Àǹfààní Wo Ni Gbọ̀ngàn Ìjọba Máa Ṣe Àdúgbò Yín?
Ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún (100) ọdún báyìí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń kọ́ ibi tí wọ́n ti ń pàdé láti jọ́sìn. Gbọ̀ngàn Ìjọba ni wọ́n ń pè é. Ṣé wọ́n ti kọ́ irú ilé yìí sí àgbègbè yín? Àǹfààní wo ni Gbọ̀ngàn Ìjọba lè ṣe àdúgbò yín?
“Ẹ̀bùn Tí Inú Àwọn Ará Àdúgbò Máa Dùn Sí”
Ṣe ni wọ́n máa ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba lọ́nà tó máa bu ẹwà kún àdúgbò. Jason, tó ń bójú tó bí wọ́n ṣe ń kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé, “Ohun tá a fi máa ń ṣe góńgó ni pé kí Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a bá kọ́ sí àgbègbè kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ilé ló rẹwà jù níbẹ̀, táwọn èèyàn sì bọ̀wọ̀ fún.” Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó jẹ́ ayàwòrán ilé tó ń bá ẹ̀ka tó ń yàwòrán ṣiṣẹ́ fi kún un pé, “Tí wọ́n bá kọ́ ilé náà tán, a fẹ́ kó jẹ́ ẹ̀bùn tí inú àwọn ará àdúgbò máa dùn sí, a sì fẹ́ kó nípa rere lórí àwọn tó ni àwọn ilé àti ilẹ̀ tó yí ibẹ̀ ká.”
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó máa ń wù gan-an láti kọ́ àwọn ilé tó pójú owó làwọn tó ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwọn ẹlòmíì sábà máa ń kíyè sí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, níbi iṣẹ́ ìkọ́lé kan tó ń lọ lọ́wọ́ ní Richmond, nílùú Texas lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ẹni tó ń ṣàyẹ̀wò ilé nílùú náà sọ pé iṣẹ́ tí wọ́n ṣe sí òrùlé Gbọ̀ngàn Ìjọba náà ni iṣẹ́ tó dáa jù tóun tíì rí. Yàtọ̀ síyẹn, ní erékùṣù Jamaica, ẹnì kan tó ń ṣàyẹ̀wò ilé mú àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wọṣẹ́ lọ wo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ má wulẹ̀ yọ ara yín lẹ́nu lórí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn yìí. Bó bá ṣe wà lórí ìwé gẹ́lẹ́ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe máa kọ́ ilé tí wọ́n ń kọ́, kódà, wọ́n á tún ṣe é lọ́nà tó ta yọ bá a ṣe ń ṣe é nílùú wa níbí.” Ẹnì kan tó ń ṣàyẹ̀wò ilé nílùú kan ní Florida lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé, “Mo ti lọ ṣàyẹ̀wò láwọn ibi tí wọ́n ti ń kọ́ ilé ìwòsàn, tó fi mọ́ àwọn ilé ńlá tí ijọba ń kọ́, àmọ́ kò séyìí tí wọ́n fètò sí bíi tiyín yìí. Iṣẹ́ yín dáa gan-an.”
Ó Ń Nípa Rere Lórí Àwọn Ará Àdúgbò
Àwọn ìpàdé tó máa ń wáyé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba máa ń nípa rere lórí àwọn tó ń lọ síbẹ̀. Àwọn ìpàdé yìí ti ran àwọn tó jẹ́ òbí nínú wọn lọ́wọ́ láti di bàbá rere àti ìyá dáadáa, ó sì ti ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti di ọmọ gidi. Rod, tó ń bá àwọn tó ń yàwòrán Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣiṣẹ́, ṣàlàyé pé: “Ibi ìdálẹ́kọ̀ọ́ ni Gbọ̀ngàn Ìjọba kọ̀ọ̀kan, àwọn ìwà tó ṣe pàtàkì ká máa hù là ń kọ́ níbẹ̀, gbogbo èèyàn nìyẹn sì ń ṣe láǹfààní.” Ó fi kún un pé: “Ibẹ̀ lo ti lè rí ìrànlọ́wọ́ tó o bá níṣòro. Tayọ̀tayọ̀ làwọn tó o bá rí níbẹ̀ á fi kí yín káàbọ̀, wọ́n á mú yín bí ọ̀rẹ́, gbogbo àwọn tó bá nílò ìtùnú tàbí tí wọ́n fẹ́ mọ Ọlọ́run sí i ló sì máa jàǹfààní níbẹ̀.”
Àwọn tó ń pàdé pọ̀ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba kì í fi ọ̀rọ̀ àwọn aládùúgbò wọn ṣeré, wọ́n sì máa ń yára ṣèrànwọ́ tí àjálù bá ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 2016, lẹ́yìn tí ìjì líle tí wọ́n ń pè ní Hurricane Matthew jà ní Bahamas, ilé igba àti mẹ́rìnléláàádọ́ta (254) làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún ṣe. Ní àdúgbò kan, obìnrin àgbàlagbà kan tó ń jẹ́ Violet, tó jẹ́ ẹni ọgọ́rin (80) ọdún lọ bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń ṣiṣẹ́ ìrànwọ́ pé kí wọ́n wá bá òun tún ilé òun tí omi ya wọ̀ ṣe. Ó ní òun máa sanwó ohunkóhun tí wọ́n bá bá òun ṣe fún wọn. Àmọ́ wọn ò gba kọ́bọ̀ lọ́wọ́ ẹ̀. Wọ́n ṣe ọ̀pọ̀ àtúnṣe sí òrùlé Violet tó ń jò. Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe òrùlé tuntun sínú pálọ̀ rẹ̀. Nígbà tí wọ́n ṣiṣẹ́ tán, ṣe ni Violet dì mọ́ gbogbo wọn níkọ̀ọ̀kan, tó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn ṣáá, tó sì ń sọ pé, “Èèyàn Ọlọ́run ni yín lóòótọ́!”
‘Inú Wa Dùn Pé Gbọ̀ngàn Ìjọba Náà Wà ní Àdúgbò Wa’
Kí àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba lè lálòpẹ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣètò kan láti máa fi dá àwọn ará ìjọ lẹ́kọ̀ọ́ lórí bí wọ́n á ṣe máa tójú Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn. Ó sì ti sèso rere. Bí àpẹẹrẹ, ní àdúgbò kékeré kan ní Arizona, wọ́n pe obìnrin kan wá sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, ó sì gbà láti wá. Ó sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe tọ́jú gbọ̀ngàn náà dáadáa, ó sì wú u lórí nígbà tó gbọ́ nípa ètò ìtọ́jú tó wà nílẹ̀, ìyẹn pé, bí ilé bá tiẹ̀ dáa, ètò wà láti máa tọ́jú ẹ̀ kó lè máa dáa sí i. Obìnrin yẹn máa ń bá iléeṣẹ́ ìròyìn ìlú yẹn kọ̀wé, nígbà tó sì yá, iléeṣẹ́ náà gbéròyìn jáde lórí bí wọ́n ṣe ń tọ́jú Gbọ̀ngàn Ìjọba náà dáadáa. Ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi parí àpilẹ̀kọ ìròyìn náà ni pé, “Inú wa dùn pé . . . Gbọ̀ngàn Ìjọba náà wà ní àdúgbò wa.”
Káàkiri ayé ni wàá ti rí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Tọ̀yàyà-tọ̀yàyà la pè ẹ́ wá síbẹ̀. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé tayọ̀tayọ̀ la máa kí ẹ káàbọ̀.