Àkànṣe Ìwàásù Yọrí sí Rere ní Lapland
Lórílẹ̀-èdè Finland, Nọ́wè àti Sweden, àwọn kan ń gbé níbẹ̀ tí wọ́n ń pè ní àwọn Saami. Àwọn èèyàn yìí ní àṣà ìbílẹ̀ tiwọn, wọ́n sì láwọn èdè tí wọ́n ń sọ níbẹ̀. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ohun méjì tó jẹ́ kí wọ́n lè wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn Saami.
Àkọ́kọ́, nígbà ìwọ́wé ọdún 2015, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì àtàwọn fídíò lédè Saami. * Ìkejì, nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe àkànṣe ìwàásù méjì lọ́dún 2016 àti 2017, wọ́n rìnrìn àjò lọ sí Lapland, agbègbè tó jìnnà kan táwọn ìgalà pọ̀ sí, kí wọ́n lè lọ fi àwọn ìwé àtàwọn fídíò náà wàásù fún àwọn Saami.
“Iṣẹ́ tó ń ran àwọn aráàlú lọ́wọ́ gan-an”
Nígbà àkànṣe ìwàásù tó wáyé ní May 2017, ó ju igba (200) àwọn Ẹlẹ́rìí tó wá láti orílẹ̀-èdè Finland, Nọ́wè àti Sweden, tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn láti lọ sí ọ̀pọ̀ àwọn abúlé kéékèèké tó wà káàkiri ní Lapland, bí agbègbè náà ṣe fẹ̀ tó. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan kọ́ bí wọ́n ṣe ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan lédè Saami, èyí sì wú àwọn èèyàn náà lórí. Denis, tó yọ̀ǹda ara ẹ̀ ní Karigasniemi sọ pé, “Àwọn ará ibẹ̀ mọyì bá a ṣe sapá láti sọ èdè wọn, wọ́n sì rí i pé ọ̀rọ̀ àwọn jẹ wá lọ́kàn lóòótọ́.”
Torí pé àwọn Saami fẹ́ràn ìṣẹ̀dá àtàwọn ẹran igbó, ìyẹn jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ mọyì ìlérí tó wà nínú Bíbélì pé ayé máa di párádísè. (Sáàmù 37:11) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí obìnrin Saami kan bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! ó kọ́ nípa ohun tí Ọlọ́run máa ṣe fún aráyé, ó sọ ọ́ jáde pé ó ya òun lẹ́nu pé pásítọ̀ òun ò bá òun sọ ọ́ rí pé ayé máa di Párádísè.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló fi hàn pé àwọn mọrírì bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe wá sí agbègbè náà. Ọkùnrin kan tó ní ṣọ́ọ̀bù tó ti ń tajà kíyè sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì kan, ó sì gbóríyìn fún wọn. Ó sọ fún wọn pé iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe yìí “ṣe pàtàkì, iṣẹ́ tó ń ran àwọn aráàlú lọ́wọ́ gan-an ni.” Ló bá ní kí wọ́n wá sí ṣọ́ọ̀bù òun, kí wọ́n mú oúnjẹ èyíkéyìí tí wọ́n bá fẹ́, kí wọ́n má sì ṣèyọnu nípa owó.
Nígbà àkànṣe ìwàásù yẹn, nǹkan bí ọgọ́sàn-án (180) fídíò làwọn Saami wò, wọ́n sì gba ìwé tó lé ní ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500). Wọ́n sábà máa ń béèrè pé káwọn Ẹlẹ́rìí fún àwọn ní gbogbo ìwé tó bá ti wà lédè wọn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn Saami mẹ́rìnlá (14) làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
“Àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ló ṣiṣẹ́ yìí”
Àwọn Saami kan tí wọ́n ka ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọyì iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè tó jinná tí wọ́n ṣe síbẹ̀. Nilla Tapiola, tó jẹ́ olùkọ́ iléèwé, tó sì wà nínú Ìgbìmọ̀ Aláṣẹ ti Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Saami sọ pé, “Bí ẹ ṣe túmọ̀ àwọn ìwé yín dáa gan-an.” Ó ṣàlàyé pé àwọn ìwé náà “rọrùn láti kà, ó sì bá àkọtọ́ mu.” Ọkùnrin Saami kan tó ń gbé níbi tó jìn jù ní àríwá orílẹ̀-èdè Finland sọ pé: “Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ló ṣiṣẹ́ yìí.”
Ní Karigasniemi, níbi tí orílẹ̀-èdè Finland àti Nọ́wè ti pààlà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá obìnrin Saami kan tó jẹ́ olùkọ́ jíròrò ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́ nínú ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! Bí wọ́n ṣe túmọ̀ ìwé náà wú olùkọ́ náà lórí, ló bá bi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kí wọ́n jẹ́ kóun lò ó níléèwé láti máa fi kọ́ àwọn ọmọ ní èdè Saami.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti túmọ̀ àwọn fídíò lóríṣiríṣi àtàwọn ìwé àṣàrò kúkúrú, títí kan ìwé pẹlẹbẹ kan sí èdè Saami. Àti February 29, 2016 ni èdè Saami ti wà lórí ìkànnì jw.org. Ó ju ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ìgbà tí làwọn tó ń sọ èdè yìí máa ń lọ sórí ìkànnì náà lóṣooṣù, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti àádọ́ta (350) ìwé, àtẹ́tísí àti fídíò ni wọ́n sì ń wà jáde lórí rẹ̀.
Àwọn Saami àtàwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti lọ wàásù fún wọn gbà pé àkànṣe ìwàásù yẹn ṣiṣẹ́ gan-an. Henrick àti Hilja-Maria, tí wọ́n rìnrìn àjò lọ sí Utsjoki kíyè sí i pé àwọn aráàlú “rí i pé oríṣiríṣi ọ̀nà ni Bíbélì ń gbà ṣe àwọn Saami láǹfààní.” Lauri àti Inga, táwọn náà wà ní Utsjoki fi kún un pé: “Àkànṣe ìwàásù yìí rán wa létí pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú. Inú wa dùn pé a lè jẹ́ káwọn tó ń gbé ní àdádó yìí rí bí Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn tó.”
^ ìpínrọ̀ 3 Oríṣiríṣi èdè làwọn Saami (tí wọ́n tún ń pè ní Sami) máa ń sọ. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica sọ pé, “Èdè tí wọ́n ń sọ jù ni North Sami, torí ìdá méjì nínú mẹ́ta gbogbo àwọn Sami ló ń sọ ọ́.” Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń túmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde wọn sí èdè North Saami. Kí ọ̀rọ̀ má bàa lọ́jú pọ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí, “Saami” ni àá máa fi tọ́ka sí èdè tí ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ń sọ.