Wọ́n Pàtẹ “Ẹ̀bùn tí Ọlọ́run Fún Àwọn Èèyàn” ní Ìlú Ìṣúra
Ọ̀kan lára ìlú tó tóbi jù lórílẹ̀-èdè Ròmáníà ni Cluj-Napoca, Ìlú Ìṣúra ni wọ́n mọ̀ ọ́n sí. Nígbà ìpàtẹ ìwé Gaudeamus tí wọ́n ṣe nílùú náà láti April 20 sí 24 lọ́dún 2016, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ káwọn èèyàn rí ohun tí Bíbélì sọ nípa ìwà rere àti bí wọ́n ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run. Wọ́n pàtẹ àwọn fídíò, àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì àtàwọn Bíbélì síbi ìpàtẹ ìwé náà, wọ́n sì bá ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tó wá síbẹ̀ sọ̀rọ̀ bí wọ́n ṣe ń béèrè nípa àwọn ohun tí wọ́n rí lórí àtẹ.
Ọ̀pọ̀ iléèwé ló kó àwọn ọmọ wá síbi ìpàtẹ náà, àwọn olùkọ́ sì kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn wá wo ìpàtẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà gbádùn àwọn fídíò bèbí tá a pe àkòrí rẹ̀ ní Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà gan-an, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló sì sọ pé àwọn fẹ́ gba Ìwé Ìtàn Bíbélì àti ìwé Kọ́ Ọmọ Rẹ. Nígbà tí obìnrin kan tó ń ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn ọmọdé rí àwọn fídíò bèbí náà, ó sọ fún ẹni tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ pé, “Ó yẹ ká kọ orúkọ ìkànnì yìí [ìyẹn www.pr418.com] sílẹ̀ o, ká lè fi gbogbo fídíò bèbí tó wà níbẹ̀ han àwọn ọmọ.”
Àwọn fídíò eré ojú pátákó tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi hàn lórí tablet wú àwọn ọ̀dọ́ lórí gan-an. Ara àwọn fídíò tí wọ́n fi hàn ni Ṣé Ìfẹ́ Tòótọ́ Ni àbí Ìfẹ́ Ojú Lásán?, Máa Fọgbọ́n Lo Ìkànnì Àjọlò, àti Bó O Ṣe Lè Borí Ẹni Tó Ń Halẹ̀ Mọ́ Ẹ Láì Bá A Jà.
Léraléra ni àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì kan àti ìyàwó rẹ̀ lọ síbi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàtẹ sí, tí wọ́n ń gba Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun àtàwọn ìwé pẹlẹbẹ kan. Àlùfáà náà sọ pé òun fẹ́ràn apá tá a pè ní “Atọ́ka Àṣàyàn Ọ̀rọ̀ Bíbélì” gan-an, ó sì sọ pé ó wú òun lórí nígbà tóun kà nípa ọ̀pọ̀ ìwé àfọwọ́kọ àtàwọn ohun èlò míì tó ṣeé fọkàn tán táwọn tó túmọ̀ Bíbélì náà lò. Ó fún àwọn Ẹlẹ́rìí ní nọ́ńbà rẹ̀, ó sì ní kí wọ́n pe òun káwọn lè jọ sọ̀rọ̀ sí i nípa Bíbélì.
Ìyàwó àlùfáà náà béèrè ibi tóun ti lè rí ìsọfúnni nípa àwọn ọmọdé lórí ìkànnì jw.org, wọ́n sì fi apá tá a pè ní “Àwọn Ọmọdé” hàn án lórí ìkànnì náà. Ó wá wo fídíò Jẹ́ Olóòótọ́, ó sì gbádùn ẹ̀ gan-an. Lẹ́yìn tí ọkọ rẹ̀ wo abala yìí àtàwọn ohun míì tó wà lórí ìkànnì náà, ó pè é ní “ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún àwọn èèyàn.”