Wọ́n Ń Túmọ̀ Èdè Láìkọ Ọ́ Sílẹ̀
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti túmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì láti èdè Gẹ̀ẹ́sì sí èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900). Kì í ṣe iṣẹ́ kékeré láti túmọ̀ èdè kan sí èdè míì. Àmọ́ iṣẹ́ títúmọ̀ sí èdè àwọn adití tún wá légbá kan. Ọwọ́ àti ìrísí ojú ni ọ̀pọ̀ àwọn adití fi máa ń bára wọn sọ̀rọ̀, torí náà, ṣe làwọn tó ń túmọ̀ èdè adití máa ń túmọ̀ ohun tó wà lórí ìwé, tí wọ́n á sì sọ ọ́ di fídíò. Bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ṣe é nìyí tí wọ́n fi túmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde sí èdè àwọn adití tó lé ní àádọ́rùn-ún (90).
Àwọn wo ló ń ṣiṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè yìí?
Bíi ti gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jẹ́ atúmọ̀ èdè, àwọn tó ń túmọ̀ èdè adití máa ń gbọ́ èdè náà dáadáa. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló jẹ́ adití, tó sì jẹ́ pé èdè yẹn ni wọ́n sọ dàgbà. Àwọn atúmọ̀ èdè míì lè gbọ́, wọ́n sì lè sọ, àmọ́ kó jẹ́ pé àárín àwọn mọ̀lẹ́bí wọn tó jẹ́ adití ni wọ́n gbé dàgbà. Àwọn tó ń túmọ̀ èdè yìí tún máa ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Àwọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ di atúmọ̀ èdè máa ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó yarantí lórí àwọn ìlànà tó bá iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè rìn. Bí àpẹẹrẹ, Andrew sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo lọ síléèwé àwọn adití ní kékeré, tí mo sì máa ń sọ èdè adití, síbẹ̀ ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí mo gbà nígbà tí mo di atúmọ̀ èdè ti jẹ́ kí n lóye bí wọ́n ṣe ń hun ọ̀rọ̀ ní èdè náà. Àwọn atúmọ̀ èdè yòókù kọ́ mi bí màá ṣe túbọ̀ já fáfá tí mo bá ń fi ọwọ́, ojú tàbí ara ṣàpèjúwe, kí n lè ṣiṣẹ́ ìtúmọ̀ tó péye.”
Bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè tó péye
Àwùjọ-àwùjọ làwọn atúmọ̀ èdè máa ń ṣiṣẹ́. Nínú àwùjọ kọ̀ọ̀kan, kálukú ló níṣẹ́ tiẹ̀, ẹnì kan á máa ṣe ìtúmọ̀, ẹnì kan á máa wò ó bóyá ọ̀rọ̀ kan ti sọ nú àbí wọ́n ti fi ọ̀rọ̀ kún un, ẹnì kan á sì máa rí sí i pé bí àwọn tó ń sọ èdè náà ṣe ń sọ ọ́ ni wọ́n ṣe túmọ̀ ẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti túmọ̀ ìtẹ̀jáde kan, tó bá ṣeé ṣe, wọ́n lè ní kí àwọn adití kan láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí wọ́n sì dàgbà níbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ yẹ iṣẹ́ náà wò. Àkíyèsí táwọn adití náà bá ṣe máa jẹ́ káwọn atúmọ̀ èdè náà mọ bí wọ́n ṣe lè jẹ́ kí ohun tí wọ́n ti túmọ̀ tẹ́lẹ̀ sunwọ̀n sí i. Àyẹ̀wò yìí ló máa jẹ́ kí wọ́n lè rí sí i pé iṣẹ́ ìtúmọ̀ tí wọ́n ṣe bá bí àwọn adití ṣe máa ń fara ṣàpèjúwe mu, wọ́n á sì lè mọ̀ pé tí wọ́n bá ṣe é sí fídíò tán, ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ máa péye, á sì yé àwọn tó ń wò ó.
Ìpàdé ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè adití làwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìtúmọ̀ sí èdè adití sábà máa ń lọ. Bákan náà, wọ́n sábà máa ń kọ́ àwọn adití tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn nǹkan yìí máa ń jẹ́ káwọn atúmọ̀ èdè mọ bí àwọn tó ni èdè ṣe ń sọ èdè wọn, wọ́n á sì mọ̀ tí àyípadà èyíkéyìí bá dé bá bí wọ́n ṣe ń sọ ọ́.
Kí ló jẹ́ kí wọ́n máa sapá tó tóyìí?
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn èèyàn látinú “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n” máa tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ìtùnú àti ìrètí tó wà nínú Bíbélì. (Ìṣípayá 7:9) Ó sì dájú pé àwọn tó ń sọ èdè adití náà wà lára wọn.
Tayọ̀tayọ̀ làwọn tó ń túmọ̀ èdè náà fi ń lo àkókò wọn àti okun wọn láti ṣiṣẹ́ tó nítumọ̀ yìí. Atúmọ̀ èdè kan tó ń jẹ́ Tony sọ pé: “Torí pé adití ni mí, ohun tójú àwọn adití bíi tèmi ń rí máa ń tètè yé mi. Ó ti pẹ́ tó ti máa ń wù mí gan-an láti rí i pé mo kàn sí ọ̀pọ̀ àwọn adití bó bá ṣe lè ṣeé ṣe tó kí n lè fi ìrètí tòótọ́ tí Bíbélì jẹ́ ká ní hàn wọ́n.”
Amanda, tóun náà ń ṣiṣẹ́ ìtúmọ̀ sí èdè adití sọ pé: “Ní báyìí tí mo ti ń túmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde tó máa jẹ́ káwọn adití mọ ohun tó wà nínú Bíbélì, mo gbà pé mo wúlò gan-an ju ìgbà tí mo wà níbi tí mo ti ń ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀.”
Báwo lo ṣe lè rí àwọn fídíò ní èdè adití tó o gbọ́?
Apá tá a pè ní “Find Sign-Language Content” máa jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè dé ibi tí àwọn fídíò èdè adití wà lórí ìkànnì jw.org.