JW LIBRARY
Bó O Ṣe Lè Fi JW Library Sórí Fóònù Ẹ Tó Ò Bá Tiẹ̀ Lè Ṣí App Store—Lórí Android
Tó ò bá rí JW Library fi sórí fóònù Android rẹ látorí àwọn ìkànnì bíi Google Play Store tàbí Amazon Appstore, o lè lo JW Library Android Package Kit (APK) láti fi sí i.
Tó o bá fẹ́ fi fáìlì APK ti JW Library sórí fóònù ẹ, ó lè gba pé kó o sàmì sí àpótí “install unknown apps” tàbí “allow installation from unknown sources.” Tó o bá fẹ́ mọ bó o ṣe lè ṣe é, wo ìwé tó bá fóònù Android rẹ wá.
Tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni yìí kó o lè wa fáìlì APK ti JW Library jáde, kó o sì fi sórí fóònù ẹ:
Tẹ bọ́tìnì Wà á jáde tó wà ní abala yìí kó o lè wa fáìlì APK náà sórí fóònù ẹ.
Lọ síbi tí fáìlì APK náà wà lórí fóònù, kó o wá tẹ̀ ẹ́ kó o lè fi JW Library sórí fóònù ẹ.
Tó o bá ti fi sórí fóònù ẹ, máa wo orí ìkànnì léraléra kó o lè mọ̀ bóyá ètò ìṣiṣẹ́ tuntun ti wà. Tó o bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni yìí:
Lọ sí abala Settings lórí JW Library kó o lè mọ nọ́ńbà ètò ìṣiṣẹ́ tó ò ń lò.
Tí nọ́ńbà èyí tó wà lórí fóònù ẹ bá kéré sí èyí tó wà nísàlẹ̀ yìí, tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tá a tò sókè yẹn láti wa fáìlì APK tó dé kẹ́yìn jáde, kó o sì fi sórí fóònù ẹ.
Version: 15.0.2 (461440)