Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌKÀNNÌ JW.ORG

Bó O Ṣe Lè Lo Ìkànnì JW.ORG Lórí Fóònù

Bó O Ṣe Lè Lo Ìkànnì JW.ORG Lórí Fóònù

Gbogbo abala orí ìkànnì tó o lè ṣí lórí kọ̀ǹpútà àtàwọn ohun míì tó o lè ṣe lórí ẹ̀ náà lo lè ṣe lórí fóònù tàbí tablet. Àmọ́ torí pé ojú fóònù ò fẹ̀, ọ̀tọ̀ nibi tí wàá ti rí àwọn bọ́tìnì kan, kó lè ṣeé ṣe fún ẹ láti gbádùn ìkànnì náà tó o bá ń lò ó. Àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti wá àwọn ohun tó o nílò lórí ìkànnì jw.org.

 Lo Àwọn Bọ́tìnì Tó Wà Lọ́wọ́ Òkè

Lórí kọ̀ǹpútà tàbí fóònù tí ojú ẹ̀ fẹ̀ dáadáa, wàá rí gbogbo àwọn ìsọ̀rí pàtàkì tó wà lórí ìkànnì náà lápá òkè, wàá sì rí àwọn ìsọ̀rí abẹ́nú tá a tò gbọọrọ lọ́wọ́ òsì lójú kọ̀ǹpútà tàbí fóònù náà.

Àmọ́ lórí fóònù tí ojú ẹ̀ kéré, ṣe la to gbogbo àwọn ìsọ̀rí yẹn gbọọrọ. Àti pé, tó ò bá lo àwọn ìsọ̀rí kan lọ́wọ́lọ́wọ́, àwọn bọ́tìnì ẹ̀ máa sá pa mọ́, èyí á jẹ́ kí ojú fóònù lè gba nǹkan tó ò ń ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́ lórí ìkànnì náà.

  • Tẹ bọ́tìnì tó kángun sápá ọ̀tún kó o lè rí àwọn ìsọ̀rí pàtàkì tàbí kó o fi pa mọ́. Tẹ orúkọ ìsòrí kan kó o lè lọ sí abala tí ìsọ̀rí náà wà.

  • Tẹ bọ́tìnì V kó o lè rí àwọn ìsọ̀rí abẹ́nú tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí kan. Tẹ orúkọ ìsọ̀rí náà kó o lè lọ sí abala tí ìsọ̀rí náà wà.

  • Tẹ bọ́tìnì Ʌ kó o lè fi àwọn ìsọ̀rí abẹ́nú tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí kan pa mọ́.

  • Tẹ bọ́tìnì JW.ORG kó o lè pa dà sí abala ìbẹ̀rẹ̀.

  • Tẹ àmì Èdè kó o lè rí gbogbo èdè tó wà.

  • Tẹ bọ́tìnì Wá a kó o lè wá nǹkan lórí ìkànnì náà.

 Ṣí Àwọn Àpilẹ̀kọ Tàbí Orí Tó Wà Nínú Ìwé Kan

Lórí kọ̀ǹpútà tàbí fóònù tí ojú ẹ̀ fẹ̀ dáadáa, wàá rí àwọn àkòrí tó wà nínú ìwé kan nígbàkigbà tó o bá ń ka àpilẹ̀kọ tàbí orí kan nínú ìwé. Àmọ́ lórí fóònù tí ojú ẹ̀ kéré, ó máa fi àwọn àkòrí náà pa mọ́.

  • Tẹ bọ́tìni | kó o lè rí àwọn àkòrí inú ìwé. Tẹ àkòrí kan kó o lè rí ohun tó wà nínú àpilẹ̀kọ tàbí orí náà.

  • Tẹ bọ́tìnì Pa Dà kó o lè rí àpilẹ̀kọ tàbí orí tó ṣáájú.

  • Tẹ bọ́tìnì Èyí Tó Kàn kó o lè rí àpilẹ̀kọ tàbí orí tó kàn.

  • Tẹ bọ́tìnì | kó o lè fi àwọn àkòrí inú ìwé pa mọ́, kó o sì máa ka àpilẹ̀kọ tàbí orí tó ò ń kà lọ.

 Ṣí Bíbélì Lórí Ìkànnì

Lọ sí ÌTẸ̀JÁDE > BÍBÉLÌ. Tàbí kó o tẹ ìlujá Ka Bíbélì lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó wà ní abala ìbẹ̀rẹ̀.

Tó o bá ti ṣí Bíbélì, yan ìwé Bíbélì àti orí tó o fẹ́ kà níbi àpótí tó wà lókè abala náà, kó o wá tẹ bọ́tìnì Lọ síbẹ̀.

Bó o ṣe ń ka orí náà lọ, àpótí tó o ti yan ìwé Bíbélì àti orí tó o fẹ́ kà ò ní kúrò lójú fóònù ẹ kó lè rọrùn fún ẹ láti lọ sí orí míì.

  • Tẹ bọ́tìnì Unpin kó lè gbé àpótí náà kúrò. Èyí á jẹ́ kí Bíbélì tó ò ń kà lè gba ojú fóònù ẹ dáadáa. Tó o bá fẹ́ yan orí míì, wàá ní láti lọ sókè tàbí sísàlẹ̀ abala tó ò ń kà lọ́wọ́lọ́wọ́.

  • Tẹ bọ́tìnì Pin kó lè fi àpótí náà sílẹ̀ lójú fóònù ẹ.

  • Tẹ bọ́tìni | kó o lè rí àwọn ohun tó wà nínú ìwé Bíbélì tó ò ń kà, tó fi mọ́ ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ àtàwọn àfikún.

  • Tẹ bọ́tìnì Pa Dà kó o lè rí orí tó ṣáájú.

  • Tẹ bọ́tìnì Èyí Tó Kàn kó o lè rí orí tó kàn.

  • Tẹ bọ́tìnì | kó o lè fi àwọn ohun tó wà nínú ìwé Bíbélì tó ò ń kà pa mọ́.

 Tẹ́tí sí Àpilẹ̀kọ Tá A Kà Sórí Ẹ̀rọ

Tí àpilẹ̀kọ tó ò ń kà bá ní àtẹ́tísí, wàá rí àmì pé ó ní.

  • Tẹ bọ́tìnì Play kó o lè máa gbọ́ àtẹ́tísí náà.

  • Tẹ bọ́tìnì Pause kó o lè dá a dúró. Tún tẹ Play kó o lè máa gbọ́ ọ lọ.

  • Fa àmì róbóróbó tó wà lójú àtẹ́tísí náà síwájú tàbí sẹ́yìn kó o lè lọ sí apá ibòmíì nínú àtẹ́tísí náà.

Tó o bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ àtẹ́tísí náà, tó o wá lọ sísàlẹ̀ níbi àpilẹ̀kọ tó ò ń kà, àmì àtẹ́tísí náà ò ní kúrò lójú fóònù ẹ. Èyí máa jẹ́ kó o lè dá a dúró tàbí kó o máa gbọ́ ọ lọ bó o ṣe ń fojú bá ìwé tó ò ń kà lọ.