Àwọn Àtẹ Ìwé Tó Ṣeé Tì Kiri “Lọ Lo Àkókò Ìsinmi” ní Jámánì
Láwọn ìlú tó tóbi káàkiri ayé, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn tó ń fẹsẹ̀ rìn kọjá máa ń rí àwọn àtẹ tó ṣeé tì kiri táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pàtẹ ìwé wọn sí. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Jámánì, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pàtẹ àwọn ìwé wọn sílùú Berlin, Cologne, Hamburg, Munich àtàwọn ìlú ńlá míì.
Àmọ́ ṣé àwọn àtẹ ìwé tó fani mọ́ra yìí máa ríṣẹ́ ṣe láwọn ìlú kéékèèké táwọn ọmọ ilẹ̀ Jámánì ti máa ń lọ lo àkókò ìsinmi wọn? Ṣé ó máa wúlò láwọn ìlú tó wà lápá àríwá táwọn èèyàn ti ń gbafẹ́, láwọn àdúgbò tó wà létí òkun àti láwọn erékùṣù tó wà ní Òkun Baltic àti Òkun Àríwá? Lọ́dún 2016, ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílẹ̀ Central Europe ṣètò nǹkan kan lákànṣe tó máa jẹ́ ká rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yẹn. Láti May sí October, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [800] tó máa ń pàtẹ ìwé sáwọn ìlú ńlá, títí kan àwọn kan tó wá láti ìlú Vienna lórílẹ̀-èdè Austria lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún, ló yọ̀ǹda ara wọn láti pàtẹ ìwé sáwọn ibi tó tó ọgọ́ta [60] ní àríwá orílẹ̀-èdè Jámánì.
“Àwọn Èèyàn . . . Ń Fojú Aráàlú Wò Wá”
Tọwọ́tẹsẹ̀ làwọn èèyàn gba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọ̀kan nínú àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn sọ pé: “Àwọn èèyàn ń wá síbi àtẹ náà. Ara wọn yá mọ́ọ̀yàn, wọ́n fẹ́ mọ ohun tá a bá wá, wọ́n sì fẹ́ bá wa sọ̀rọ̀.” Heidi, tó rìnrìn àjò lọ sílùú Plön sọ pé: “Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, àwọn èèyàn ti ń fojú aráàlú wò wá. Ṣe ni àwọn kan tó ti dá wa mọ̀ máa ń juwọ́ sí wa tí wọ́n bá ti rí wa.” Ọkùnrin adití kan fọwọ́ bá wọn sọ̀rọ̀, ó ní: “Kó síbi tẹ́ ò sí!” Lọ́jọ́ yẹn, òun àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ń bọ̀ látibi àpérò kan táwọn adití ṣe ní gúúsù ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Jámánì, ó sì ti rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbẹ̀ náà.
Àwọn kan lára àwọn aráàlú náà tiẹ̀ ran àwọn Ẹlẹ́rìí lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ní erékùṣù Wangerooge, ọlọ́pàá kan lọ bá àwọn Ẹlẹ́rìí, ó sì fìfẹ́ dábàá bí wọ́n ṣe lè túbọ̀ rí àwọn èèyàn fún wọn. Bákan náà, nílùú Waren an der Müritz, ọ̀gá ọkọ̀ ojú omi kan táwọn èèyàn máa ń tibẹ̀ wo àyíká ń tọ́ka àwọn ibi tó rẹwà, tó sì fani mọ́ra fáwọn èrò tó gbé. Nígbà tí wọ́n dé tòsí ibùdókọ̀, ó nàka sí àtẹ ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó ní: “Tẹ́ ẹ bá lọ síbẹ̀ yẹn, wọ́n á kọ́ yín lẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run.” Àwọn kan tó wá lo àkókò ìsinmi sún mọ́ àtẹ ìwé náà, wọ́n sì fara balẹ̀ ka àwọn ìwé fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ tó wà lára àwọn àtẹ náà.
Ó wu àwọn tó wá gbafẹ́ àtàwọn aráàlú kí wọ́n mọ ohun tó wà nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ mẹ́ta yìí:
Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? Ẹnì kan tó wá gbafẹ́ sọ pé: “Ó ti pẹ́ tí mo ti ń bi ara mi ní ìbéèrè yìí. Mo dúpẹ́ pé màá ráyè ka nǹkan kan nípa ẹ̀ lásìkò tí mo wá lo àkókò ìsinmi yìí.”
Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! Ọkùnrin àgbàlagbà kan sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ti yọ lọ́kàn òun. Wọ́n wá jẹ́ kó yé e pé èèyàn ò lè bá wa yanjú ìṣòro wa, Ọlọ́run nìkan ló lè ṣe é. Tayọ̀tayọ̀ ni ọkùnrin náà gba ìwé pẹlẹbẹ náà, ó sì ṣèlérí pé òun máa kà á.
Ẹ̀kọ́ Bíbélì. Bàbá kan gbà kí ọmọbìnrin rẹ̀ kékeré mú ìwé náà. Àwọn ọmọdé ni wọ́n dìídì ṣe ìwé náà fún. Ó tún gba ẹ̀dà Ìwé Ìtàn Bíbélì, ó sì sọ pé: “Ìwé yìí máa wúlò gan-an fún ìdílé mi.”
Ó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [3,600] ìwé táwọn tó ń kọjá lọ gbà. Àwọn kan tiẹ̀ sọ pé káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sílé àwọn, káwọn lè jọ sọ̀rọ̀ sí i.
Àwọn Ẹlẹ́rìí tó kọ́wọ́ ti ìṣètò yìí gbádùn ẹ̀ gan-an. Jörg àti Marina ìyàwó rẹ̀ rìnrìn àjò lọ síbì kan tó wà nítòsí Òkun Baltic. Wọ́n sọ pé, “A gbádùn ẹ̀ gan-an ni. A láǹfààní láti rí oríṣiríṣi nǹkan tí Ọlọ́run dá, lẹ́sẹ̀ kan náà, a ráyè sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn.” Lukas tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] sọ pé: “Ó ti lọ wà jù! Mo gbádùn ara mi, àmọ́ mo tún ṣèrànwọ́ fáwọn míì lọ́nà tó máa tún ayé wọn ṣe.”