JW LANGUAGE
Ìrànlọ́wọ́ Lórí iPad, iPhone àti iPod touch
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ètò ìṣiṣẹ́ JW Language láti máa fi ran àwọn tó ń kọ́ èdè lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ gbọ́ èdè náà, kí wọ́n sì lè lò ó lóde ìwàásù àti nínú ìjọ.
Ohun Tuntun Tó Wà ní Version 2.5
Ìsọ̀rí Grammar: Wo bí oríṣiríṣi ọ̀rọ̀ ṣe máa ń pinnu bó o ṣe máa hun ọ̀rọ̀, kó o lè mọ òfin ẹ̀hun gbólóhùn nínú èdè tó ò ń kọ́. Yí àwọn ọ̀rọ̀ inú gbólóhùn kan pa dà láti ọ̀rọ̀ ẹlẹ́ni kan sí ẹlẹ́ni púpọ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Wàá rí Settings ní abala ìbẹ̀rẹ̀ ètò ìṣiṣẹ́ náà
Jọ̀ọ́ Fi Sọ́kàn Pé:
Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, kọ̀ǹpútà ò ní lè fi álífábẹ́ẹ̀tì òde òní kọ ọ̀rọ̀ lábẹ́ ìsọ̀rí Grammar.
Ohun tó o ti ṣe ní apá text-to-speech lórí fóònù ẹ ló máa pinnu bí àtẹ́tísí tó wà lábẹ́ Grammar ṣe máa rí, torí náà, o lè ṣètò bó o ṣe fẹ́ kí èdè àti àtẹ́tísí rí lórí fóònù ẹ.
Ìsọ̀rí Grammar ti wà láwọn èdè yìí: Bengali, Chinese Cantonese (Traditional), Chinese Mandarin (Simplified), Faransé, German, Gẹ̀ẹ́sì, Hindi, Indonesian, Italian, Japanese, Korean, Malay, Myanmar, Potogí, Russian, Spanish, Swahili, Tagalog, Thai, Turkish, Vietnamese
NÍ APÁ YÌÍ
Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Máa Ń Béèrè—JW Language (Lórí iOS)
Wo ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tí àwọn èèyàn sábà máa ń béèrè.