Àwọn Tó Ń Dáni Lẹ́kọ̀ọ́ ní Philippines Rí Ìwúlò Ìkànnì JW.ORG
Lọ́dún 2016, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láǹfààní láti fi han àwùjọ àwọn kan tó ń dáni lẹ́kọ̀ọ́ ní àgbègbè Zamboanga del Norte lórílẹ̀-èdè Philippines bí àwọn fídíò àtàwọn àpilẹ̀kọ tó wà lórí ìkànnì jw.org ṣe wúlò tó láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Kó tó di pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá àwọn tó ń dáni lẹ́kọ̀ọ́ náà sọ̀rọ̀, wọ́n kọ́kọ́ lọ ṣe àbẹ̀wò sí Ẹ̀ka Tó Ń Rí sí Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́ lágbègbè náà, èyí tó wà nílùú Dipolog tó jẹ́ olú-ìlú rẹ̀. Ìkànnì jw.org wu àwọn alábòójútó ẹ̀ka náà lórí débi pé wọ́n pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kí wọ́n wá fi ọgbọ̀n (30) ìṣẹ́jú ṣe ìdálẹ́kọ̀ọ́ níbi ètò ìdálẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ta tí wọ́n ṣe fáwọn olùkọ́ tó máa wá láti oríṣiríṣi ìlú ní Zamboanga del Norte.
Báwo ni wọ́n ṣe ṣe é?
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi àwọn fídíò àtàwọn àpilẹ̀kọ kan lórí ìkànnì jw.org han nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) olùkọ́ níbi ìdálẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan. Àpilẹ̀kọ kan táwọn tó wá síbẹ̀ gbádùn dọ́ba ni èyí tí àkòrí ẹ̀ sọ pé “Ohun Tí Ẹ Lè Ṣe Nípa Gbèsè.” Ọ̀pọ̀ àwọn olùkọ́ náà ló rí i pé kì í ṣe àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn nìkan ni ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà wúlò fún, ó tún máa wúlò fáwọn náà. Gbogbo wọn ló gba ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ibo La Ti Lè Rí Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Pàtàkì Nípa Ìgbésí Ayé? tó mẹ́nu ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsọfúnni tó wà lórí ìkànnì jw.org tó gbádùn mọ́ni, tó sì wúlò gan-an. Àwọn olùkọ́ kan tiẹ̀ wa fídíò jáde lórí ìkànnì náà.
Ìdálẹ́kọ̀ọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta táwọn Ẹlẹ́rìí ṣe ṣàṣeyọrí gan-an débi pé Ẹ̀ka Tó Ń Rí sí Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́ lágbègbè náà ṣètò pé kí wọ́n ṣe ìdálẹ́kọ̀ọ́ sí i láti ṣèrànwọ́ fún nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) agbani-nímọ̀ràn àtàwọn míì tó ń dáni lẹ́kọ̀ọ́. Ọ̀pọ̀ èèyàn lorí wọn wú, tí wọ́n sì tún gbóríyìn fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́ẹ̀kan sí i.
“Ìkànnì yẹn wúlò gan-an”
Àwọn kan lára àwọn tó wá gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà pa dà ṣàlàyé bí ohun tí wọ́n kọ́ àti ìkànnì jw.org ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́. Olùkọ́ kan sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí n sọ bí mo ṣe mọrírì ìkànnì yẹn tó. Ó wúlò gan-an, mo máa ń fi kọ́ àwọn ọmọ kíláàsì mi.” Olùkọ́ míì sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan ni mò ń kọ́, pàápàá tó bá dọ̀rọ̀ bí mo ṣe lè kojú wàhálà. Ìkànnì yẹn wúlò gan-an, kì í ṣe àwọn ọ̀dọ́ nìkan ló ń ràn lọ́wọ́, ó tún ń ran àwọn tó ti ń dàgbà lọ́wọ́.”
Ó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti àádọ́ta (350) lára àwọn tó ń dáni lẹ́kọ̀ọ́ tó wá síbi ìdálẹ́kọ̀ọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí ṣe tó sọ fáwọn Ẹlẹ́rìí pé àwọn fẹ́ àlàyé sí i. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fìyẹn fún wọn láwọn ìtẹ̀jáde míì, wọ́n sì fi àwọn ọ̀rọ̀ tó wúlò tó wà nínú Bíbélì han gbogbo àwọn tó béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ wọn.
Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dùn gan-an pé ó lé ní ẹgbẹ̀rún kan (1,000) àwọn tó ń dáni lẹ́kọ̀ọ́ tó wá síbi ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ṣe nípa ìkànnì jw.org ní Zamboanga del Norte, tí wọ́n sì kọ́ nípa bí ìkànnì jw.org ṣe wúlò tó láti kọ́ àwọn míì. Ohun èlò tó wúlò gan-an ni ìkànnì yìí jẹ́, kárí ayé ló sì ti lè ṣe àwọn tó ń dáni lẹ́kọ̀ọ́ láǹfààní tó bá dọ̀rọ̀ ìtọ́sọ́nà lórí ìwà híhù, ìwà ọmọlúàbí àti béèyàn ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run. *
^ ìpínrọ̀ 9 Ojúṣe àwọn iléeṣẹ́ tó bójú tó ìmọ̀ ẹ̀kọ́ lórílẹ̀-èdè Philippines ni láti jẹ́ kí àwọn ọmọ iléèwé ní ìmọ̀, kì í ṣe ìyẹn nìkan, kí wọ́n tún “kọ́ wọn bí wọ́n ṣe ń hùwà, bí wọ́n ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run, [àti bí wọ́n ṣe lè] jẹ́ ọmọlúàbí, kí wọ́n sì mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.”—Òfin Orílẹ̀-èdè Philippines ti Ọdún 1987, Abala XIV, Ìsọ̀rí 3.2.