Àkànṣe Iṣẹ́ ìwàásù Gbẹ̀mí Àwọn Èèyàn Là
Àwọn tó ń gbẹ̀mí ara wọn túbọ̀ ń pọ̀ sí i ní ìlú Tabasco lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, ìdí nìyí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ṣètò àkànṣe iṣẹ́ ìwàásù olóṣù méjì lọ́dún 2017, kí wọ́n bàa lè fáwọn èèyàn ní Jí! April 2014 tó sọ pé “Má Ṣe Jẹ́ Káyé Sú Ẹ.” Àwọn èèyàn mọrírì àkànṣe iṣẹ́ ìwàásù táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe yìí.
Ó Bọ́ Sásìkò
Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń jẹ́ Faustino wàásù fún obìnrin kan tó ní ìdààmú ọkàn nítorí ọmọkùnrin rẹ̀ tó ní ìsoríkọ́. Ọmọ náà ò tíì ju ẹni ọdún méjìlélógún [22] lọ, àmọ́ ọ̀pọ̀ ìgbà ló ti gbìyànjú láti pa ara rẹ̀. Ìyá rẹ̀ ò mọ ohun tó máa ṣe láti ràn án lọ́wọ́. Àmọ́ nígbà tí Faustino fún un ní ìwé ìròyìn yẹn, ó sọ pé, “Ohun tí ọmọ mi nílò gan-an rèé.” Lọ́jọ́ kejì, Faustino lọ wo ọmọkùnrin yẹn, wọ́n sì jọ jíròrò àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì tó wà nínú ìwé ìròyìn yẹn. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ tí wọ́n jọ jíròrò, ọmọkùnrin yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà. Faustino sọ pé, “Ní báyìí, ọkàn rẹ̀ ti balẹ̀, inú rẹ̀ sì ń dùn gan-an.” Yàtọ̀ síyẹn, ó tún ń ṣàlàyé àwọn nǹkan tó ti kọ́ fún àbúrò rẹ̀, torí pé òun náà ní ìsoríkọ́.
Karla, tó ń gbé ní ìlú Huimanguillo fi ìwé ìròyìn yìí ran ọmọbìnrin ọmọ ọdún mẹ́rìnlá [14] kan tó wà ní kíláàsì rẹ̀ lọ́wọ́. Karla sọ pé: “Mó kíyè sí pé inú rẹ̀ máa ń bàjẹ́, torí náà, mo bá a sọ̀rọ̀, ó sì sọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé wọn fún mi. Bá a ṣe ń sọ̀rọ̀, mo rí i pé àpá egbò wà ní ọwọ̀ rẹ̀ òsì.” Ṣe ló fi nǹkan ya ara rẹ̀ lọ́wọ́ àti lẹ́sẹ̀. Ṣe ló máa ń wo ara rẹ̀ bí ẹni ìtìjú, ó sì gbà pé ìgbésí ayé òun kò ní ìtumọ̀. Karla fún un ní ìwé ìròyìn Jí! yẹn. Lẹ́yìn tí ọmọbìnrin yẹn kà á, ó sọ fún Karla pé òun gan-an ni wọ́n kọ ìwé ìròyìn yẹn fún. Pẹ̀lú ẹ̀rín lójú, ó sọ pé òun ti wá gbà báyìí pé kò yẹ kẹ́èyàn pa ara rẹ̀.
Ìṣòro dé bá ọkùnrin kan tó ń gbé nílùú Villahermosa. Iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ìyàwó rẹ̀ sí fi í sílẹ̀, ó wá ku òun àtàwọn ọmọ. Ó gbàdúrà sí Ọlọ́run, àmọ́ ó ṣì ń ṣe é bíi pé kò sí ojútùú sí ìṣòro rẹ̀. Bó ṣe ní kóun pa ara òun ni Martín àti Miguel tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ìlẹ̀kùn rẹ̀. Ó ṣí ilẹ̀kùn, wọ́n sì fun un ní ìwé ìròyìn yẹn. Nígbà tí ọkùnrin yẹn rí àkòrí ìwé yẹn, ó gbà pé Ọlọ́run ló dáhùn àdúrà òun. Martín àti Miguel fi Ìwé Mímọ́ tù ú nínú lọ́jọ́ yẹn, nígbà tí wọ́n máa fi pa dà wá lọ́jọ́ míì, ara ọkùnrin yẹn ti balẹ̀ ju ìgbà tí wọ́n kọ́kọ́ wá. Ní báyìí, ẹ̀ẹ̀mejì lọ́sẹ̀ ni ọkùnrin yẹn ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn.
Wọ́n Wàásù Fáwọn Ẹlẹ́wọ̀n
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún lọ sí oríṣiríṣi ẹ̀wọ̀n ní ìlú Tabasco láti lọ sọ̀rọ̀ Bíbélì fáwọn ẹlẹ́wọ̀n kí ìgbésí ayé wọn lè ní ìtumọ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo fídíò, àsọyé Bíbélì àti àwọn kókó tó wà nínú ìwé ìròyìn yẹn láti ṣàlàyé ìdí tí kò fi yẹ kéèyàn pa ara rẹ̀. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n àtàwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n mọrírì bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe wá wàásù fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, ẹlẹ́wọ̀n kan sọ pé: “Ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni mo ti gbìyànjú láti pa ara mi. Àwọn kan ti sọ fún mi pé Ọlọ́run bìkítà nípa mi, àmọ́ wọn ò fi hàn mí nínú Bíbélì, torí náà mi ò gbà pé òótọ́ ni. Àwọn ọ̀rọ̀ tẹ́ ẹ sọ ti gbé mi ró gan-an ni.”
Àwọn èèyàn mọyì iṣẹ́ takuntakun táwọn Ẹlẹ́rìí ṣe gan-an. Akọ̀wé ìlú lórí ọ̀rọ̀ ìlera dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ṣe láti ran àwọn ará ìlú lọ́wọ́. Ìwé ìròyìn kan ládùúgbò yẹn náà gbé àpilẹ̀kọ kan jáde tí àkòrí rẹ̀ sọ pé, “Wọ́n Gbógun Ti Ìṣekúpara Ẹni.”