Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àdéhùn Ààbò Lórí Ìsọfúnni Ara Ẹni Tí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ń Tẹ̀ Lé Kárí Ayé

Àdéhùn Ààbò Lórí Ìsọfúnni Ara Ẹni Tí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ń Tẹ̀ Lé Kárí Ayé

Ọwọ́ pàtàkì ni ètò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé fi mú ẹ̀tọ́ tí ẹnì kọ̀ọ̀kan ní tó bá dọ̀rọ̀ pé ká pa ìsọfúnni ara ẹni mọ́ láṣìírí, ká sì dáàbò bò ó. Ètò náà mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn sọ̀rọ̀ láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, a kì í sì í fọ̀rọ̀ ohun tó jẹ́ àṣìrí ẹnì kan ṣeré rárá bá a ṣe ń bójú tó ohun tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílò, tá à ń ṣe ìjọsìn wa, tá a sì ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. A ò gbàgbé pé a gbọ́dọ̀ pa àṣírí mọ́, a sì ń rí i dájú pé àwọn ìsọfúnni tó wà níkàáwọ́ wa ò lu síta. (Òwe 15:22; 25:9) Ọwọ́ gidi la fi mú ọ̀rọ̀ àṣírí.​—Òwe 20:19.

Láwọn orílẹ̀-èdè kan, ìjọba ti ṣe òfin lórí ẹ̀tọ́ oníǹkan, èyí tó máa jẹ́ kí olúkùlùkù ní ẹ̀tọ́ lórí ohun tó jẹ́ àṣírí rẹ̀. Tipẹ́tipẹ́ kí wọ́n tó ṣe irú òfin yìí ní ètò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ oníǹkan, a kì í sì í fọ̀rọ̀ àṣírí tàfàlà, ìlànà yìí náà la sì ń tẹ̀ lé ní àwọn ẹ̀ka ófíìsì wa kárí ayé. Ètò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò máa bá a nìṣó láti pa ọ̀rọ̀ àṣírí tó wà níkàáwọ́ wa mọ́ bá a ti ṣe ń ṣe bọ̀ tipẹ́tipẹ́.

Ààbò Tó Péye Lórí Ìsọfúnni. Àwọn ìlànà tó tẹ̀ lé e yìí ni ètò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń tẹ̀ lé tó bá dọ̀rọ̀ ìsọfúnni nípa ara ẹni tó wà lọ́wọ́ wa:

  1. Ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀ kò ní di ohun ṣeréṣeré. A ò ní tẹ òfin lójú.

  2. A máa lo ìsọfúnni tá a bá gbà lọ́wọ́ ẹnì kan fún kìkì ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ìrànwọ́ tá à ń ṣe fún àwọn èèyàn.

  3. A ò ní ṣe àfikún ìsọfúnni tá a bá gbà, a ò sì ní yọ kúrò níbẹ̀. A máa ṣe àtúnṣe sí àṣìṣe èyíkéyìí ní gbàrà tí ètò náà bá ti mọ̀ èyí.

  4. A máa tọ́jú ìsọfúnni kan sọ́wọ́ fún àkókò gígún kìkì tó bá yẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀, tó sì bá òfin mu.

  5. A máa rí i dájú pé a bọ̀wọ̀ tó yẹ fún àwọn tí ìsọfúnni wọn wà lọ́wọ́ wa.

  6. A máa gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ láti rí i pé a tọ́jú àwọn ìsọfúnni ẹni ẹlẹ́ni tó wà lọ́wọ́ wa, débi tí kò fi ní lu sọ́wọ́ ẹni tí kò yẹ kó mọ̀ nípa rẹ̀. Gbogbo kọ̀ǹpútà táwọn ìsọfúnni àwọn èèyàn wà lórí rẹ̀ ló jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ìwọlé nìkan ni èèyàn lè fi wọ orí rẹ̀, àwọn tó sì lẹ́tọ̀ọ́ sí i nìkan ló mọ àwọn ọ̀rọ̀ ìwọlé náà. A máa ń ti àwọn ọ́fíìsì wa pa lẹ́yìn àkókò iṣẹ́, àwọn tó sì lẹ́tọ̀ọ́ láti wọlé nìkan ló lè wọ àwọn ọ́fíìsì yìí.

  7. A ò ní fi àwọn ìsọfúnni ẹni ẹlẹ́ni ránṣẹ́ sáwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa láìjẹ́ pé ó pọn dandan ká lè ṣe àwọn ohun tó jẹ́ mọ ìjọsìn àti ìrànwọ́ tá à ń ṣe fún àwọn èèyàn. Gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló fara mọ ètò ìjọsìn wa àti ètò ìrànwọ tá a ń ṣe fun àwọn èèyàn, torí fúnra wọn ni wọ́n pinnu láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, káwọn èèyàn sì mọ̀ wọ́n sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Ìlànà tá à ń tẹ̀ lé tó bá dọ̀rọ̀ dídáàbò ìsọfúnni ara ẹni yìí wà nínú ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, èyí tá a máa ń fún gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tí wọ́n bá di akéde. Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i, wo ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà.

Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ẹ̀tọ́ pé ká dáàbò bo ìsọfúnni àtàwọn ọ̀rọ̀ àṣírí nípa ara rẹ̀, ẹnì kan sì lè sọ pé ká ṣe àtúnṣe tàbí ká pa ìsọfúnni òun rẹ́, tó fi mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àṣírí nípa ara rẹ̀. Tí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, oníǹkan gbọ́dọ̀ fara mọ́ ohun tó wà ní abala Ìlànà Nípa Lílo Ìsọfúnni Ara Ẹni, lábẹ́ ìsọ̀rí náà Ẹ̀tọ́ Oníǹkan

Àlàyé nípa nípa ọwọ́ tá a fi ń mú ìsọfúnni táwọn èèyàn fi sí ìkáwọ́ wa ló wà ní abala yìí tá a pè ní Àdéhùn Ààbò Lórí Ìsọfúnni Ara Ẹni Tí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ń Tẹ̀ Lé Kárí Ayé.