí òrùlé kó lè lágbára. Ní Ilé 5, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [800] akọ igi ni wọ́n fi ṣe òrùlé náà.
March 17, 2015—Ilé 5
Àwọn òṣìṣẹ́ ń po kọnkéré tí wọ́n fẹ́ fi ṣiṣẹ́ kékeré kan. Lára àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbi ìkọ́lé yìí ni àwọn tó lé ní ọgọ́rùn-ún [100] òṣìṣẹ́ láti Ọsirélíà, Kánádà, Faransé, Japan, New Zealand, South Korea, Sípéènì, Amẹ́ríkà àtàwọn orílẹ̀ èdè míì.
March 25, 2015—Ilé 5
Wọ́n ń ṣe òrùlé onírin sí Ilé 5, níbi tí ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè wà tẹ́lẹ̀. Ẹ̀ka tó ń ṣe fídíò tó sì ń gbohun sílẹ̀ àti Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn láá máa lo ibí yìí tí wọ́n bá parí ẹ̀.
May 13, 2015—Ilé 5
Oníṣẹ́ irin kan ń fi ẹ̀rọ gé irin tí wọ́n á fi gbé ògiri àwọn ọ́fíìsì dúró.