Wọ́n Mára Tu Àwọn Èèyàn Níbi Eré Ìdárayá Tour de France
Eré ìdárayá kan wà táwọn èèyàn mọ̀ kárí ayé, tí wọ́n ti máa ń fi kẹ̀kẹ́ sáré. Tour de France ni wọ́n ń pè é. July 2 sí 24, 2016 ni wọ́n ṣe ìkẹtàlélọ́gọ́rùn-ún [103] irú ẹ̀, àmọ́ nǹkan ò fara rọ rárá nígbà tí wọ́n ń ṣe é. Lọ́dún tó ṣáájú, àwọn apániláyà ṣọṣẹ́ gan-an ní Ilẹ̀ Faransé, wọ́n gbẹ̀mí èèyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún [100]. Nígbà tó wá di July 14, 2016, tó jẹ́ ọjọ́ ọlidé lórílẹ̀-èdè náà, apániláyà kan wa ọkọ̀ akẹ́rù wọ àárín àwọn èrò tó ń wo iná aláràbarà tó ń yọ lára báńgà tí wọ́n ń yìn sójú ọ̀run nílùú Nice. Èèyàn mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún [86] ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ, àwọn tó sì fara pa pọ̀ gan-an.
Ọ̀fọ̀ ńlá ló ṣẹ ìlú yìí, ẹ̀rù sì bẹ̀rẹ̀ sí í ba àwọn èèyàn. Àmọ́ lákòókò tí àjálù ṣẹlẹ̀ yìí, ó wu àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gan-an láti sọ̀rọ̀ ìtùnú táá fún àwọn ọmọ Ilẹ̀ Faransé nírètí. Torí náà, àwọn Ẹlẹ́rìí gbé àwọn àtẹ ìwé tó ṣeé tì kiri lọ sáwọn ìlú tí àwọn èèyàn ti sá eré ìje náà. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [1,400] ló yọ̀ǹda ara wọn láti kọ́wọ́ ti ètò yìí, ó sì lé ní ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ìwé tí wọ́n fún àwọn èèyàn tó ń wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè kan tó ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé.
‘Kò Síbi Tá Ò Ti Rí Yín!’
Àwọn èèyàn ń tẹ̀ lé àwọn tó ń fi kẹ̀kẹ́ sáré náà káàkiri bí wọ́n ṣe ń ti ìlú bọ́ sílùú. Ó ya àwọn èèyàn yẹn lẹ́nu gan-an láti rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà káàkiri láwọn ìlú tí wọ́n dé. Ó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ táwọn òṣìṣẹ́ àjọ tó ń rí sí eré ìdárayá Tour de France yìí gbóríyìn fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí bí wọ́n ṣe ṣètò nǹkan lọ́nà tó mọ́yán lórí, wọ́n ní: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà síbi tá ò ti rí yín bá a ṣe ń ti ibì kan bọ́ síbòmíì!” Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mà tún wà níbí!” Ọ̀pọ̀ ọjọ́ lẹ́yìn tí eré ìje náà bẹ̀rẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí fún ẹnì kan tó ń wa bọ́ọ̀sì ní ìwé àṣàrò kúkúrú, àmọ́ ó sọ fún wọn pé òun ò ní fẹ́ gbà á, ó ní ìwé mẹ́rin lòun ti gbà tẹ́lẹ̀!
Ó ya àwọn èèyàn lẹ́nu bí wọ́n ṣe ń rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà léraléra, èyí sì mú kí àwọn kan yà sídìí àtẹ ìwé wọn láti mú ìwé. Ìgbà àkọ́kọ́ tí ẹlòmíì máa mú ìwé níbẹ̀ nìyẹn. Irú ẹ̀ ló ṣe ẹnì kan tó ń ṣiṣẹ́ ní iléeṣẹ́ kan tó ń gbé eré ìdárayá jáde lórí tẹlifíṣọ̀n. Ó rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbi eré ìdárayá yẹn lọ́dún tó ṣáájú. Nígbà tó wá di ọdún yìí, ó lọ síbi tí wọ́n pàtẹ ìwé sí, ó sì mú ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé torí pé ìwé yẹn sọ ọ̀rọ̀ kan tó kàn án gan-an. Ó mú ìwé náà lọ sínú mọ́tò ẹ̀, ó sì ka díẹ̀ níbẹ̀. Ó wá sọ̀rọ̀ àwọn àtẹ ìwé náà fún àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́, làwọn náà bá lọ mú ìwé lóríṣiríṣi.
Wọ́n Sọ̀rọ̀ Ìrètí, Wọ́n sì Fi Àwọn Èèyàn Lọ́kàn Balẹ̀
Àwọn kan tó wá síbi tí wọ́n ti ń sáré yìí wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kàn, wọ́n sì bá wọn sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn. Bí àpẹẹrẹ, obìnrin kan sọ fún wọn pé ayé ti sú òun, kódà, òun ti ń rò ó pé kóun pa ara òun, kóun lọ kó sábẹ́ ọkọ̀ rélùwéè. Àmọ́ lẹ́yìn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ tí Bíbélì sọ, pé àlàáfíà máa wà nínú Ìjọba Ọlọ́run lọ́jọ́ iwájú, ṣe lara tù ú, ó sì sọ pé òun ò ní pa ara òun mọ́. Nígbà tí obìnrin míì rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ kú iṣẹ́ Olúwa o, ẹ máà jẹ́ kó sú yín o!”
Ọkùnrin kan tó ń fi igi rìn sọ pé tí òun bá ti rí ẹni tóun ò mọ̀, ṣe lòun máa ń fura sí wọn. Àmọ́ nígbà tí obìnrin kan tó múra dáadáa sọ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun, tó sì fẹ́ ran ọkùnrin yìí lọ́wọ́, ọkùnrin náà gbà kó ran òun lọ́wọ́. Ọkùnrin náà sọ fún un pé: “Inú mi dùn bó o ṣe ń rẹ́rìn-ín músẹ́, mo sì mọyì bó o ṣe múra dáadáa. Ó fi mí lọ́kàn balẹ̀.”