Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Bá A Ṣe Ń Ya Àwọn Àwòrán Tó Gbé Kókó Ọ̀rọ̀ Jáde

Bá A Ṣe Ń Ya Àwọn Àwòrán Tó Gbé Kókó Ọ̀rọ̀ Jáde

Báwo ni àwọn ayàwòrán wa ṣe máa ń ya àwọn àwòrán tó fani mọ́ra tó wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa, tí àwọn àwòrán náà á sì gbé kókó ọ̀rọ̀ inú ìtẹ̀jáde náà jáde? Ká lè ṣàlàyé báa ṣe ń ṣe é, wó bá a ṣe ṣe iwájú ìwé ìròyìn Jí! November-December 2015 àti bá a ṣe ya àwòrán iwájú ìwé. *

  • Bá a ṣe ṣe é. Àwọn ayàwòrán tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ọnà, tó wà ní Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower ní ìlú Patterson, ìpínlẹ̀ New York kọ́kọ́ ka àpilẹ̀kọ tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Èrò Tó Yẹ Ká Ní Nípa Owó.” Lẹ́yìn náà, wọ́n fọwọ́ ya àwọn àwòrán tó ṣàlàyé ohun tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà. Wọ́n wá gbé àwòrán tí wọ́n fọwọ́ yà yìí lọ sọ́dọ̀ Ìgbìmọ̀ Ìkọ̀wé tó ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ Ìgbìmọ̀ Olùdarí, àwọn ni wọ́n sì yan irú àwòrán tí wọ́n máa ya fọ́tò rẹ̀.

    Díẹ̀ lára àwọn àwòrán tá a kó fún Ìgbìmọ̀ Ìkọ̀wé pé kí wọ́n yẹ̀ wò

  • Ibi tí wọ́n ti máa yà á. Kàkà kí wọ́n lọ sí inú báǹkì láti ya fọ́tò yìí, inú Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower ni àwọn ayàwòrán tún tò kó lè dà bíi báǹkì. *

  • Àwọn Olùkópa. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni gbogbo àwọn tá a yà síbẹ̀, a sì yan oríṣiríṣi àwọn èèyàn tó jọ àwọn oníbàárà tó máa ń wá sáwọn báǹkì tó wà láwọn ìlú ńlá. A máa ń ṣàkọsílẹ̀ àwọn tá a ti lo fọ́tò wọn rí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa, ká má báa máa lo àwọn kan náà ní gbogbo ìgbà.

  • Àwọn nǹkan tá a lò. Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ọnà lọ wá àwọn owó ilẹ̀ òkèèrè kó lè dà bíi pé kì í ṣe ìlú Amẹ́ríkà ni báǹkì náà wà. Àwọn ayàwòrán lo oríṣiríṣi irin iṣẹ́ tó máa jẹ́ kí àwòrán náà jọ báǹkì gidi, kó sì rí bí ohun tó ṣẹ́lẹ̀ lóòótọ́. Ayàwòrán kan tó ń jẹ́ Craig sọ pé “A ò fojú kéré ohunkóhun.”

  • Aṣọ àti ìṣaralóge. Ṣe làwọn tó kópa níbi tá a ti ya àwòrán báǹkì yẹn mú aṣọ wọn wá láti ilé. Àmọ́ o, tó bá jẹ́ pé àwòrán nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àtijọ́ kan ni tàbí àwòrán tó jẹ́ aṣọ pàtó kan ní wọ́n gbọ́dọ̀ wọ̀, Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ọnà máa ṣèwádìí, wọ́n á sì ṣe aṣọ tó bá a mu wẹ́kú. Àwọn aṣaralóge máa ń múra fún àwọn tá a fẹ́ ya fọ́tò wọn kí ìrísí wọn lè bá àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ náà mu, kó bá ohun tí àpilẹ̀kọ náà sọ mu, kò sì bára mu pẹ̀lú àwọn nǹkan míì tó wà nínú fọ́tò náà. Craig sọ pé, “Torí pé àwọn fọ́tò òde òní máa ń hàn kedere gan-an, ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo ohun tá a ṣètò ṣe rẹ́gí kí fọ́tò náà lè dáa, torí pé àṣìṣe kékeré kan lè ba gbogbo ẹ̀ jẹ́.”

  • Ìgbà tá à ń ya fọ́tò. Àwọn tó ya fọ́tò náà rí i dájú pé ìtànṣán iná tí wọ́n lò jẹ́ kó rí bíi pé ọ̀sán ni wọ́n wà ní báǹkì náà. Ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ń ya fọ́tò, àwọn tó ń ya fọ́tò náà gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ìtànṣán iná tí wọ́n lò bá ohun tí wọ́n fẹ́ mu (bóyá wọ́n fẹ́ kó jọ pé òòrùn ń mú ni o, tàbí òṣùpá ló ń ràn, tàbí iná títì ló tàn), kó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú iná tó wà níbi tí wọ́n ti ya fọ́tò náà, kó sì tún bá ohun tó ń ṣẹlẹ̀ mu. Craig sọ pé, “Fọ́tò yàtọ̀ sí fídíò torí àwòrán kan ṣoṣo lẹ fẹ́ fi gbé ìmọ̀lára jáde, ìdí nìyẹn tí ìtànṣán iná fi ṣe pàtàkì gan-an.”

  • Àtúnṣe. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn tó ń ṣàtúnṣe sí fọ́tò ṣe é tí irú owó tí wọ́n mú dá ní nínú àwòrán náà kò fi ní hàn kedere, kó má bàa di pé owó tí wọ́n mú dá ní làwọn èèyàn á máa wò dípò àwọn èèyàn tó wà nínú fọ́tò náà. Àwọ̀ pupa ni wọ́n kun àwọn igi ilẹ̀kùn àti igi fèrèsé inú àwòrán yẹn, àmọ àwọn tó ń tún fọ́tò ṣe ló kùn ún ní àwọ̀ ewé kó lè bá àwọ̀ tí wọ́n lò jù nínú ìtẹ̀jáde yẹn mu.

Yàtọ̀ sí àwọn fọ́tò tí à ń yà ní Patterson, a tún lè sọ pé káwọn tó máa ń ya fọ́tò láwọn ẹ̀ka ọ́fíísì wa bí Ọsirélíà, Brazil, Kánádà, Jámánì, Japan, Korea, Màláwì, Mẹ́síkò, àti South Africa fi àwọn fọ́tò ránṣẹ́ sí wa ká lè lò wọ́n nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa. Oṣooṣù ni Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ọnà tó wà ní Patterson máa ń fi fọ́tò tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ [2,500] kún àwọn tí wọ́n ní tẹ́lẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn àwòrán yìí ni wọ́n máa ń tẹ̀ sínú àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Iye tó lé ní mílíọ̀nù márùndínlọ́gọ́fà [115] ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la pín lóṣooṣù lọ́dún 2015. Inú wa á dùn, tó o bá wá ṣèbẹ̀wò sí ọ́fíísì wa tó wà ní Patterson, nílùú New York tàbí ẹ̀ka ọ́fíísì wa èyíkéyìí tó wà káàkiri ayé kó o lè mọ púpọ̀ sí i nípa iṣẹ́ wa.

Wọ́n ń fi ìwé ìròyìn lọni lóde ẹ̀rí

^ ìpínrọ̀ 2 Tá a bá fẹ́ ya fọ́tò tá a máa lò fún àwòrán iwájú ìwé kan, a sábà máa ń ya èyí tó ju iye tá a nílò lọ. A máa ń tọ́jú àwọn tó kù tá ò lò pa mọ́ síbi tá à ń kó àwọn fọ́tò wa sí ká lè lò wọ́n lọ́jọ́ iwájú.

^ ìpínrọ̀ 4 Tó bá jẹ́ pé àárín ìgboro la ti fẹ́ ya fọ́tò kan, Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ọnà máa gbàṣẹ lọ́wọ́ àwọn aláṣẹ, wọ́n á sọ iye èèyàn tí wọ́n fẹ́ lò, àwọn ohun èlò tí wọ́n á lò àti irú ìtànṣán iná tí wọ́n á lò nígbà tí wọ́n bá ń ya fọ́tò náà.