Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JW LIBRARY

Bó O Ṣe Lè Wa Bíbélì Jáde Kó O sì Máa Lò Ó​—Lórí iOS

Bó O Ṣe Lè Wa Bíbélì Jáde Kó O sì Máa Lò Ó​—Lórí iOS

Ọ̀kan lára ohun pàtàkì tó o lè ṣe lórí JW Library ni kó o ka Bíbélì, kó o sì kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.

Tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni yìí kó o lè wa Bíbélì jáde, kó o sì máa lò ó:

 Wa Bíbélì Jáde

O lè wa oríṣiríṣi Bíbélì jáde kó o lè máa kà á, kó o sì máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.

  • Tẹ apá tá a pè ní Bible kó o lè rí àwọn ìwé inú Bíbélì.

  • Tẹ apá tá a pè ní Languages kó o lè rí gbogbo ìtumọ̀ Bíbélì tó wà. Àwọn Bíbélì tó wà ní èdè tó ò ń lò jù ló sábà máa ń wà lókè pátápátá. O tún lè wá Bíbélì míì jáde tó o bá fi orúkọ èdè tàbí orúkọ Bíbélì náà wá a. Bí àpẹẹrẹ, o lè tẹ “int” tó o bá fẹ́ wá Bíbélì Kingdom Interlinear lédè Gẹ̀ẹ́sì tàbí kó o tẹ “port” kó o lè rí gbogbo Bíbélì tó wà lẹ́dè Portuguese.

  • Wàá rí àmì òfúrufú lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn Bíbélì tó ò tíì wà jáde. Tó o bá tẹ irú Bíbélì bẹ́ẹ̀, o máa lè wà á jáde. Tó o bá ti wa Bíbélì kan jáde sórí fóònù ẹ, o ò ní rí àmì òfúrufú yẹn mọ́. Tún tẹ Bíbélì náà kó o lè kà á.

Tó ò bá rí ìtumọ̀ Bíbélì tó o fẹ́, jọ̀ọ́ pa dà wá wò ó tó bá yá. Tí àwọn ìtumọ̀ Bíbélì tuntun bá ti wà, a máa gbé e síbẹ̀.

 Yọ Bíbélì Kúrò

O lè yọ ìtumọ̀ Bíbélì kan kúrò tó ò bá fẹ́ mọ́ tàbí tí fóònù ẹ bá ti kún, tó o sì fẹ́ kí àyè wà lórí ẹ̀.

Tẹ Bible, kó o wá tẹ Languages kó o lè rí ibi táwọn Bíbélì wà. Fọwọ́ fa Bíbélì tó o fẹ́ yọ kúrò, kó o wá tẹ Delete.

 Wa Bíbélì Tá A Ṣàtúnṣe sí Jáde

Látìgbà dégbà, a lè máa ṣe àwọn àtúnṣe kan lórí àwọn Bíbélì tó o ti wà jáde tẹ́lẹ̀.

Tí àtúnṣe bá ti wà lórí Bíbélì kan, wàá rí àmì róbóróbó kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Tó o bá ti tẹ Bíbélì yẹn, o máa rí ìsọfúnni pé àtúnṣe ti wà. Kó o wá tẹ Download kó o lè tún un wà jáde, tàbí kó o tẹ Later kó o lè máa ka èyí tó o ti ní lọ́wọ́ lọ.

February 2015 la gbé àwọn àtúnṣe yìí jáde, ó bá JW Library 1.4 wá. Ó máa ṣiṣẹ́ lórí iOS 6.0 sókè. Tó ò bá rí i lórí fóònù ẹ, jọ̀ọ́ tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà nínú àpilẹ̀kọ “Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Lo JW Library​—Lórí iOS,” lábẹ́ Rí Àwọn Ohun Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Dé.