JW LIBRARY
Bó O Ṣe Lè Sàmì sí Ìwé—Lórí Android
Ohun tó o lè fi sàmì sí ìwé lórí JW Library máa jẹ́ kó o mọ ibi tó o kàwé dé, ṣe ló dà bí ìgbà téèyàn fi okùn tẹ́ẹ́rẹ́ kan tàbí bírò há ibi téèyàn kàwé dé. Lórí JW Library, ibi mẹ́wàá lo lè sàmì sí nínú ìwé kọ̀ọ̀kan.
Tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni yìí kó o lè sàmì sí ìwé:
Sàmì sí Ìwé
O lè sàmì sí àpilẹ̀kọ kan tàbí orí kan nínú ìwé, tàbí kó o sàmì sí ìsọ̀rí kan àbí ẹsẹ Bíbélì kan.
Tó o bá fẹ́ sàmì sí àpilẹ̀kọ kan tàbí orí kan, tẹ àmì Bookmark. Á to àwọn àmì tó o lè fi síwèé náà. Wá tẹ àmì tó ò tíì lò kó o lè sàmì sí àpilẹ̀kọ tàbí orí tó ò ń kà lọ́wọ́lọ́wọ́.
Tó o bá fẹ́ sàmì sí ìpínrọ̀ kan tàbí ẹsẹ Bíbélì kan, kọ́kọ́ tẹ ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹsẹ yẹn tàbí ìpínrọ̀ yẹn, kó o wá tẹ àmì Bookmark níbi àpótí tó hàn lókè.
Lọ Síbi Tó O Sàmì Sí
Tó o bá fẹ́ lọ síbi tó o sàmì sí nínú ìwé kan, ṣí ìwé tí àmì náà wà, kó o wá tẹ àmì Bookmark. Yan èyí tó o bá fẹ́ rí.
Yọ Ọ́ Kúrò Tàbí Kó O Rọ́pò Rẹ̀
Tó o bá ti sàmì síbì kan nínú ìwé, o lè yọ ọ́ kúrò tàbí kó o rọ́pò rẹ̀.
Tó o bá fẹ́ yọ àmì kan kúrò, tẹ bọ́tìnì Bookmark, kó o wá tẹ àmì tó-tò-tó tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àmì tó o fẹ́ yọ kúrò. Lẹ́yìn náà, tẹ Delete.
Tó o bá fẹ́ rọ́pò àmì kan, tẹ bọ́tìnì Bookmark, kó o wá tẹ àmì tó-tò-tó tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àmì tó o fẹ́ yọ kúrò. Lẹ́yìn náà, tẹ Replace. Á wá fi ibi tó ò ń kà lọ́wọ́ rọ́pò ibi tó o ti sàmì sí tẹ́lẹ̀. O lè máa ṣe irú nǹkan yìí tó o bá fẹ́ máa mọ ibi tó o ka ìwé kan dé. Bí àpẹẹrẹ, o lè máa fìyẹn sàmì sí ibi tó o ka Bíbélì dé lójoojúmọ́.
May 2014 la gbé àwọn àtúnṣe yìí jáde, ó bá JW Library 1.2 wá. Ó máa ṣiṣẹ́ lórí Android 2.3 sókè. Tó ò bá rí i lórí fóònù ẹ, jọ̀ọ́ tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà nínú àpilẹ̀kọ “Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Lo JW Library—Lórí Android,” lábẹ́ Rí Àwọn Ohun Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Dé.