Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ó “Dáa Ju Àwọn Sinimá Àgbéléwò Lọ”

Ó “Dáa Ju Àwọn Sinimá Àgbéléwò Lọ”

Ọdọọdún làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe oríṣiríṣi fídíò tí wọ́n máa gbé jáde láwọn àpéjọ àgbègbè wọn. Èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n fi máa ń ṣe ọ̀pọ̀ nínú àwọn fídíò náà. Báwo wá ni àwọn fídíò yìí ṣe máa yé àwọn tó ń fi ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè tó yàtọ̀ sí Gẹ̀ẹ́sì ṣe àpéjọ àgbègbè wọn? Ohun tí èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn tó ń sọ èdè yẹn máa ń ṣe ni pé, wọ́n máa túmọ̀ Gẹ̀ẹ́sì inú àwọn fídíò náà sí èdè tiwọn, wọ́n á gbohùn sílẹ̀ ní èdè yẹn, wọ́n á wá fi kọ̀ǹpútà gbé ohùn tí wọ́n gbà sílẹ̀ sínú àwọn fídíò náà. Báwo ni àwọn fídíò tí wọ́n ṣe ní èdè àbínibí yìí ṣe máa ń rí lára àwọn tó wá sí àpéjọ náà?

Bí Àwọn Fídíò Tá A Ṣe Lédè Àbínibí Ṣe Rí Lára Àwọn Èèyàn

Àwọn kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá síbi àpéjọ àgbègbè ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò àti Central America. Wo ohun tí wọ́n sọ.

  • “Kì í ṣe pé fíìmù tá a wò yé mi nìkan ni, ṣe ló tún ń ṣe mí bíi pé mo wà níbi tí ohun tá à ń wò yẹn ti ń ṣẹlẹ̀. Ó wọ̀ mí lọ́kàn gan-an.”​​—Ẹni tó lọ sí àpéjọ àgbègbè lédè Popoluca, ní ìpínlẹ̀ Veracruz, ní Mẹ́síkò.

  • “Ṣe ló ń ṣe mí bíi pé mo wà nílùú ìbílẹ̀ mi, tí mò ń bá ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ kan sọ̀rọ̀. Fíìmù yẹn dáa ju àwọn sinimá àgbéléwò lọ torí pé gbogbo ohun tí wọ́n ń sọ níbẹ̀ ló yé mi.”​​—Ẹni tó lọ sí àpéjọ àgbègbè lédè Nahuatl, ní Nuevo León, Mẹ́síkò.

  • “Nígbà tí mo wo àwọn fíìmù yẹn lédè mi, àfi bíi pé èmi láwọn tó ń sọ̀rọ̀ nínú fíìmù náà ń bá wí.”​​—Ẹni tó lọ sí àpéjọ àgbègbè lédè Chol, ní Tabasco, Mẹ́síkò.

  • “Ohun tó jẹ ètò yìí lógún ni pé kí wọ́n kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ ní èdè tiwọn fúnra wọn. Kò sí ètò míì bíi rẹ̀!”​​—Ẹni tó lọ sí àpéjọ àgbègbè lédè Cakchiquel, ní Sololá, lórílẹ̀-èdè Guatemala.

Pẹ̀lú bó ṣe jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi owó pe àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tàbí àwọn eléré orí ìtàgé tó ń gbohùn sílẹ̀, tó sì jẹ́ pé àwọn ibi tó wà ní àdádó, tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ lajú ni wọ́n ti sábà máa ń gbohùn sílẹ̀, báwo wá ni wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ tó jójúlówó tó bẹ́ẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ká gbohùn sílẹ̀?

‘Iṣẹ́ Tó Ń Mérè Wá Jù’

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Central America ṣe kòkárí bí wọ́n ṣe máa gbohùn sílẹ̀ fún àwọn fídíò ní èdè Spanish àtàwọn èdè àbínibí méjìdínlógójì [38] míì. Àwọn bí ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ [2,500] ló yọ̀ǹda ara wọn láti ṣèrànwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ yìí. Àwọn amojú ẹ̀rọ àtàwọn atúmọ̀ èdè gba ohùn sílẹ̀ láwọn èdè àbínibí ní ẹ̀ka ọ́fíìsì, láwọn ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè àti láwọn ilé míì tí wọ́n ṣe torí àtifi gbohùn sílẹ̀ fúngbà díẹ̀. Ní kúkúrú, ibi tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ yìí lé ní ogún [20], wọ́n ṣe é ní orílẹ̀-èdè Belize, Guatemala, Honduras, Mẹ́síkò àti Panama.

Wọ́n ń gbohùn sílẹ̀ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Central America

Iṣẹ́ kékeré kọ́ ni wọ́n ṣe kí wọ́n tó lè ṣe àwọn ilé tí wọ́n fẹ́ fi gbohùn sílẹ̀ fúngbà díẹ̀, kódà iṣẹ́ ọpọlọ ni. Nígbà tí wọ́n fẹ́ ṣe àwọn yàrá kótópó tí wọ́n á ti máa gbohùn sílẹ̀ lọ́nà tí ohùn tó ń wá láti ìta ò fi ní ráyè máa wọbẹ̀, ìwọ̀nba ohun tí wọ́n rí láyìíká ni wọ́n dọ́gbọ́n lò fi ṣe é, tó fi mọ́ àwọn aṣọ ìbora tó nípọn àtàwọn fóòmù tí wọ́n fi ń sùn.

Ọ̀pọ̀ àwọn tá a gbohùn wọn sílẹ̀ ni ò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ, ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n sì fi du ara wọn torí àtirin ìrìn-àjò lọ síbi tí wọ́n á ti gbohùn wọn sílẹ̀ tó sún mọ́ wọn jù. Kódà, àwọn míì nínú wọn rin ìrìn wákàtí mẹ́rìnlá [14]! Bàbá àti ọmọ kan tiẹ̀ wà tí wọ́n fi nǹkan bíi wákàtí mẹ́jọ rìn kí wọ́n tó débi tí wọ́n á ti gbohùn wọn sílẹ̀.

Ọmọbìnrin kan wà tó ń jẹ́ Naomi. Àtikékeré lòun àti ìdílé ẹ̀ ti máa ń ṣèrànwọ́ láti ṣe àwọn ilé tí wọ́n fi ń gbohùn sílẹ̀ fúngbà díẹ̀. Ó rántí ìgbà yẹn, ó ní: “Gbogbo ìgbà la máa ń wọ̀nà fún ọ̀sẹ̀ tí wọ́n máa gbohùn sílẹ̀. Iṣẹ́ àṣekára ni dádì mi máa ń ṣe láti bójú tó bí nǹkan ṣe ń lọ. Ìgbà míì wà tí mọ́mì mi máa ń se oúnjẹ tó máa bọ́ ọgbọ̀n [30] èèyàn tó yọ̀ǹda ara wọn láti wá ṣiṣẹ́.” Naomi ti yọ̀ǹda ara ẹ̀ láti máa ṣiṣẹ́ ní ọ̀kan lára ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè ní Mẹ́síkò báyìí. Ó sọ pé: “Tí wọ́n bá gẹṣin nínú mi, kò lè kọsẹ̀, torí pé mò ń fi àkókò mi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ ní èdè àbínibí wọn. Mi ò rò pé mo lè ṣiṣẹ́ míì tó ń mérè wá tó báyìí.”

Kárí ayé làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti máa ń ṣe àpéjọ àgbègbè lọ́dọọdún, gbogbo èèyàn la sì pè. Wo abala ÀWỌN ÀPÉJỌ tó o bá fẹ́ ìsọfúnni sí i.