Wọ́n Rìn Gba Àárín Òkun Kọjá Láti Lọ Wàásù
Àwọn èèyàn tí iye wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ló ń gbé ní erékùṣù Halligen tó wà níbi òkun àríwá tó wà nítòsí etíkun ìwọ̀ oòrùn ìpínlẹ̀ Schleswig-Holstein lórílẹ̀-èdè Jámánì. Kí ló máa ń ná àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti lè lọ wàásù fún àwọn tó ń gbé ní erékùṣù yìí?—Mátíù 24:14.
Àwa ẹlẹ́rìí máa ń wọ ọkọ̀ ojú omi kékeré tá a bá fẹ́ lọ wàásù láwọn erékùṣù kan níbẹ̀. Àmọ́ ọ̀rọ̀ kì í fìgbà gbogbo rí bẹ́ẹ̀ tá a bá ń lọ sáwọn erékùṣù míì, ó máa ń gbà pé káwọn àwùjọ kékeré kan fẹsẹ̀ rin ìrìn kìlómítà márùn-ún gba àárín òkun kọjá. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe é?
Wọ́n Ń Lo Àǹfààní Ìgbì Òkun
Ìgbì òkun ló ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Ní abúlé yìí, láàárín wákàtí mẹ́fà òkun yìí fi nǹkan bí ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà kún sí i tàbí fà sí i! Nígbà tí ìgbì òkun yẹn bá lọ sílẹ̀, a máa ń fẹsẹ̀ lọ wàásù láwọn erékùṣù mẹ́ta torí èyí tó pọ̀ jù lára ibi tí omi òkun yẹn kún dé ló ti máa gbẹ.
Báwo ni ìrìn àjò yìí ṣé máa ń rí? Ulrich tó nírìírí nípa ìrìn àjò tó sì tún ṣáájú àwọn tó lọ síbẹ̀ sọ pé: “A máa ń rin ìrìn wákàtí méjì ká tó dé erékùṣù kan. Lọ́pọ̀ ìgbà ẹsẹ̀ lásán la máa fi ń rìn. Ọ̀nà tó rọrùn jù lọ tá a fi lè gba àárín òkun náà kọjá nìyẹn. Láwọn àsìkò òtútù ṣe la máa ń wọ àwọn bàtà tó gùn dé orúnkún.”
Ulrich tún sọ pé: Ọ̀rọ̀ náà máa ń dà bí nǹkan nígbà míì torí ṣe ló máa ń dà bí pé inú ayé míì la ti ń rìn. Ẹrẹ̀ máa pọ̀ láwọn ibì kan, àwọn ibòmíì sì rèé àpáta ni, nígbà tó sì tún jẹ́ pé àwọn ewéko òkun ló máa bo àwọn ibòmíì mọ́lẹ̀. Ẹ máa rí àwọn ẹyẹ etíkun tó pọ̀, alákàn, àtàwọn ẹranko míì.” Àwùjọ yìí tún máa gba ibi omi kan tí wọ́n ń pè ní Priele lédè Jámánì kọjá.
Kì í rọrùn fáwọn tó ń fẹsẹ̀ rìn. Ulrich kìlọ̀ pé: “Ó rọrùn láti sọnù, pàápàá tí kùrukùru bá bo ojú ọjọ́. Torí náà, a máa ń lo kọ́ńpáàsì àti ẹ̀rọ GPS tó máa ń júwe ọ̀nà láti fi rìnrìn àjò, a sì tún máa ń fọwọ́ pàtàkì mú ètò tá a ṣe ká má bá à kó sí páńpẹ́ ìgbì òkun tó ń ru bọ̀.”
Ṣé ó yẹ kí wàhálà yìí pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Ulrich sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin kan tó sábà máa ń ka ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tó sì tún ti lé lẹ́ni àádọ́rùn-ún [90] ọdún, ó sọ pé torí pé ọjọ́ ti ń lọ, àwọn ò ráyè dé ọ̀dọ̀ ọkùnrin yìí, ni ọkùnrin náà bá gbé kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ó sì lé àwọn bá, ó wá sọ pé: ‘Ṣé ẹ ò ní fún mi ní ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ mi ni?’ Inú wa dùn láti fún-un.”