JW LIBRARY
Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Lo JW Library—Lórí Android
Káàbọ̀ sórí JW Library. A ṣe ètò ìṣiṣẹ́ yìí láti máa fi ka Bíbélì, ká sì máa fi kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Tó o bá fẹ́ rí àwọn ohun pàtàkì tó wà lórí rẹ̀, fìka fa apá òsì lọ́wọ́ òkè ojú fóònù ẹ tàbí kó o tẹ àmì onígi mẹ́ta tó wà lọ́wọ́ òsì lókè pátápátá.
Bible
Apá tá a pè ní Bible máa jẹ́ kó o lè ka Bíbélì, kó o sì wa àwọn ìtumọ̀ Bíbélì jáde. Tó o bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì, tẹ ìwé Bíbélì kan, kó o wá tẹ orí tó o fẹ́ kà. Bó o ṣe ń kà á, wàá tún máa rí àwọn àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, atọ́ka àtàwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì ní abala Ìkẹ́kọ̀ọ́ lápá ọ̀tún.
Tó o bá fẹ́ wo ẹsẹ Bíbélì míì, fìka fa apá òsì lọ́wọ́ òkè ojú fóònù ẹ, kó o tún tẹ Bible kó o lè pa dà rí ibi tá a to àwọn ìwé Bíbélì sí.
Publications
Apá tá a pè ní Publications máa jẹ́ kó o rí àwọn ìwé, àtẹ́tísí àti fídíò. Tó o bá fẹ́ kàwé, tẹ ìwé kan, kó o sì tẹ àpilẹ̀kọ kan níbẹ̀. Bó o ṣe ń kàwé, o tún lè máa wo àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà níbẹ̀. Tó o bá tẹ ẹsẹ Bíbélì tó o fẹ́ kà, wàá rí i ní abala Ìkẹ́kọ̀ọ́. Tẹ ìlujá ẹsẹ Bíbélì kan ní abala Ìkẹ́kọ̀ọ́, ó máa gbé ẹ lọ sínú Bíbélì gangan.
Tó o bá fẹ́ ṣí ìtẹ̀jáde míì, fìka fa apá òsì lọ́wọ́ òkè ojú fóònù ẹ, kó o tún tẹ Publications kó o lè pa dà sí ibi táwọn ìtẹ̀jáde wà.
Daily Text
Fìka fa apá òsì lọ́wọ́ òkè ojú fóònù ẹ, kó o wá tẹ Daily Text kó o lè rí ẹsẹ ojúmọ́ tòní.
Online
Tó o bá fìka fa apá òsì lọ́wọ́ òkè ojú fóònù ẹ, wàá rí apá tá a pè ní Online, ó ní ìlujá tó máa gbé ẹ lọ sórí àwọn ìkànnì wa.
Rí Àwọn Ohun Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Dé
Máa rí i pé ètò ìṣiṣẹ́ Android tó dé kẹ́yìn ló wà lórí fóònù ẹ kó o lè máa rí ohun tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sórí JW Library.
Ó dáa kó jẹ́ pé ètò ìṣiṣẹ́ Android tó dé kẹ́yìn lò ń lò lórí fóònù ẹ. Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni sí i, tẹ ìlujá yìí: https://support.google.com/nexus/answer/4457705.
Kó lè rọrùn fún ẹ, o lè ṣe é kí fóònù ẹ máa wa ètò ìṣiṣẹ́ tó dé kẹ́yìn jáde fúnra ẹ. Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni sí i, tẹ ìlujá yìí: https://support.google.com/googleplay/answer/113412.