Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ní Italy Ran Àwọn Aládùúgbò Wọn Lọ́wọ́
Lẹ́yìn tí òjò tó lágbára gan-an rọ̀ ní àríwá orílẹ̀-èdè Italy ní November 2016, omi ya wọ àwọn abúlé kan ní gúúsù ìlú Moncalieri. Láwọn ibì kan, omi yẹn ga tó ààbọ̀ mítà (1.6 ft). Ìwé ìròyìn kan sọ pé, “Kò sí ibi tí omi yẹn kò dé.” Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni àwọn aláṣẹ ní kí àwọn 1,500 tó ń gbé láwọn àdúgbò yẹn kúrò níbẹ̀, ọpẹ́lọpẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ tó máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nígbà ìjábá, àwọn ni kò jẹ́ kí ẹnì Kankan kú. Àmọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló pàdánù nǹkan ìní wọn.
Wọ́n Ṣètò Ara Wọn
Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ náà ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Wọ́n bá àwọn kan kó ẹrọ̀fọ̀ àti àwọn ìdọ̀tí kúrò nínú ilé wọn, wọ́n sì bá wọn fọ àwọn àga, tábìlì àti àwọn nǹkan ìní wọn míì. Kódà nígbà tí àwọn aláṣẹ dí ọ̀nà, wọ́n gbà kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan kọjá nígbà tí wọ́n fẹ́ lọ ran ìdílé kan lọ́wọ́ pẹ̀lú irinṣẹ́ àti oúnjẹ gbígbóná tó wà lọ́wọ́ wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ ran àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin wọn lọ́wọ́, wọ́n tún ran àwọn míì tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́.
Bí àpẹẹrẹ, omi kún inú àjà ilẹ̀ nínú ilé àwọn kan. Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tó ń rí sí ìjábá wá bá wọn fa omi náà kúrò, lẹ́yìn náà àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá bá ìdílé arákùnrin kan tó ń jẹ́ Antonio kó ìdọ̀tí tó wà ní àjà ilẹ̀ ilé náà. Wọ́n tún ran àwọn míì lọ́wọ́ nínú ilé yẹn. Ṣe ni wọ́n tò tẹ̀lé ra, tí ẹnì kìíní sì ń gbé ẹrù fún ẹnì kejì, láàárín wákàtí díẹ̀, wọ́n ti kó gbogbo ẹrù tó wà níbẹ̀ kúrò. Gbogbo èèyàn ló mọrírì àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe. Viviana náà ń gbé ní ilé kan náà pẹ̀lú ìdílé Antonio, pẹ̀lú ẹkún ayọ̀ lójú ló fi wá bá ìyàwó Antonio, tó sì sọ fún un pé: “Jọ̀wọ́ bá mi dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn arákùnrin yín, wọ́n ṣe bẹbẹ!”
Ní abúlé kan tí omi ya wọ̀ gan-an, àwọn aládùúgbò ríi bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Ohun tí wọ́n rí wú wọn lórí gan-an tó fi jẹ́ pé àwọn kan lára wọn wá yọ̀ǹda ara wọn láti ràn wọ́n lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà, inú wọn dù gan-an pé àwọn ṣe bẹ́ẹ̀, tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n sì ń tẹ̀lé gbogbo ìtọ́sọ́nà tí wọ́n ń fún wọn.
Wọ́n fi ìmọrírì hàn
Àwọn ibì kan lára ilé ọkùnrin kan bàjẹ́, ẹrọ̀fọ̀ sì kún ibi tó máa ń gbé mọ́tò àtàwọn nǹkan míì sí. inú rẹ̀ dùn bó ṣe rí i tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́jọ ṣiṣẹ́ kára fún wákàtí mẹ́rin kí wọ́n bàa lè kó ìdọ̀tí kúrò tó wà níbi tó máa gbé ọkọ̀ sí. Inú rẹ̀ dùn gan-an, ó dì mọ́ àwọn kan lára àwọn tó wá ṣiṣẹ́ níbẹ̀, ó tún kọ ọ́ sí orí ìkànnì àjọlò pé òun mọrírì bí wọ́n ṣe wá ran òun lọ́wọ́.”
Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ràn lọ́wọ́, àwọn arúgbó tó jẹ́ ẹni ọgọ́rin [80] ọdún ló pọ̀ nínú wọn. Pẹ̀lú omijé lójú ni àwọn kan ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn fún àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe.” Aládùúgbò kan tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì náà sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bí òun ṣe mọrírì ohun tí wọ́n ṣe tó. Ó tún fi kún un pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tá a gbà gbọ́ yàtọ̀ síra, inú mi dùn pé a ṣì ń ran ara wa lọ́wọ́.” Ọkùnrin kan sọ pé: “Ó dùn mí pé ohun tí àwọn èèyàn mọ̀ nípa yín nìkan ni bẹ́ẹ ṣe máa ń lọ sí ilé wọn láti wàásù láàárọ̀ Sunday, wọn ò mọ àwọn ìrànlọ́wọ́ míì tẹ́ ẹ máa ń ṣe fún àwọn èèyàn.”