Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kọ́wọ́ Ti Àwọn Aráàlú Láti Tún Ìlú Rostov-on-Don Ṣe

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kọ́wọ́ Ti Àwọn Aráàlú Láti Tún Ìlú Rostov-on-Don Ṣe

Ní May 20, 2015, gómìnà ìlú tó tóbi jù ní gúúsù orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, ìyẹn ìlú Rostov-on-Don, kọ lẹ́tà ìdúpẹ́ sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó yìn wọ́n fún “iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ṣe nígbà táwọn èèyàn ń tún ìlú náà ṣe nígbà ìrúwé.”

Nígbà táwọn aráàlú ń pawọ́ pọ̀ tún ìlú Rostov-on-Don ṣe, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti ìjọ mẹ́rin kó ìdọ̀tí lóríṣiríṣi tó ti kún àwọn ojú ọ̀nà ìlú náà àti etí odò. Láàárín wákàtí mélòó kan, nǹkan bíi ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] ọ̀rá tí ìdọ̀tí kún inú ẹ̀ ni wọ́n kó jọ, àwọn ọkọ̀ akẹ́rù sì wá kó o.

Kí ló mú kó yá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lára láti ran ìlú lọ́wọ́? Raisa tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínláàádọ́rin [67] sọ pé, “Mi ò kàn lè fọwọ́ lẹ́rán, kí n máà dá sí ohun tó ń lọ. Mo fẹ́ kí ìlú wa mọ́, kí gbogbo èèyàn lè máa gbé níbi tó mọ́. Táwọn èèyàn ò bá tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ mọ iṣẹ́ tá a ṣe, mo ṣì gbádùn iṣẹ́ yẹn. Béèyàn ò sì rí wa, Jèhófà Ọlọ́run kúkú rí wa.” Aleksander náà sọ pé: “Kì í ṣe pé a máa ń wàásù fáwọn míì nìkan ni, a tún máa ń ṣe ohun tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́. Inú mi máa ń dùn, mo sì máa ń láyọ̀ gan-an tí mo bá ran àwọn aládùúgbò mi lọ́wọ́.”

Àwọn tó rí ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe mọrírì báwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe yọ̀ǹda ara wọn. Ó ya ọ̀kan lára àwọn aráàlú lẹ́nu nígbà tó gbọ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí ò gbowó fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe yẹn. Lòun náà bá lọ bá wọn ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń kó ìdọ̀tí. Nígbà tó yá, ó sọ pé: “Mi ò mọ̀ pé mo lè gbádùn irú iṣẹ́ yìí, kó sì múnú mi dùn tó báyìí!” Ó fi kún un pé: “Àwọn kan nínú yín ò gbé ibí o, àmọ́ ẹ ṣì wá bá wa tún àdúgbò wa ṣe!”

Ọ̀kan nínú àwọn aláṣẹ ìlú kíyè sí i pé ìdọ̀tí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mélòó kan kó pọ̀ gan-an. Ló bá ní kí wọ́n dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀rá tí wọ́n fi kó ìdọ̀tí náà, ó sì yà wọ́n ní fọ́tò. Ó ní òun fẹ́ “fi han àwọn míì bó ṣe yẹ kí wọ́n ṣe iṣẹ́ náà.”