Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ń Kọ́ Àwọn Òbí Àtàwọn Ọmọ Nítorí Àwọn Tó Ń Bá Ọmọdé Ṣèṣekúṣe
Bíbélì rọ àwọn òbí pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n dáàbò bò wọ́n, kí wọ́n máa tọ́ wọn sọ́nà, kí wọ́n sì mọ̀ pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni wọ́n. (Sáàmù 127:3; Òwe 1:8; Éfésù 6:1-4) Ọ̀kan lára àwọn ohun tó lè wu ọmọ léwu ni àwọn tó máa ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe. Torí náà, ó yẹ káwọn òbí dáàbò bo àwọn ọmọ wọn kí wọ́n má bàa kó sọ́wọ́ irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀.
Ọ̀pọ̀ ọdún làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń tẹ àwọn ìwé tó ń jẹ́ káwọn tó wà nínú ìdílé ṣe ara wọn lọ́kan. Yàtọ̀ síyẹn, a ti ṣe àwọn ìwé tó ń ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ àwọn tó ń bá ọmọdé ṣèṣekúṣe àti bí àwọn ọmọ náà ṣe lè dá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ mọ̀. Díẹ̀ lára àwọn ìwé táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti tẹ̀ jáde ló wà nísàlẹ̀ yìí. Àwọn àpilẹ̀kọ náà fún wa láwọn ìsọfúnni pàtó lórí àwọn ọ̀rọ̀ yìí. Ẹ kíyè sí iye ẹ̀dà tá a tẹ̀ jáde àti iye èdè tá a tú àwọn àpilẹ̀kọ náà sí.
Àkòrí: Ibalopọ̀ Takọ-tabo Laaarin Ibatan—Iwa Ọdaran Ti O Farasin
Ìtẹ̀jáde: Jí! April 8, 1982
Ẹ̀dà: 7,800,000
Èdè: 34
Àkòrí: Iranlowo fun Awọn Ẹran-ijẹ Ibalopọ Takọtabo Laarin Ibatan
Ìtẹ̀jáde: Ilé Ìṣọ́ April 1, 1984
Ẹ̀dà: 10,050,000
Èdè: 102
Àkòrí: Ìfìtínà Ọmọdé—Àlá Buburu fun Gbogbo Iya; Ìfìtínà Ọmọdé—Tani Yoo Ṣe Iru Nkan Bẹẹ?’; Ìfìtínà Ọmọdé—Iwọ Lè Daabo Bo Ọmọ Rẹ
Ìtẹ̀jáde: Jí! July 22, 1986
Ẹ̀dà: 9,800,000
Èdè: 54
Àkòrí: Awọn Òjìyà Ipalara Aláìmọwọ́mẹsẹ̀ ti Ìlòkulò Ọmọdé; Awọn Ọgbẹ́ Fifarasin ti Lilo Ọmọde Nílòkulò
Ìtẹ̀jáde: Jí! March 8, 1992
Ẹ̀dà: 12,980,000
Èdè: 64
Àkòrí: Ọmọ Rẹ Wà Ninu Ewu!; Bawo Ni A Ṣe Lè Dáàbò Bo Awọn Ọmọ Wa?; Ìdènà Ninu Ilé
Ìtẹ̀jáde: Jí! October 8, 1993
Ẹ̀dà: 13,240,000
Èdè: 67
Àkòrí: Protect Your Children
Ìtẹ̀jáde: Public Service Announcement Video Number 4, tá a ṣe jáde lọ́dún 2002
Èdè: 2
Àkòrí: Bí Ọlọ́run Ṣe Dáàbò Bo Jésù
Ìtẹ̀jáde: Orí 32 nínú ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà, tá a tẹ̀ jáde lọ́dún 2003
Ẹ̀dà: 39,746,022
Èdè: 141
Àkòrí: Ewu Tí Gbogbo Òbí Ń Kọminú Lé Lórí; Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Yín; Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Mú Kí Ilé Yín Jẹ́ Ibi Ààbò
Ìtẹ̀jáde: Jí! October 2007
Ẹ̀dà: 34,267,000
Èdè: 81
Àkòrí: Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Kó Sọ́wọ́ Àwọn Tó Ń Fipá Báni Lò Pọ̀?; Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Òbí Ń Béèrè: Ṣé Ó Yẹ Kí N Bá Ọmọ Mi Sọ̀rọ̀ Nípa Ìbálòpọ̀?
Ìtẹ̀jáde: Orí 32 àti àfikún inú ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní, tá a tẹ̀ jáde lọ́dún 2011
Ẹ̀dà: 18,381,635
Èdè: 65
Àkòrí: Báwo Ni Àwọn Òbí Ṣe Lè Kọ́ Àwọn Ọmọ Wọn Nípa Ìbálòpọ̀?
Ìtẹ̀jáde: Ìkànnì jw.org; àpilẹ̀kọ kan tó jáde ní September 5, 2013
Èdè: 64
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà á ṣì máa kọ́ àwọn òbí àtàwọn ọmọ káwọn ọmọ náà má bàa kó sọ́wọ́ àwọn tó ń bá ọmọdé ṣèṣekúṣe.