Ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run Dé Àwọn Àgbègbè Àdádó
Ní ọdún 2014, Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ ètò tuntun kan tí wọ́n ṣe láti mú kí ìwàásù dé àwọn àgbègbè àdádó ní ilẹ̀ Yúróòpù àti Amẹ́ríkà ti Àríwá. (Ìṣe 1:8) Nígbà tá a kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ètò yìí, àwọn àgbègbè kan ní Alaska lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Lapland lórílẹ̀-èdè Finland, Nunavut àti àwọn àgbègbè kan ní Gúúsù ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Kánádà la gbájú mọ́.
Ọ̀pọ̀ ọdún ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti lọ ń wàásù ní àwọn àgbègbè àdádó yìí. Àmọ́, wọn kì í pẹ́ púpọ̀ níbẹ̀, ohun tí wọ́n lọ ń ṣe níbẹ̀ kò ju kí wọ́n pín àwọn ìwé tí wọ́n fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ.
Àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àwọn àgbègbè àdádó yẹn sọ pé kí àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún (aṣáájú-ọ̀nà) lọ wàásù fún ó kéré tán oṣù mẹ́ta, ní àwọn ibi kan lára àwọn àgbègbè àdádó náà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì ibẹ̀ yàn. Tí ọ̀pọ̀ nínú àwọn tó wà ní àgbègbè náà bá nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn òjíṣẹ́ yìí lè dúró pẹ́ díẹ̀ níbẹ̀, kódà wọ́n máa ń ṣe ìpàdé níbẹ̀.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìṣòro ni àwọn tó lọ sí àwọn àgbègbè yìí kojú. Ọ̀kan lára àwọn aṣáájú-ọ̀nà méjì tí wọ́n ní kó lọ sìn ní ìlú Barrow ní Alaska ń gbé ní gúúsù California, ẹnì kejì sì ń gbé ní Georgia, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Nígbà tí òtútù kọ́kọ́ máa mú nílùú Barrow, wọ́n fara da otútù tó lágbára gan-an! Síbẹ̀ náà, láàárín oṣù mélòó kan tí wọ́n débẹ̀, wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ wáàsù ní èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ilé tó wà ní ìlú náà, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́rin. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ John wà lára àwọn tí wọ́n kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọ̀dọ́kùnrin yìí àti ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? ó sì máa ń sọ ohun tó kọ́ fún àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́. Ó tún máa ń ka ẹ̀kọ́ ojúmọ́ látinú ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ tó wà lórí ètò ìṣiṣẹ́ JW Library tó gbé sórí fóònù rẹ̀.
Kò sí ọ̀nà tí wọ́n lè gbà dé ìlú Rankin Inlet tó wà ní àgbègbè Nunavut ní Kánádà. Torí náà, àwọn aṣáájú-ọ̀nà méjì wọ ọkọ̀ òfuurufú lọ sí abúlé kékeré náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í darí ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbẹ̀. Lẹ́yìn tí ọkùnrin kan wo fídíò Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba? ó bi wọ́n pé ìgbà wo ni wọ́n máa kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba sí abúlé àwọn. Ó ní: “Tí mo bá ṣì wà ní abúlé yìí nígbà tí ẹ bá kọ́ ọ, màá máa wá sí ìpàdé.”
Àwọn aṣáájú-ọ̀nà tí wọ́n rán lọ sí àgbègbè Savukoski ní Finland níbi tí àwọn ìgalà ti pọ̀ ju àwọn èèyàn lọ ní ìlọ́po mẹ́wàá sọ pé: “Òtútù ibẹ̀ pọ̀ gan-an ni, yìnyín sì tún máa ń jábọ́.” Síbẹ̀, wọ́n sọ pé ìgbà tó dára jù làwọn lọ síbẹ̀. Kí nìdí tí wọ́n fi sọ bẹ́ẹ̀? Wọ́n sọ pé: “A ti ṣe àwọn àgbègbè yìí kúnnákúnná, torí pé àwọn ọ̀nà tó já sí àwọn abúlé náà dáa, wọ́n sì ṣeé gbà. Òtútù ò sì jẹ́ kí àwọn èèyàn lè kúrò nílé.”
Ìsapá tá a ṣe láti kọ́ àwọn tó wà láwọn àgbègbè àdádó náà ní ẹ̀kọ́ Bíbélì ti wá gba àfíyèsí àwọn èèyàn. Lẹ́yìn tí àwọn aṣáájú-ọ̀nà méjì kan wàásù fún obìnrin kan tó jẹ́ olórí ọ̀kan lára àwọn ìlú tó wa ní Alaska, obìnrin náà gbé àwọn ìsọfúnni tó dára nípa jíròrò tó ní pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí náà sórí ìkànnì àjọlò, ó sì tún gbé àwòrán ìwé àṣàrò kúkúrú Kí ni Ìjọba Ọlọ́run?
Ní ìlú Haines ní Alaska, ẹni mẹ́jọ ló wá sí ìpàdé táwọn aṣáájú-ọ̀nà méjì tó wà lágbègbè náà ṣe níbi ìkówèésí ìlú náà. Ìwé ìròyìn àdúgbó náà tiẹ̀ ròyìn pé àwọn ọkùnrin méjì kan tí wọ́n wá láti Texas àti North Carolina ti wà nílùú, wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ nínú ilé wọn. Ìwé ìròyìn náà wá sọ ní ìparí ìkéde rẹ̀ pé: “Lọ sí orí ìkànnì jw.org kó o lè mọ púpọ̀ sí i.”